You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
TrumpBanned: Twitter ní ó tó gẹ́ ,o yọ Ààrẹ́ Donald Trump dànù lórí ẹ̀rọ títí láé
Oju opo ibaranisọrọ Twitter fi gbegi dina oju opo aarẹ Amẹrika Donald Trump titi lae nitori ewu ti Trump le ṣe nipa lilo opo rẹ lati da ikọlu silẹ.
Twitter sọ pe awọn be igbesẹ yi lẹyin tawọn ṣe ''agbeyẹwo finifin lori awọn ọr to n jade lati oju opo rẹ iyẹn @realDonaldTrump "
Igbesẹ yi n waye lẹyin ti pupọ ninu awọn ilumọọka oju opo ibaraẹnisọrọ ti n yọ Trump ati awọn alatilẹyin rẹ kuro loju opo wọn.
Ṣaaju asiko yi lawọn oloṣelu ati ati gbajumọ lawujọ ti n lọgun lori opo Twitter pe ki wọn yọ Trump kuro nibẹ patapata.
Lọjọbọ to kọja yi ni iyawo aarẹ tẹlẹ Michelle Obama ko si Twitter pe ki wọn dẹkun bi Trump ti ṣe n hu iwakiwa lori opo naa ki wọn si yọ kuro nibẹ.
Ki lo de ti wọn fi yọ ?
Lọjọru ni Twitter gbegi dina oju opo aarẹ Trump fun wakati mejila lẹyin to pe awọn awọn eeyan to yabo ile aṣofin Capitol ni akikanju
Ọgọrọ awọn alatilẹyin rẹ lo yabo ile aṣofin lasiko tawọn aṣofin fẹ fontẹ lu iyansipo Biden gẹgẹ bi aarẹ tara ilu dibo yan ninu idibo aarẹ.
Ikọlu towaye lọjọ yi ṣokunfa iku ọlọpa kan ati araalu mẹrin.
Lẹyin iṣẹlẹ yi niTwitter sọ pe awọn yoo yọ Trump kuro lori opo awọn titi lae to ba fi tako ilana lilo oju opo naa.
Wo ìdí tí Trump fi pinnu láti má lọ síbi ìbúra Joe Biden gẹ́gẹ́ bí ààrẹ Amẹrika tuntun
Fun anfaani ẹyin ti ẹ n beere, n ko lọ si ibi ayẹyẹ ifilọlẹ ijọba Joe Biden ati ibura rẹ gẹgẹ bi aarẹ tuntun orilẹede Amẹrika logunjọ oṣu yii.
Aarẹ ilẹ Amẹrika Donald Trump lo fọrọ yii lede lẹyin ti ẹgbẹ oṣelu alatako, Democrat n gbimọ lati yọọ nipo.
Ikọlu ile igbimọ aṣofin to wa ni Capitol nibi ti awọn ololufẹ Trump ti yabo awọn aṣofin eyi ti ẹmi eeyan marun ti lọ si bayii lo ṣe okunfa igbesẹ ẹgbẹ Democrat lati beere fun iyọnipo Trump.
Ẹgbẹ oṣelu Democrat ni Trump gbọdọ kọwe fi ipo silẹ, bi bẹẹ kọọ awọn yoo kuro.
Ẹwẹ, iwe ofin ilẹ Amẹrika fun igbakeji aarẹ lagbara lati ṣe ojuṣe aarẹ ti aarẹ ko ba lanfaani lati wa nibi ifilọlẹ ijọba aarẹ tuntun.
Aarẹ Trump ko ṣai bẹnu atẹ lu iṣẹlẹ Capitol ninu fidio kan to ṣe nibi to ṣeleri pe eto igbejọba kalẹ fun Biden yoo lọ ni irọwọ-rọsẹ.
A ti fòfin de Trump lórí Facebook àti Instagram lẹ́yìn ìkọlù ilé aṣòfin ní Capitol- Zuckerberg
Oludasilẹ oju opo ayelujara Facebook ati Instagram, Mark Zuckerberg ti kede igbesẹ ileeṣẹ naa lati fofin de Aarẹ Donald Trump lori oju opo ayelujara naa.
