Seyi Makinde: Àwọn jàǹdùkú Mali ń gba Saki wọlé àmọ́ Amotekun kápá wọn

Gomina Seyi Makinde, ti ipinlẹ Oyo ti kede pe awọn agbesunmọmi ti n gba agbegbe Oke Ogun nipinlẹ naa wọ ẹkun Iwọ Oorun Guusu Naijiria.

Gomina Makinde sọ ọrọ yii lasiko to ṣe abẹwo silu Saki pẹlu afikun pe awọn agbesunmọmi naa, to fi mọ awọn janduku agbebọn lati orilẹ-ede Mali ati awọn orilẹ-ede mii ni Iwọ Oorun Afirika, n wọle lati ibode to wa ni Saki.

O ni ọrọ awọn janduku agbebọn jẹ ọkan lara ipenija ti iṣakoso rẹ n doju kọ.

Amọ ṣa, o ni ifilọlẹ ikọ alaabo Amotekun ti n so eso rere, nitori pe ikọ naa ti le diẹ lara awọn janduku to n ni awọn olugbe ipinlẹ Oyo lara, jade.

O ṣalaye pe ọrọ awọn janduku naa ti kuro ni ti ipinlẹ Oyo nikan, nitori pe ibode agbaye lo wa ni ilu Saki, eyi ti awọn janduku lati Mali n gbiyanju lati ma a gba wọle.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Igba akọkọ kọ niyii ti iru iroyin yii n jade sita nipa pe awọn agbesunmọmi ti wọ ilẹ Yoruba.

Oṣu diẹ sẹyin ni Aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba, Gani Adams ke gbajare pe oun kẹẹfin nkan bẹ ẹ.

Bakan naa ni gbajugbaja ajafẹtọ ẹni kan, Sunday Igboho naa sọ bẹ ẹ laipẹ yii, to si ni oun ati awọn oṣiṣẹ alaabo kan lo le awọn janduku naa kuro ninu igbo kan ni agbegbe Oke Ogun nipinlẹ Oyo.