LASU Best Graduating Student: Wo ẹ̀bùn owó gọbọi tí Sanwo-Olu fún akẹ́kọ̀ọ́ tó gba ipò kínní ní fásítì LASU l'Eko

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Olorin kan lko kọrin pe ''bata rẹ a dun koko ka, ti o ba kawe rẹ.''

Bẹẹ gẹgẹ lọrọ ri fun ọdọkunrin Shotunde Oladimeji Idris, akẹkọọ ile iwe giga fasiti ipinlẹ Eko, LASU to ṣe ipo kinni ninu gbogbo awọn akẹgbẹ rẹ ti wọn jọ kẹkọọ gboye jade.

Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ṣe imọnyi fun Shotunde pẹlu ẹbun miliọnu marun un owo naira.

Ko tan sibẹ o, gomina tun kede iṣẹ nileeṣẹ ijọba ni Marina fun Shotunde.

Ọgbẹni Shotunde, ẹnui ọdun mejilelogun kẹkọọ gboye ninu ẹkọ iadari okowo.

Bakan naa ni Gomina Sanwo-Olu tun fun akẹkọọ to pegede julọ ninu awọn akẹkọọ to gboye ẹkeji ni LASU, Olabanjo Olusola Aanu naa lẹbun miliọnu marun un naira.

Olubanjo to kẹkọọ nipa imọ ẹrọ kọmputa gba ipo 5.0 eyi to tumọ si pe gbogbo maaki lo gba tan an.