Ọgbẹni Zuckerberg ṣalaye pe titi ti Trump yoo fi gbejọba fun Joe Biden to wọle gẹgẹ bi aarẹ tuntun orilẹede Amẹrika ni Trump ko fi ni lanfaani lati lo Facebook ati Instagram.
O ni eleyi ko ṣẹyin rogbodiyan ti ileeṣẹ naa gbagbọ pe Trump lo ṣagbatẹru rẹ nibi tawọn ololufẹ rẹ ti yabo ile aṣofin ilẹ Amẹrika ni Capitol.
- Afeez Ọwọ: Èmi kọ́ ni mo kọ́kọ́ làwòrán Orisabunmi, ẹ ti ṣe wá rangun mọ́ mi?
- "Ikọ́ lásán ló pa Orisabunmi"
- Orisabunmi ti jáde láyé, ohun tí a mọ̀ nípa ayé àti ikú rẹ̀ nìyí
- COVID-19 pa èèyàn márùn ún, ènìyàn 1664 míràn tún ṣẹ̀ṣẹ̀ lùgbàdì ààrùn náà ní Nàìjíria
- Èèyàn kan kú, ẹni mẹ́ta farapa nínú àkàsọ̀ ìgbàlódé(lift) tó já ní Cocoa House n'Ibadan
- Àwọn aṣòfin àpapọ̀ l'Amerika fa ìrètí Donald Trump ya, wọ́n buwọ́lu Joe Biden gẹ́gẹ́ bí ààrẹ
Iroyin kan tiẹ sọ pe eeyan mẹrin lo gbẹmi mi nibi iṣẹlẹ naa nigba tawọn olofẹhonuhan kọlu awọn agbofinro.
Awọn olufẹhonuhan ọhun yabo ile aṣofin lati ṣe idiwọ fawọn ọmọ ile lati fontẹ lu idibo Biden gẹgẹ bi aarẹ tuntun ilẹ Amẹrika.
Amọ pabo ni gbogbo akitiyan wọn jasi nori wọn pada fontẹ lu idibo to gbe Biden wọle, koda Igbakeji Aarẹ, Mike Pence lo ṣoju Trump nibẹ.
Zuckerberg ni awọn ti faye gba Trump lati lo facebook ati Instagram lati sọ oriṣiiriṣii ohun to wu u lati igba to ti wọle gẹgẹ bi aarẹ Amẹrika.
Ṣugbọn o ni awọn ko ni gba ki Trump maa oju opo facebook ati Instagram lati maa da rogbodiyan silẹ lọwọ akoko perete to ku fun un ti yii lo gẹgẹ bi aarẹ Amẹrika.
Àwọn aṣòfin àpapọ̀ l'Amerika fa ìrètí Donald Trump ya, wọ́n buwọ́lu Joe Biden gẹ́gẹ́ bí ààrẹ
Ileegbimọ aṣofin orilẹede Amẹrika ti buwọlu Joe Biden ati Kamala Harris gẹgẹ bi aarẹ ati igbakeji aarẹ tuntun lorilẹede Amẹrika.
Awọn aṣofin apapọ naa buwọlu awọn ibo isọri-isọri lẹyin ti ile aṣofin agba ati aṣọju da awọn aba to tako esi ibo ni ipinlẹ Pennsylvania ati Arizona nu.
Awọn ololufẹ aarẹ to n fipo silẹ, Donald Trump ya wọ ile aṣofin apapọ naa ni ọjọru ti wọn si da eto igbọwọle esi idibo naa ru ki o to di pe awọn aṣofin pada sẹnu ijoko lati buwọlu esi idibo naa loru mọju Ọjọbọ lẹyin ti awọn agbofinro ti le awọn oluwọde naa sita.
Ki ni Aarẹ Donald Trump n sọ bayii?
Nibayii, aarẹ Donald Trump ti kede pe eto ayipada iṣejọba yoo waye ni irọwọ rọsẹ ni Ogunjọ oṣu kini ọdun yii.
