You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
DV-2022: Àyédèrú ni ìpolówó US visa lottery to n lọ ní Naijiria - Iléèṣẹ́ ilẹ̀ America
Ileeṣẹ ilẹ America ni orilẹ-ede Naijiria ti fi ikilọ sita fun awọn eeyan, lori iroyin kan to n lọ nipa iwe igbelu 'green card' orilẹ-ede naa.
Ninu atẹjade to fi si ori ayelujara Twitter rẹ, ni ọjọ Ẹti, wọn sọ pe ayederu ni iroyin naa ati awọn atẹjisẹ to n lọ kiri nipa tẹtẹ oriire iwe igbelu 'visa lottery'.
Ajọ ilẹ America ọhun sọ pe ori ayelujara oun, ng.usembassy.gov ati travel.state.gov, nikan ni wọn ti le ri ojulowo iroyin nipa eto naa.
Lati igba de igba ni eto 'DV visa lottery' naa ma n waye.
Oṣu Kẹwaa, ọdun 2020 si ni eto iforukọsilẹ fun eyi to n lọwọ fun ọdun 2022 ti waye.
Fun ọpọlọpọ ọdun, eto visa lottery jẹ gbajugbaja ni orilẹ-ede Naijiria ni nkan bi ọdun 'year 2000'.
Kilode ti US fi opin si eto visa lottery ni Naijiria?
Ọdun 1995 ni ijọba ilẹ America bẹrẹ eto irinna naa ti yoo fun awọn ọmọ ilẹ okeere ni anfaani lati gba iwe igbelu titi lai (Permanent Residence). Ọdọọdun si ni wọn ma n ṣe e .
Eto PR yii ti awọn kan tun mọ si Green Card, ni yoo pada di didi ọmọ ilẹ America gan-an. Eeyan bi 680,000 to jẹ arinrinajo si lo ma n di ọmọ ilẹ America ni ọdọọdun.
Ṣugbọn lọdun 2014, ilẹ America kede pe Naijiria ko koju osunwọn mọ lati ọdun 2015. Oun si ni orilẹ-ede kan ṣoṣo ati akọkọ nilẹ Africa ti wọn fi ofin 'visa lottery' de.
Wọn ni Naijiria ti de gbedeke iye eyan to ni anfaani si: eyi tumọ si pe ti eeyan to le ni 50,000 ba ti janfaani rẹ laarin ọdun marun-un lati orilẹ-ede kan ṣoṣo.
Awọn orilẹ-ede ti wọn ba fi ofin de tun le pada jẹ anfaani, gẹgẹ bo sẹ ṣẹlẹ si Peru, Poland ati awọn mii.
Nitori naa, orilẹ-ede America ṣi le gbẹsẹ kuro lori ofin to de Naijiria lọjọ iwaju.
Ghana tun ni orilẹ-ede mii nilẹ Africa, to ti n sunmọ gbedeke rẹ diẹdiẹ.