Manchester United vs Crystal Palace: Manchester United fi orí kó ògúlùtu ìyà olójú mẹ́ta sí ẹyọkan lọ́wọ́ Crystal Palace

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn agba bọ wọn ni aile ja nii jẹ ojude baba mi o de ihin; ibi gbogbo nii gba alagbara o.
Bẹẹ gẹlẹ lọrọ ri ni papa iṣire Old Trafford loni nigba ti Manchester United gbalejo Crystal palace ni ibuba rẹ.
Amọṣa nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju keje ni Townsend, atamatase Crystal palace gba goolu akọkọ wọle.
Gbogbo igbiyanju akọnimọọgba Manchester United, Olegunner Solkjaer atawọn agbabọọlu rẹ lati yii oju ọrọ naa pada lo n jasi pabo.
Ni gba ti ifẹsẹwọnsẹ naa tun wọ iṣẹju kẹtalelaadọrin ni Crystal palace ba tun fọba lee pẹlu goolu pẹnariti nigba ti agbabọọlu ọwọ ẹyin fun Manchester, Lindelof fi ọwọ gbe bọọlu loju ile rẹ.
Ayew lo kọkọ gba pẹnariti naa to si gbaa si ọwọ aṣọle Mancxhester United ki alamojuto ifẹsẹwọnsẹ naa, Martin Atkinson to pe fun atungba lẹyin ayẹwo aworan VAR, eyi ti William Zaha wa gba wọle.
Manchester united da ẹyọkan pada pẹlu agbabọọlu tuntun ti wọn ṣẹṣẹ ra, Van de Beek nigbati ifẹsẹwọnsẹ naa wọ ọgọrin iṣẹju .
Amọṣa, Crystal Palace jẹ ko di mimọ pe ko tii rẹ awọn ati pe ayo ṣi wa lara awọn nigba ti Zaha ti gba goolu kẹta wọle ni iṣẹju karundinlaadọrun.












