You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Dino Melaye fi ọkọ Rolls Royce bùgá lórí Instagram, ni oníṣòwò ọkọ́ bá ní kó wá san gbèsè owó ọkọ̀ tó jẹ́ òun
Odu ni gbajugbaja oloṣelu, to ti fi igba kan jẹ ọmọ ile aṣofin Naijiria, Dino Melaye, lori ayelujara paapaa fun bi o ṣe maa n ṣe afihan awọn dukia olowo iyebiye to ni.
Gẹgẹ bi iṣe rẹ, laarin ọsẹ to kọja ni Melaye tun fi fọto kan sori ayelujara Instagram rẹ ti awọn ololufẹ rẹ naa si bẹrẹ si ni kọ awọn ọrọ iwuri ati ikini si abẹ fọto naa.
Ninu fọto ọhun lati ri Melaye to duro ni ẹgbẹ ìkan lara awọn ọkọ ayọkẹlẹ bọginni to n lo, Rolls Royce, pẹlu akọle pe "Ẹ tẹsiwaju lati ma a sọ isọkusọ ti ẹ n sọ, emi a si ma a lo RR (Rolls Royce).
Iroyin sọ pe ọkọ Rolls Royce naa ni owo rẹ to ọgọrun miliọnu Naira.
Ṣugbọn, kinni Melaye fi fọto naa sita, a fi bi ẹni pe o jade wa gba ẹtẹ ati abuku ni.
Nitori pe niṣe ni gbajugbaja ile itaja ọkọ ayọkẹlẹ kan nilu Eko, Unique Motors, naa darapọ mọ awọn to n kọ ọrọ si abẹ rẹ, to si sọ pe Dino ṣi ni gbese lati san lori ọkọ ayọkẹlẹ lọdọ wọn.
Ninu ọrọ naa, Unique Motors ṣalaye pe gbogbo igbiyanju oun lati ba Melaye sọrọ, ati ẹnikan to pe ni Moses, lo jasi pabo. O si tun gba Melaye ni imọran pe ko wa a san gbese rẹ ni kiakia.
Unique Motors ni "Sir, ẹ si ni owo ti ẹ fẹ san fun Unique Motors. Gbogbo akitiyan lati ba yin sọrọ, ati Moses naa, lo ja si ofo. Ẹ jọwọ, ẹ sanwo."
Lati igba naa si ni ọpọ eeyan lori ayelujara ti n sọ oriṣiriṣi ọrọ eebu si Dino Melaye.
Lẹyin ọjọ diẹ to kọkọ fi ẹsun naa kan, ni wọn tun fi aworan Melaye sori Instagram stories, nibi to ti duro si ẹgbẹ ọkọ ayọkẹlẹ bọginni funfun kan, pẹlu akọle pe "a kan fẹ ẹ gba owo ti o san ku lori ọkọ yii to o ra lati ọdun 2019.
"Abi, ṣe eyi ti pọju nkan ti a le beere ni, @dinomelaye?"
Kini Dino Melaye sọ lori ẹsun naa?
Sẹnetọ Dino Melaye ko kọkọ fesi lori ẹsun ti Unique Motors fi kan pe o jẹ gbese lori ọkọ ayọkẹlẹ to ra lọwọ wọn.
Amọ, ni ọjọ meji sẹyin ni Sẹnetọ Melaye fesi si ẹsun naa ninu ọrọ to kọ si ori Instagram.
O ni: "A fi unique motor na! To ba jẹ lootọ ni mo n jẹ ọ ni owo, o mọ nkan to yẹ ki o ṣe. Abi, ṣe ori ayelujara lo ti ta ọkọ naa ni?
"Gbogbo ẹyin ti ẹ n fi orukọ mi polowo ọja iregbe ati iranu ti ẹ n ta... Ọlọrun mọ adirẹsi yin ooo. Amọ, fun Unique oniranu yii, awọn agbẹjọro mii yoo ranṣẹ si ọ laipẹ. O ti fa ijọgbọn lẹsẹ."
Ọpọ eeyan lo si tun ti pada si ni sọrọ si Melaye lẹyin naa pe, o n fi ọwọ agbara fi iya jẹ oniṣowo ọkọ naa.
Bẹẹ ni awọn kan naa n gba ni imọran pe ko tete lọ san gbese to jẹ.
Amọ, nisẹ ni awọn eeyan kan naa tun n sọ pe awọn jẹri Melaye pe ko le jẹ gbese.
- Ọwọ́ tẹ ọmọdébìnrín tó jí ara rẹ̀ gbẹ́ nítorí ìyá rẹ̀ ní kó lọ kọ́ ẹ̀kọ́ láti ṣe dókítà
- Ẹ ṣeun, ẹ kú àdúrótì mi! Ẹ wo ọ̀rọ̀ tí Tope Alabi padà sọ nípa awuyewuye tó wáyé lóri orin Oniduro Mi
- Timothy Obadare ìránṣẹ́ Ọlọ́run to fọ́ lójú ìta ṣùgbọ́n tó ríran jù ọ́pọ́ wòlíì lọ
- Rahmon ń múra láti lọ rí ìyàwó àti ìbèjì tó bí ní US ni wọ́n bá pa á níbi ìjà tó bẹ́ sílẹ̀ ní Iwo road
- Ṣé lóòtọ́ ni ilẹ̀ America ti bẹ̀rẹ̀ 'visa lottery padà fún àwọn ọmọ Naijiria? Wo àlàyé níbí