Isho Pepper: Isola Ogunsola pẹ̀lú àfihàn àwọn ìyàwó tó jẹ́ igi lẹ́yìn ọgbà fun un nínú iṣẹ́ tíátà

Yoruba ni igba ko lọ bi orere, ako o tọ lọ bi ọpa ibọn, nitori saa laa ni, ẹnikan ko lo ile aye gbo.

Bẹẹ ni ọrọ ri pẹlu gbajugbaja oṣere tiata, Olusola Isola Ogunsola, ti ọpọ eeyan mọ si Isho Pepper ati awọn aya rẹ, ti wọn dìjọ mi agbo tiata Yoruba logbo-logbo laarin ọdun 1965 si 1992.

Ọjọ Aje, ọjọ Kejidinlọgbọn osu Kejila ọdun 1992, eyi to pe ọgbọn ọdun bayii ni iku pa oju akọni osere naa de, amọ bi onirese rẹ ko ba fin igba mọ, sibẹ awọn eyi to ti fin ko le parun.

Bi o tilẹ jẹ pe Isho Pepper ati meji ninu awọn iyawo marun-un to n ba a ṣe ere tiata ti jade laye, sibẹ o yẹ ki awọn ọdọ iwoyi mọ nípa igbe aye ati iku akọni oṣere tiata naa, to fi mọ ipa to ko si idagbasoke iṣẹ tiata nigba aye rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ta ni Isho Pepper?

Apetan orukọ gbajumọ oṣere tiata naa ni Olusola Isola Ogunsola, tii ṣe ọmọ bibi ilu Abeokuta, to jẹ olu ilu ipinlẹ Ogun bayii ni guusu iwo oorun Naijiria..

Ọjọ Kẹrinla, oṣu Kọkanla, ọdun 1942 ni Samuel ati Abigail Ajike Ogunsola bi akọni oṣere tiata naa sile aye, to si jẹ ọmọ agboole Baala Dasaolu lẹyin mọsalasi Ita Igbẹyin ladugbo Oke Itoku.

Olusola ni abigbẹyin ninu ọmọ mẹrin ti awọn obi rẹ bi, abule Olokuta, ni ẹba Alahọ to wa nijọba ibilẹ Oluyole nilu Ibadan si lo ti lo igba kekere rẹ, ibẹ si lo ti lọ sile ẹkọ alakọbẹrẹ Christ School, Olokuta.

Lẹyin to pari iwe mẹfa rẹ lo pada si Abeokuta fun eto ẹkọ girama, to si lọ si Abeokuta Grammar School nibi to ti bẹrẹ afihan ifẹ rẹ si ere tiata lasiko ti ọpọ eeyan korira isẹ naa, ti wọn si n rii awọn osere tiata bii alagbe.

Nitori idi eyi, ọpọ ipenija ni Olusola koju nidi iṣẹ to yan laayo ọhun, tawọn ẹbi ati ọrẹ si kọ ẹyin sii.

Amọ, niwọn igba to jẹ pe yeye ọmọ nii gba ọmọ, iya rẹ, Abigail Ajike ṣe atilẹyin alailẹgbẹ fun un nidi iṣẹ naa, ti Olusola si dara pọ mọ ẹgbẹ oṣere tiata Akin Ogungbe to wa nilu Abeokuta lọdun 1959, lẹyin to pari ẹkọ girama.

Lara awọn ti wọn dijọ kọ iṣẹ tiata lọdọ Akin Ogungbe lasiko naa ni Jimoh Aliu, Charles Olumo (Agbako), oloogbe Afolabi Afolayan (Jagua), ati Femi Adeyemo (Baba n gba life).

Olusola kuro lọdọ ọga rẹ lọdun 1965 lati da ẹgbẹ tiata tara rẹ silẹ, to si n kọrin, lu ilu, jo ati sere.

O fẹ ọpọ iyawo lati maa ba sere, ti wọn si n tẹle yika gbogbo ilu to ba n lọ.

Isho Pepper jẹ ọkan lara awọn oṣere tiata to kọkọ ṣe ere itage lori amohunmaworan pẹlu awọn gbajumọ oṣere tiata miran bii Hubert Ogunde, Baba Sala, Baba Mero, Kola Ogunmola, Oyin Adejobi, ati Adeyemi Afolayan.

