Lagos-Ibadan Expressway Fire: Kíló fa iná tó sọ ní òpópónà Ibadan sí Eko tó gbẹ̀mí ènìyàn tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkọ̀ sì jóná?

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ijamba ina sọ ni opopona Ibadan si Eko ni agbegbe Ọgere ni owurọ Ọjọ Iṣẹgun, to si mu ẹmi eniyan meji lọ pẹlu ọpọlọpọ ọkọ to jọna ninu iṣẹlẹ naa.

Adari ileeṣẹ irinna oju popo nipinlẹ Ogun, Arakunrin Ahmed Umar to fi idi ọrọ naa mulẹ ni nkan bi aago mẹfa aarọ oni lo ṣẹlẹ.

Umar ni iwaju ibudokọ Romona ti awọn ọkọ nla ni Ogere ni iṣẹlẹ naa ti waye.

O ni ijanu ọkọ to gbe bẹntirolu lo da iṣẹ silẹ, to si lọ kọlu ọkọ miran to wa loju ọna , eleyii to fa ija to si mu ẹmi lọ.

Bakan naa lo fikun pe sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ to ṣẹlẹ laarọ nitori oju ọna ti wọn n tunṣe nibẹ, to si mu ki wọn ṣi oju ọna kan ṣoṣo to sokunfa iṣẹlẹ naa.

''Ina naa pọ gidigan an ni ti a ko tii le ṣọ iye ọkọ to jona ninu iṣẹlẹ naa.

Ọkan lara awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ ni awọn awakọ tirela nla mejeeji to kolu ara wọn to si fa ijamba ina naa ni ẹmi wọn ti lọ si iṣẹlẹ naa.

Lọwọlọwọ bayii, awọn ẹsọ alaabo, panapana ti wa nibẹ lati ri pe wọn ri ojutu ina to sọ naa.

Bakan naa ni ọkọ kankan ko le e lọ siwaju lasiko yii, nise ni wọn duro si oju kan naa nitori awọn eniyan si n woye wi pe o ṣeeṣe ki awọn ọkọ nla miran to gbe afẹfẹ gaasi ṣi le jona.