Ninu atẹjade oju opo twitter kan ti ọgbẹni Dan Scavino, ọkan lara awọn amugbalẹgbẹ aarẹ Trump fi sita, O ni:
"Bi o tilẹ jẹ wi pe n o faramọ abajade idibo yii, ti awọn ẹri to wa nilẹ si n fihan pe bẹẹ lo ri, amọṣa eto ayipada iṣejọba yoo waye ni irọwọ rọsẹ ni Ogunjọ oṣu kini ọdun yii."
Aarẹ Trump ko lee lo oju opo Twitter ara rẹ lati fi gbe atẹjade rẹ naa sita nitori ileeṣẹ Twitter ti gbẹsẹ le oju opo rẹ, lẹyin ti o sọ awọn ọrọ ti ọpọ onwoye wo pe o ṣokunfa wahala to bẹ silẹ nileegbimọ apapọ orilẹede naa l'Ọjọru.
Báyìí ni àwọn olórí ní àgbáyé ṣe fèsì sí wàhálà tí àwọn alátìlẹyìn Trump fà
Lọjọru ni okiki kàn pe awọn alatilẹhin Aarẹ ilẹ America, Donald Trump fi agidi wọ ile aṣofin orilẹ-ede naa, Capitol Hill, ti wọn si bẹrẹ si ni pariwo "Trump la fẹ".
Asiko yii gan-an ni apapọ ile aṣofin mejeeji ń ṣe ijiroro papọ lati buwọlu awọn esi idibo apapọ to waye lọdun 2020, ati iyansipo Joe Biden gẹgẹ bi aarẹ tuntun.
Lasiko iwọde naa to pada di rogbodiyan, awọn ọlọpaa yinbọn obinrin kan, eeyan mẹta mii si kú nitori iṣẹlẹ pajawiri to de ba ilera wọn.
Gbogbo eyi waye lẹyin ti Aarẹ Trump sọ ọrọ kan lọjọ naa, nibi to ti kesi awọn alatilẹhin rẹ lati ya lọ si Capitol fun ifẹhonuhan.
Awọn olori orile-ede kaakiri agbaye si ti n koro oju si iṣẹlẹ naa.
Aarẹ Naijiria tẹlẹ, Goodluck Jonathan
Aarẹ orilẹ-ede Naijiria nigba kan, Goodluck Jonathan sọ pe ko tọ ọ ki erongba tabi afojusun ẹnikẹni nidi oṣelu mu itajẹ silẹ dani, botilẹjẹ pe ko darukọ America ninu ọrọ rẹ.
O ni "o san lati fìdírẹmi , kí alaafia si jọba, ju ki eeyan o de ipo àṣẹ lọna to mu ẹ̀mí eeyan lọ.
Olootu ijọba Canada, Justin Trudeau
Olootu ijọba orilẹ-ede Canada, Justin Trudeau ṣọ pe" iporuru ọkan ati ibanujẹ ni iṣẹlẹ to waye ni America, to mule ti wa, jẹ fun awọn eeyan ni orilẹ-ede mi
"Iwa ipanle ko le bori nkan ti awọn eniyan n fẹ lailai. Ijọba awaarawa gbọdọ fẹṣẹ mulẹ, bẹẹni yoo si ri."
Olootu ijọba orilẹ-ede UK, Boris Johnson
Olootu ijọba orilẹ-ede United Kingdom, Boris Johnson sọ pe nkan itiju ni iṣẹlẹ to waye ni America jẹ́, nitori pe ijọba awaarawa ni orilẹ-ede naa fẹ jakejado agbaye.
" O se pataki bayii pe ki gbigbe ijọba kalẹ lọ ni alaafia."
Aarẹ ajọ ilẹ Yuroopu, Ursula von der Leyen
Aarẹ ajọ ilé Yuroopu, Ursula von der Leyen sọ pe gbigbe agbara kalẹ pẹlu alaafia lo ṣe pataki julọ.
"Mo ni igbagbọ ninu okun ti ilẹ America ati isejọba awaarawa rẹ ni... Joe Biden lo bori ninu idibo naa."
