Oyo palliatives stealing: Èèyàn mẹ́ta dèrò iléẹjọ́ lórí ẹ̀sùn jíjí ẹrù palíétìfù covid-19 ìpínlẹ̀ Oyo tà

Awọn oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ Oyo mẹta ti dero ileẹjọ lori ẹsun pe wọn ji ohun elo iranwọ fun araalu lori coronavirus ta.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo, SP Olugbenga Fadeyi, lo fidi ọrọ yii mulẹ fun BBC Yoruba.

Awakọ pẹlu ipinlẹ Oyo, Ọgbẹni Adebiyi Azeez, Ọgbẹni Sunday Akinleye ati Kafayat Babalola ni wọn fẹsun kan pe wọn gbimọ pọ ta ogoji baagi ṣuga ninu ẹru palietifu covid-19 ipinlẹ Oyo.

Ẹsun onikoko mẹta ole jija, igbimọpọ ati gbigba ẹru ole.

Ọgbọnjọ oṣu kejila ọdun 2020 ni wọn sọ pe awọn mẹtẹẹta gbimọ pọ da ọran yii ni ẹka ijọba to n ri si ọrọ ijọba ibilẹ ati ọrọ oye nipinlẹ Oyo.

Ileeṣẹ ọlọpaa sọ fun ileẹjọ Majisireeti to wa ni Iwo Road pe awọn eeyan yii lo ọkọ ijọba lati ko ẹru palietifu lọ ta fun ẹni to ra a.

Olupẹjọ ASP Sunday Ogunremi ṣalaye pe ẹru tawọn eeyan mẹta yii ji ta to ẹgbẹrun lọna ọgọta owo naira.

Ọgbẹni Ogunremi tun sọ wi pe irufẹ ẹru bẹẹ ko wa fun tita.

Awọn mẹtẹẹta sọ pe awọn ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan awọn.

Adajọ Majisireeti Ọgbẹni Taiwo Oladiran fun awọn mẹtẹẹta ni beeli lẹyin ti ẹnikọọkan wọn san ẹgbẹrun lọna ogun naira.

Adajọ Oladiran ti sun igbẹjọ si ọjọ kẹjọ oṣu keji ọdun 2021 yii.