You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
EndSARS, Kemisola Ogunniyi: Kéére o! Àwọn orúkọ mẹọmọ tí Obí sọ ọmọ rèé...
Ile ijọsin Vera Christian Assembly, Temiaseese Parish 2 nilu Akure ti wọn ti ṣe ikomọjade ọmọ ti Kemisola Ogunniyi bi sẹwọn ni Ondo.
Ero lorisirisi lo pese sibẹ to jẹ ki o kun fọfọ fun ero bi ẹbi, ọrẹ, awọn afẹnifẹre ati awọn ọmọ ẹgbẹ #RevolutionNow ti Alex Adeniyi ko sọdi ṣe bawọn pe biba sibẹ lai fi ti arọọda ojo ṣe.
Adari ijọ ọhun, Woli Funmi juwe ọmọ tuntun naa bii ọmọ ologo pẹlu awọn iṣelẹ́ ti o yi bibi rẹ ka.
- Hàà! Akẹ́kọ̀ọ́ UNILAG ẹni ọdún 21 kà bòrò-bòrò pé: Èmi ló pa olówó, ọ̀gá Super TV, Usifo Ataga
- 'Òògùn ìtọ́jú egbò ni Musa pe àgbo tó fún mi, àmọ́ èèyàn mẹ́wàá ti kú lẹ́yìn tí wọ́n lò ó'
- Àwọn lọ́balọ́ba nílẹ̀ Yoruba dalẹ̀ wa lórí àwọn ọmọ OPC mẹ́ta tí wọ́n tímólé láìṣẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ Iskilu Wakili - Ẹgbẹ́ OPC
- Ta ló gbé ìròyìn ikú ẹlẹ́jẹ̀ nípa Wòlìí SK Abiara, kí ní wọ́n sì ṣe fún un?
- Ilé ẹjọ́ ECOWAS pàṣẹ fún Naijiria láti gbẹ́sẹ̀ kúrò lórí òfin tó fi de Twitter
- Ẹ̀wọ̀n ọdún méje gbáko ni adájọ́ sọ pé kí Farouk Lawan fi ṣara ridin!
- Ẹ̀wọ̀n ọdún méje gbáko ni adájọ́ sọ pé kí Farouk Lawan fi ṣara ridin!
Yeyeluwa ilẹ Yoruba to tun jẹ aya Ọọni Ile-Ifẹ, Olori Silekunola Naomi Ogunwusi, iya rẹ, Diakoni Funmilayo Ogunseyi naa wa nibi isọmọ lorukọ naa.
Ọgbẹni Adewale Williams to jẹ ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ondo wa lara awọn eekan ilu to bawọn pejọ sibi ikomọ ọmọ Kemisola Ogunniyi ti wọn fẹsun kan pe o ba wọn ba dukia ilu jẹ lakoko iwọde ifẹhonuhan #EndSARS.
Bakan naa lo ṣe ladura pe ki Ọlọrun fun ọmọ naa lẹmi gigun lakoko to fi awọn orukọ mẹrinla ti ọmọ naa yio maa jẹ lede.
Awon orukọ ọun ni Ẹripọnmile, Ẹriaanu, Okikioluwa, Oluwajọmiloju, Mororeda, Ayọmipọsi, Ẹridamilare, Samuel, Elijah, Oluwadarasimi, Oluwanifemi, Aduragbemi, Oluwapamilẹrin ati Moriaanugba.
Yeyeluwa ilẹ Yoruba to ko obitibiti ẹbun wa fun ọmọ naa ṣe ileri iranlọwọ ati itọni loorekoore fun Kemisola.
Olori Naomi wa rọ awọn ọdọ to ba wa ni iru ipo Kemisola ki wọn ma ṣe sọ ireti nu, amọ ki wọn sapa lati ṣamulo ipo yowu ti wọn ba wa fun daadaa ati igbega ara wọn.
Dokita Thomas Ikubese to figba kan ri jẹ́ oludije sipo aarẹ lorilẹ ede yi ṣeleri iwosan ati ẹkọ ọfẹ titi de ile ẹkọ girama fun ọmọ naa.