Ọga Agba ninu ajọ NATO, Jens Stoltenberg
Ọga Agba ajọ NATO, Jens Stoltenberg sọ pe ki wọn o bọ̀wọ̀ fun esi idibo aarẹ ilẹ America.
Minisita akọkọ ni orilẹ-ede Scotland, Nicolas Sturgeon
Nicola Sturgeon sọ lori ayelujara Twitter rẹ pe ibẹru nla ni nkan to ṣẹlẹ ni America jẹ, ati pe ki itiju ba awọn to pilẹ rogbodiyan naa.
Aarẹ igbimọ olusakoso ilẹ Yuroopu, Charles Michel
Aarẹ igbimọ olusakoso nilẹ Yuroopu, Charles Michel sọ pe iyalẹnu nla ni iṣẹlẹ to waye ni Amerika jẹ.
O fi kun ọrọ rẹ pe oun jẹri ilẹ America pe yoo ri daju pe agbara de ọwọ Biden lai mu wahala dani.
Olootu ijọba orilẹ-ede India, Narendra Modi
Olootu ijọba orilẹ-ede India, Narendra Modi naa kọ ọrọ sori ayelujara Twitter pe o jẹ ibanujẹ fun oun nigba ti oun ri iroyin nipa rogbodiyan to waye ni Washington.
O si gba wọn nimọran pe ki wọn o jẹ gbigbe ijọba silẹ pẹlu alaafia tẹsiwaju.
Aarẹ orilẹ-ede Chile, Sebastian Pinera
Aarẹ orilẹ-ede Chile, Sebastian Pinera bu ẹnu ẹtẹ lu rogbodiyan to waye ni Capitol Hill, ati pe orilẹ-ede oun kọ igbesẹ to fẹ ẹ yí isejọba awaarawa pada ni America.
"Ilẹ America ni orilẹ-ede Chile gbarale lati ẹsẹ ofin mulẹ."
Olootu ijọba orilẹ-ede Fiji, Frank Bainimarama
Olootu ijọba orilẹ-ede Fiji to dari iditẹgbajọba lọdun 2006 naa ti faraya lori rogbodiyan to waye ni Capitol Hill.
O ni "iwa ipanle to waye ni Washington lonii jẹ ìwọ̀sí si ijọba awaarawa kaakiri agbaye.
" Isejọba awaarawa tootọ jẹ nkan alumọọni ti orilẹ-ede kankan ko gbọdọ fi ṣeré. O dawaloju pe ilẹ America yoo fi opin si iṣẹlẹ buruku yii laipẹ. "
Àwọn olólùfẹ́ Trump ya bo ilé aṣòfin àpapọ̀ l'Amerika, èèyàn mẹ́rin kú, ọlọ́pàá mẹ̀rìnlá farapa
Obinrin kan ti jade laye lẹyin ti wọn yinbọn fun un ni ọrun lasiko rogbodiyan to waye ni ileegbimọ aṣofin orilẹede Amẹrika lọjọru.
Awọn iroyin abẹle nibẹ kọkọ fihan pe awọn oṣiṣẹ adoola ẹmi gbiyanju lati doola ẹmi arabinrin naa ki awọn ọlọpaa to wa fi idi rẹ mulẹ lẹyin wakati diẹ pe arabinrin naa ti ku nipasẹ ọgbẹ ibọn naa.
Bi o tilẹ jẹ wi pe wọn ko darukọ rẹ, awọn ọlọpaa ni araalu ni kii ṣe ọlọpaa tabi aṣofin.
Awọn aṣofin apapọ orilẹede Amẹrika n joko lati buwọlu esi idibo aarẹ ọdun 2020 ninu eyi ti Joe Biden ti wọle gẹgẹ bi aarẹ, amọṣa awọn oluwọde to jẹ ololufẹ aarẹ Trump to n palẹmọ ati fipo silẹ ya bo gbagede ile aṣofin Capitol ti wọn si bẹrẹ si ni pariwo "Trump la fẹ" ki wọn to fi ipa ja wọ ile naa.
