You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
CBN's N50bn COVID-19 Loans: Àlàyé rè é lórí bí o ṣe lè rí owó náà gbá
Ijọba orilẹede Naijiria ti ri eto iranwọ fun awọn eniyan lede lati dẹkun ipalara ti ajakalẹ arun Coronavirus ni lori awọn eniyan ati ọrọ aje wọn.
Ọna kan gboogi ti ijọba gbe kalẹ ni eleyii ti Banki apapọ lorilẹede Naijiria, CBN ti pese eto iyawo to le ni aadọta biliọnu Naira fun awọn ọmọ Naijiria.
Eto ẹyawo naa ni ile ifowopamọ awọn olowokekeeke NIRSAL Microfinance Bank ṣe onigbọwọ fun.
Amọ ọpọlọpọ awọn ọmọ Naijiria ko mọ boya wọn ni anfaani lati ya owo yii, abi kii ṣe fun wọn
- End SARS, Kemisola Oguniyi: Láti 23/10/2020 ni Kemisola Ogunniyi ti dèrò ẹ̀wọ̀n nítorí ìwọ́de EndSARS tó fi wa bímọ sẹ́wọ̀n báyìí
- Mo ṣetán láti wọ inú igbọ́ lọ wa àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n jígbé- Gomina ìpínlẹ̀ Kebbi
- ''Oyún oṣù méjì ní Kemisola Ogunniyi gbé dé ọgbà ẹ̀wọ̀n, a sì ṣe ìtọ́jú rẹ̀ dáradára''
- Wo ìdí tí EFCC fi fẹ́ wádìí ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Ogun láti ọdun 2015 dí àsìkò yìí
- 'Kò sí ẹni tó lè ní kí a má wá sí Èkó, iwọ́de òní pẹ̀lẹ́ kùtù la fẹ́ ṣe'
- Kò lè sí ààbò fún iléèwé kankan àfi tí ìjọba bá wá iṣẹ́ fáwọn tó ń jí ọmọ gbé - Gumi
CBN's Targeted Credit Facility (TCF)
Eyi ni agbekalẹ Banki apapọ lorilẹede Naijiria, CBN lati ṣeranwọ fun awọn eniyan lati le ṣeranwọ fun wọn nitori ipalara ti ajakalẹ arun Coronavirus da silẹ fun awọn ọmọ Naijiria ati idokowo wọn.
Ileeṣẹ Banki apapọ CBN ti gbe iye owo toto aadọta biliọnu Naira silẹ fun eto yii ni ileeṣẹ ifọwopamọsi NIRSAL Microfinance Bank ṣe onigbọwọ fun un.
Alaye re e lori ipele mẹta ti wọn pin awọn ọmọ Naijiria to ni anfaani lati ya owo CBN naa si;
Ojule si Ojule - Households
Awọn idile ni anfaani lati gba ẹyawo yii ti wọn ba ni ẹri to daju pe aarun Coronavirus ṣekupa ohun ti wọn n ṣe lati ri ounjẹ ọjọ wọn.
Nitori naa awọn wọnyii loni anfaani lati gba eto iyawo yii lọwọ ijọba Naijiria.
Oniṣowo kekeeke - Microenterprises
Bakan naa ni awọn ileeṣẹ kekeeke ni anfaani lati bere fun ẹyawo yii lọwọ ijọba apapọ.
Amọ awọn ileeṣẹ ti wọn le e fi aridaju lede pe lọọtọ ni aarun Coronavirus ba ọrọ aje wọn jẹ, ti wọn si nilo iranwọ ijọba lati gbera pada.
- Timothy Obadare ìránṣẹ́ Ọlọ́run to fọ́ lójú ìta ṣùgbọ́n tó ríran jù ọ́pọ́ wòlíì lọ
- Ẹ ṣeun, ẹ kú àdúrótì mi! Ẹ wo ọ̀rọ̀ tí Tope Alabi padà sọ nípa awuyewuye tó wáyé lóri orin Oniduro Mi
- Ọwọ́ tẹ ọmọdébìnrín tó jí ara rẹ̀ gbẹ́ nítorí ìyá rẹ̀ ní kó lọ kọ́ ẹ̀kọ́ láti ṣe dókítà
- Dino Melaye fi ọkọ Rolls Royce bùgá lórí Instagram, ni oníṣòwò ọkọ́ bá ní kó wá san gbèsè owó ọkọ̀ tó jẹ́ òun
- Ẹ wo ohun tí a mọ̀ nípa bí agbébọn ṣe gbẹ̀mí sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀, Titus Badejo Ejanla ní ìlú Ibadan
- Àjọ JAMB ṣèlérí ìdánwò mìí fún àwọn tí NIN jákulẹ̀, ó tún fòfin de ibùdó CBT 25
Ileeṣẹ kekere ati nla - SMEs
Awọn ọmọ Naijiria to ni ileeṣẹ kekere ati nla naa le bere fun ẹyawo yii lati mu ọrọ aje wọn pada.
Ileeṣẹ NIRSAL Microfinance Bank ni awọn ileeṣẹ yii gbọdọ ni aridaju pe lootọ ni aarun Coronavirus ṣe ipalara fun wọn.
Bakan naa ni wọn fikun pe ẹni kọọkan ati ileeṣẹ to ba pegede yoo ni anfaani lati ri iye owo toto miliọnu marundinlọgbọn naira gẹgẹ bi owo iranwọ.
Awọn to ba fẹ eto iranwọ yii le e lọ si oju opo ayelujara NIRSAL Microfinance Bank lati lọ fi orukọsilẹ
Awọn ọna miran ti ileeṣẹ Banki apapọ lorilẹede Naijiria tun gbekalẹ fun awọn ọmọ Naijiria lati ya owo ni the Guaranteed Off-take Stimulus Scheme (GoS) and the General MSME Grant.
- Ẹ wo bí olówó 'billionaire', Usifo Ataga ṣe kú ikú òjijì ní Eko
- Ṣé lóòtọ́ ni àwọn ọmọ ogun òfurufú Nàìjíríà ṣèèṣì pa máàlú 1,000 ní Nasarawa?
- Ajínigbe sún gbàgbé láwọn 15 nínú àwọn 156 tí wọ́n jí gbé ní Tegina bá sálọ
- Mo ṣetán láti wọ inú igbọ́ lọ wa àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n jígbé- Gomina ìpínlẹ̀ Kebbi
- Fola Alade, 'Architect' tó ya àwòrán ọ̀pọ̀ ilé àti ọ́fíísì tí Naijiria ní ti kú!
- Wo ìdí tí EFCC fi fẹ́ wádìí ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Ogun láti ọdun 2015 dí àsìkò yìí