Kemisola ni ko le pa ayọ rẹ mọra lakoko to n dupẹ lọwọ awọn araalu fun ifẹ ti wọn fihan si lati gba ohun ati ọmọ rẹ kuro lọgba ẹwọn.
Ìyàwó Ooni Ogunwusi, Olori Naomi Silekunola lọ ibi ìsọmọlórúkọ Kemisola, ayé gbọ́!
Ayo abara tintin, kẹti kẹti ni ero n wọ ni ii ti wọn ti ṣe isin ikomọjade Ogunniyi to bimọ si ọgba ẹwọn niilu Akure, ipinlẹ Ondo.
Awọn eeyan jankan jankan gan ko gbẹyin nibẹ pẹlu bi arabinrin yii ṣe ti di ilumooka lati ẹwọn. Ọrọ naa fẹ dabii itan Josẹfu inu Bibeli to ti ati inu ọgba ẹwọn di aarẹ ati ẹni ti gbogbo ilu fẹ ri.
Awọn orukọ tó làmì laaka ti wọn sọ ọmọ tuntun jojolo ọhún niwọnyii:
Eriponmile, Erianu, Okikioluwa, Oluwajomiloju, Mororeda, Ayomiposi,
Eridamilare, Samuel, Elijah, Oluwadarasimi, Oluwanifemi, Aduragbemi,
Oluwapamilerin ati Morianugba.
Ẹkun ayọ kun rọrọ loju iya ọmọ ti ara rẹ ṣi tutu latari irora ọmọ bibi. O ranti gbogbo ohun to la kọja o si bu sẹkun ninu ijọ Vera Christian Assembly Temiasese ti wọn ti ṣe isin ikomọ naa.
Lara awọn eekan ilu to lọ yẹ Kemisola si ni Yeyeluwa ti Ile Ife, Olori Naomi Silekunola ti aworan fihan to gbe ọmọ naa lọwọ.
- Ṣé lóòtọ́ ni olè kan wọlè fipá bá ìyá 80 lòpọ̀ nípìnlẹ̀ Ondo?
- Alága ìjọba ìbílẹ̀ Eti-Osa, Eko tí jádé láyé lẹ́yìn tó ṣe àìsàn
- Kò sí ìpínlẹ̀ tí ijọba mi kò tíì fọwọ́ bà sí rere- Ààrẹ Muhammadu Buhari
- Ẹranko àìmọ́ kan wọ Nàìjíríà, ó pa ènìyàn mẹ́rin ní Benue- ilé iṣẹ́ ọmọogun ni ìròyìn òfegè ni
- Pipa ní wọ́n gbọ́dọ̀ pa àwọn agbébọn tí wọ́n ń jí àwọn ènìyàn gbé, ẹ da ọ̀rọ̀ Sheik Gumi nù -Aisha Yesufu
Ninu ijọ, ati ẹbi ati ara lo peju sibẹ to fi mọ awọn to n ja fun itusilẹ rẹ latari ẹsun ti wọn fi kan an pe o darapọ mọ awọn oluwọde EndSARS lọdun to kọja.
Ṣe ni ẹbun n wọle lọtun losi si inu ile awọn Kemisola lẹyin ti wọn pari isin isọmolorukọ ati lati igba to ti pada sile lati ẹwọn.
Kí ẹ̀dá máa dúpẹ́ nínú ipòkípò tó bá wà láyé ni èrò ọ̀pọ̀ ọmọ Nàìjíríà sí Kemisola
Ọpọ ọmọ Naijiria ni wọn ti n kí Kemisola Ogunniyi ku oriire ikomọjade oni.
Opo n kii pe o tun ku ajabọ.
Bẹẹ ni awọn miran n kii pe o ju yiyọ Olorun pẹlu imọran pe ki o ṣe jẹjẹ laisko yii.
Lana, ọjọ Iṣegun, ọjọ kejilelogun, oṣu kẹfa ni ileẹjọ ni Olokuta nipinlẹ Ondo tu Kemisola ati ọmọ ikoko to bi sọgba ẹwọn silẹ̀.