Ki lawọn ohun ti a ṣi mọ lori iṣẹlẹ yii
- Awọn aṣofin apapọ orilẹede Amẹrika n joko lati buwọlu esi idibo aarẹ ọdun 2020 ninu eyi ti Joe Biden ti wọle gẹgẹ bi aarẹ
- Awọn oluwọde naa fi ipa wọ gbagede ile aṣofin apapọ orilẹede Amẹrika ti gbogbo eeyan mọ si 'Capitol building'eyi si mu ki awọn aṣofin o pa iṣẹ ijiroro ti wọn n ṣe lọwọ lori rẹ ti
- Ariwo "Trump la fẹ" ati "A o ni gba" ni ọkẹ aimoye awọn oluwọde naa ti wọn jẹ ololufẹ Aarẹ Donald Trump npa ni olu ilu Amẹrika, Washinghton DC.
- Iwọde naa bẹrẹ lẹyin ti aarẹ Trump ba ọpọ awọn ololufẹ rẹ sọrọ ni Washinghton DC ti oun pẹlu si n pariwo "A o ni gba".
- Bakan naa ni awọn amugbalẹgbẹ rẹ kan ati ọmọ rẹ ọkunrin pariwo "ipa la o fi gba a" seti awọn ololufẹ aarẹ ilẹ Amẹrika naa nibi ipade itagbangba ọhun.
- Eeyan mẹrin ku nibi iwọde naa.
- Ofiisi ati gbagede ijiroro awọn aṣofin agba nibẹ ko bọ lọwọ awọn oluwọde naa pẹlu bi wọn ṣe fi ipa wọ gbagede ijiroro naa ati ọfiisi awọn aṣofin titi kan ọfiisi olori ile aṣofin ni ibẹ ati ijoko igbakeji aarẹ to jẹ olori ile aṣofin agba nibẹ.
- Ko din ni eeyan mẹtala ti awọn ọlọpaa ti mu pẹlu awọn ohun ija oloro marun un.
- Pọ onwoye lo ni ọrọ ti aarẹ Trump atawọn amugbalẹgbẹ rẹ pẹlu ọmọ rẹ sọ lo ṣokunfa iwọde ati idarudapọ naa,
- ko din ni ọlọpaa mẹrinla to farapa lasiko iwọde naa
- Alakoso ilu Washinghton DC, Mayor Browser gbe ofin konile o gbele kalẹ̀ lati agogo mẹfa alẹ ọjọru di owurọ Ọjọbọ ki o to to sun un siwaju lọna ati mu ki alaafia jọba nibẹ.
Ki ni aarẹ ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan, Joe Biden sọ?
Ninu ọrọ to ba awọn eeyan orilẹ€de naa sọ, aarẹ ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan lorilẹede Amẹrika, Joe Biden niọrọ naa kuro ni iwọde o ti di igbimọ-ditẹ-gba ijọba.
O si ke si aarẹ Trump lati mu ẹjẹ to ṣe lati daabo bo iwe ofin orilẹede naa ṣẹ ni[pa fifopin si ikọlu naa.
Ki ni Aarẹ Donald Trump sọ?
Lẹyin ọpọlọpọ wakati ti awọn eeyan ti n ke sii pe ko pẹtu si awọn ololufẹ rẹ ti wọn n ṣe iwọde naa, Aarẹ Trump gbe fidio kan sita lẹyin iṣẹju diẹ ti Joe Biden ke si, nibẹ lo si ti ke sawọn oluwọde naa pe ki wọn "pada si ile wọn."
Trump ṣalaye pe "Mo mọ pe o n dun yin lọkan" ti o si tun ṣi n pariwo pe "wọn ji ibo naa ni"
Amọṣa ọpọ onwoye titi kan awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu rẹ ni ile aṣofin apapọ orilẹede naa atawọn alajọṣepọ rẹ gbogbo ni wọn ti bu ẹnu atẹ lu ihuwasi rẹ paapaa, ọrọ to sọ li owurọ ọjọru eyi ti ọpọ woye pe o ṣokunfa iwọde naa ati ihuwasi aarẹ Trump ni ọpọlọpọ wakati ti iṣẹlẹ naa fi waye.