Beeli Milionu mẹwaa naira ni Adajaọ Omolara fun Kemisola Ogunniyi lẹyin ti wọn muu lasiko iwọde EndSARS nipinlẹ Ondo lọdun to kọja.
Diẹ lara orukọ ti wọn n sọ ọmọ tuntun silẹ ṣaaju ikomojade ni Joseph, Oluwasegunfun Kemi, Ayomide, Ojutẹlẹgan, Opeyemi ati bẹẹ bẹẹ lọ.
- Ẹ̀wọ̀n ọdún méje gbáko ni adájọ́ sọ pé kí Farouk Lawan fi ṣara ridin!
- Ààrẹ Buhari fọwọ́sí kí Lai Mohammed, Fashola àti Malami jíròrò pẹlú 'Twitter'
- Pipa ní wọ́n gbọ́dọ̀ pa àwọn agbébọn tí wọ́n ń jí àwọn ènìyàn gbé, ẹ da ọ̀rọ̀ Sheik Gumi nù -Aisha Yesufu
- Ẹranko àìmọ́ kan wọ Nàìjíríà, ó pa ènìyàn mẹ́rin ní Benue- ilé iṣẹ́ ọmọogun ni ìròyìn òfegè ni
- Kò sí ìpínlẹ̀ tí ijọba mi kò tíì fọwọ́ bà sí rere- Ààrẹ Muhammadu Buhari
- Alága ìjọba ìbílẹ̀ Eti-Osa, Eko tí jádé láyé lẹ́yìn tó ṣe àìsàn
O jẹ akoko to lapẹrẹ ni yara igbẹjọ kẹwa ti ile ẹjọ giga ipinlẹ Ondo ninu ọgba ẹwọn Olokuta nilu Akure, bi Onidajọ Omolara Adejumo ṣe n sure fun ọmọ Kemisola Ogunniyi.
Kemisola yii lo wa ni ahamọ latari ifẹsunkan pe o kopa ninu iwọde #EndSARS.Onidajọ Adejumo lo rọjo adura le ọmọ tuntun ọun lori ni kete to yọnda ki wọn gba beeli Kemisola to jẹ iya ọmọ naa lori orukọ rẹ ki o le lọle lati ṣe ipalẹmọ fun isọmọlorukọ ọmọ naa lọla ode yíi.
'Wàá di ẹni ńlá láyé'! Lẹ́yìn bíbéèrè béèlì N10M, adájọ́ ṣe àdúrà fún ọmọ tí Kemisola bí sẹ́wọ̀n
Adajọ naa wipe oun fọwọ si ki Kemisola maa lọ sile lati le gbaradi fun bi wọn yoo ṣe fun ọmọ rẹ lorukọ titi ti yoo fi le ṣeto beeli oni miliọnu mẹwa naira ti wọn fun un."Yoo dara fun ọ. Oo di ẹni nla. Iṣẹlẹ yii ko nii da ọ duro lati de aiye ti Ọlọrun pese kalẹ fun ọ" nni adura Onidajọ Adejumo nibi iya ọmọ naa ati gbogbo awọn to wa nile ẹjọ ṣe n ṣe amin si adura ọun.
- Ta ló gbé ìròyìn ikú ẹlẹ́jẹ̀ nípa Wòlìí SK Abiara, kí ní wọ́n sì ṣe fún un?
- Òjò rọ jẹ̀jẹ̀rẹ̀ n'ílé aṣòfin Abuja, ẹ wo bí gbogbo òrùlé ṣe gbe ojò wọlé
- Ẹ̀wọ̀n ọdún méje gbáko ni adájọ́ sọ pé kí Farouk Lawan fi ṣara ridin!
- Father's Day fa gbas-gbos láàrin Mercy Aigbe àti ọkọ rẹ̀ tẹ́lẹ̀, Gentry, ọkọ́ ní òun le tú àwọn àṣírí ìwà nọ̀bì rẹ̀ síta
- Àlàyé rè é lórí bí o ṣe lè gbá owó ìrànwọ́ N50bn COVID-19 tí CBN gbé jáde
- 'Kò sí ẹni tó lè ní kí a má wá sí Èkó, iwọ́de òní pẹ̀lẹ́ kùtù la fẹ́ ṣe'
- Ṣaaju ni Tola Ologun to dari awọn to jẹ agbefọba ti wipe ohun ko tako ẹbẹ gbigba beeli Kemisola leyi ti agbẹjọro rẹ Tope Temokun gbe ka iwaju ile ẹjọ naa nitoripe ẹsun ti wọn lee gba beeli rẹ ni.
Ilé ẹjọ́ bèèrè fún 10m àti onídùúró kan láti gba béèlì Ke Kemisola Ogunniyi tó bímọ sí ẹ̀wọ̀n ní Ondo
Ile ẹjọ giga ti ipinlẹ Ondo ti gba beeli ọmọbinrin, Kemisola Ogunniyi, ti wọn fi si ẹwọn nitori iwọde EndSars.
Onidajọ Ololara Adejumo lo gbọ ẹjọ naa ni ile ẹjọ ọhun to wa ninu ọgba ẹwọn Olokuta nilu Akure.
Ṣugbọn ṣa, adajọ naa sọ pe ki mọlẹbi Kemisola mu milinu mẹwaa Naira ati oniduro kan wa ki wọn o to gba beeli rẹ.
Ọla, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹfa ni ikomọjade ọmọ ti Kemisola bi si ẹwọn.
Ọjọ Aje ni igbẹjọ lori gbigba beeli Kemisola Ogunniyi ti wọn ni o kopa ninu iwọde ifẹhonuhan #EndSARS ni ko waye loni nile ẹjọ giga kẹwa ni ọgba ẹwọn Olokuta, nilu Akure.
Lẹyin wakati marun un o le ti awọn eyan ti n duro de ẹjọ ọhun nile ẹjọ wi pe wọn ti pari ijoko loni lai mẹnu ba ẹjọ Kemisola.
Agbẹjọro Kemisola, Tope Temokun, sọ fun BBC News Yoruba pe igbẹjọ naa ni ko waye nitori pe wọn ko kọọ mọ awọn ẹjọ to wa niwaju onidajọ Omolara Adejumo to wa nile ẹjọ ọhun.
O ni wọn ti fun oun ni idaniloju pe wọn yoo gbọ ẹjọ ni aago mẹwaa ọla ode yii.
Temokun lo ni oun ko ni kaarẹ ọkan lati ri daju wi pe Kemisola jade lọgba ẹwọn ṣaaju ikomọ ọmọ rẹ ni Ọjọru ọsẹ yi.
Ọrọ Kemisola lo di kaari aiye lẹyin ti aworan oun ati ọmọ to ni ninu ọgba ẹwọn gba gbogbo oju ẹrọ aiyelujara, leyi to mu ki ọpọlọpọ koro oju si itimọle rẹ.
Igbẹjọ lori gbigba beeli Kemisola Ogunniyi ti wọn ni o kopa ninu iwọde ifẹhonuhan #EndSARS ni ko waye loni nile ẹjọ giga kẹwa ni ọgba ẹwọn Olokuta, nilu Akure.
''Oyún oṣù méjì ní Kemisola Ogunniyi gbé dé ọgbà ẹ̀wọ̀n, a sì ṣe ìtọ́jú rẹ̀ dáradára''
Ileeṣẹ ọgba ẹwọn nipinlẹ Ondo ti ni oyun oṣu meji ni arabinrin Kemisola Ogunniyi gbe wọ ọgba ẹwọn ni ọdun to kọja.
Eyi to ṣẹyin iroyin to n ja ranyin pe ijọba ipinlẹ Ondo ti arabinrin Kemisola Ogunniyi to ṣẹṣẹ bimọ si ọgba ẹwọn lẹyin to ti wa nibẹ lati igba ifẹhọnu to tako ifiyajẹni awọn ọlọpaa lorilẹede Naijiria.
Arabinrin Oguniyi ni wọn ni awọn ọlọpaa ti mọle nitori o pẹlu awọn eniyan to n fẹhọnu han lasiko Endsars, amọ iya rẹ ni oun ran niṣẹ lati lọ ba oun ra nkan.
Ninu atẹjade ti ileeṣẹ ọgba ẹwọn ipinlẹ Ondo fi lede gba ọwọ agbẹjọro wọn, Ogundare Babatunde ni Ọjọ Kẹrinlelogun, Oṣu Kọkanla, Ọdun 2020 ni wọn ti fi obinrin naa si ọgba ẹwọn lẹyin ti ileẹjọ fi ẹsun kan pe o jẹbi ẹsun ole, biba ohun ini jẹ ati apejọpọ lọna aitọ ti wọn fi kan an.
Babatunde ni ileẹjọ lo sun igbẹjọ obinrin naa si iwaju lati oṣu kejila, ọdun 2020 si oṣu Kẹta , ọdun 2021.
- Fola Alade, 'Architect' tó ya àwòrán ọ̀pọ̀ ilé àti ọ́fíísì tí Naijiria ní ti kú!
- Ṣé lóòtọ́ ni àwọn ọmọ ogun òfurufú Nàìjíríà ṣèèṣì pa máàlú 1,000 ní Nasarawa?
- Ajínigbe sún gbàgbé láwọn 15 nínú àwọn 156 tí wọ́n jí gbé ní Tegina bá sálọ
- Ẹ wo ohun tí a mọ̀ nípa bí agbébọn ṣe gbẹ̀mí sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀, Titus Badejo Ejanla ní ìlú Ibadan
Ninu ọrọ naa ni wọn ti sọ wi pe oyun osu meji ni obinrin naa gbe wọ ọgbs ẹwọn ti awọn si ṣe itọju rẹ gẹgẹ bi o ṣeyẹ titi o fi bi ọmọ, ti awọn si gba awọn ẹbi ati ara rẹ laaye lati wa yọju si loore-koore.
''Ọjọ Karundinlogun, Oṣu Kẹfa ni ọmọ gbe e, ti wọn si gbe lọ si ileewosan ijọba fun itọju to peye, to si bimọ ni Ọjọ kẹrindinlogun, Osu Kẹfa, ọdun 2021''
''Alaafia si ni ọmọ ati iya wa lẹyin to bimọ, ti wọn si fi silẹ ni ileewosan pe ara rẹ ti wa daadaaa, ti awọn si da pada si ọgba ẹwọn lẹyin naa.''
Bakan naa ni ileeṣẹ ọgba ẹwọn nipinlẹ Ondo ni o pọn dandan ki awọn eniyan mọ daju wi pe awọn ko le e dede fi eniyan si ọgba ẹwọn ti ileẹjọ ko ba fi aṣẹ si.
- Ẹ ṣeun, ẹ kú àdúrótì mi! Ẹ wo ọ̀rọ̀ tí Tope Alabi padà sọ nípa awuyewuye tó wáyé lóri orin Oniduro Mi
- Ẹ wo bí olówó 'billionaire', Usifo Ataga ṣe kú ikú òjijì ní Eko
- Dino Melaye fi ọkọ Rolls Royce bùgá lórí Instagram, ni oníṣòwò ọkọ́ bá ní kó wá san gbèsè owó ọkọ̀ tó jẹ́ òun
- Àjọ JAMB ṣèlérí ìdánwò mìí fún àwọn tí NIN jákulẹ̀, ó tún fòfin de ibùdó CBT 25
- Ọwọ́ tẹ ọmọdébìnrín tó jí ara rẹ̀ gbẹ́ nítorí ìyá rẹ̀ ní kó lọ kọ́ ẹ̀kọ́ láti ṣe dókítà
Wọn fikun un wi pe awọn n ṣiṣẹ to yẹ lati ri wi pe awọn ko tẹ oju ofin awọn eniyan to wa ni ọgba ẹwọn mọlẹ ni igba gbogbo nitori iṣẹ awọn ni awọn n ṣe.