Bakan naa lo ṣe ọpọ ere ninu iwe Atọka, oun naa si tun ni oṣere tiata kẹrin to ya ere sinima lẹyin Hubert Ogunde, eyi to gbe e lọ si orilẹ-ede United Kingdom (UK).

Ọpọ eeyan ni Isho Pepper kọ ni iṣẹ tiata, lara wọn ni Samson Eluwole (Jinadu Ewele), oloogbe Adeniyi Orofo (Ewejoko) ati oloogbe Gbolagade Adedeji (Aro onifila gogoro).

Olusola jẹ ọkan lara awọn agba ọjẹ oṣere tiata to da ẹgbẹ awọn oṣere taa mọ si ANTP silẹ lọdun 1976, to si jẹ akọwe owo akọkọ fun ẹgbẹ naa laarin ọdun 1976 si 1989, bẹẹ lo tun gbe ọpọ ere jade ni ede Yoruba.

Lara awọn ere naa ni Fere bi Ekun, Alaafin Aganju, Agbalowomeri, Efunsetan Aniwura, Ibu Olokun, Koseegbe, Ajaloleru, Iyawo Alalubosa ati bẹẹ bẹẹ lọ, ko si fẹ ẹ si ilu kan ni Naijiria ti Isho Pepper ko gbe ere tiata de.

Lasiko ti Olusola n dabira lati gbe aṣa, ede ati ìṣe Yoruba larugẹ sii, ni iku ja ẹmi rẹ gba lairo tẹlẹ lasiko aisan ranpẹ lẹni aadọta ọdun, ni ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kejila, ọdun 1992.

Àwọn ìyàwó tó jẹ́ igi lẹ́yìn ọgbà fún Isola Ogunsola

Mojisola Ogunsola:

Oloogbe Mojisola Ogunsola ti awọn eeyan mọ si Iya Alakara nigba aye rẹ, ni iyale patapata ninu awọn iyawo Isho Pepper, to si maa n tẹle ọkọ rẹ lọ ṣe ere tiata kaakiri.

Ẹni ọgọta ọdun ni oloogbe naa nigba to jade laye lẹyin iku ọkọ rẹ, to si ko ipa manigbagbe ninu iṣẹ tiata pẹlu ọkọ rẹ.

Iyabode Ogunsola

Iyabode Ogunsola ni ọpọ eeyan mọ si Efunsetan Aniwura, to si jẹ gbajumọ oṣere lobinrin lasiko ti ọkọ rẹ wa laye.

Efunsetan si ni gbogbo aye mọ julọ ninu awọn aya oloogbe Isola Ogunsola sugbọn lọwọ lọwọ bayii, o ti dagbere fun iṣẹ tiata, to si di oniwaasu ọrọ Ọlọrun.

Ọpọ ere sinima, fiimu agbelewo ati ere itage ni Efunsetan ti kopa ninu rẹ, ko si si ẹni to ri obinrin naa lori pẹpẹ iwaasu, ti ko ni maa ranti awọn ara manigbagbe to ti da ninu isẹ tiata.

Laipẹ yii si lo ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ loke eepẹ.

Funmilayo Ogunsola:

Ijewuru ni adape orukọ Funmilayo Ogunsola ninu iṣẹ tiata, to si ti silẹ bora lọdun 2019 lati ipasẹ aisan ẹjẹ ruru to ba fínra.

Isẹ kekere kọ ni Funmilayo ko nidi isẹ tiata loju aye ati lẹyin iku ọkọ rẹ, ki iku to yọ ọwọ rẹ lawo lasiko aisan ranpẹ. Orukọ Ijẹwuru to fi silẹ si lo di manigbagbe titi di oni yii, tawọn eeyan fi n ranti rẹ.

Funmilayo ni iyawo kẹta Isho Pepper, toun naa si ko ipa ti ko kere si idagbasoke iṣẹ tiata.

Yetunde Ogunsola

Arẹwa obìnrin, apọnbeporẹ, ni Yetunde Ogunsola nigba to wa lewe, ti Isola Ogunsola fẹ bii aya.

O sa ipa rẹ lati mu agbega ba iṣẹ ọkọ rẹ, tii ṣe ere tiata, ti ọpọ eeyan si mọ gẹgẹ bii Iyawo Alalubosa tabi Ayoni, nitori ipa to ko ninu ere naa Iyawo Alalubosa.

Titi di akoko yii, Yetunde Ogunsola sì n kopa ninu ere tiata lorisirisi, oun naa si ti di Ajihinrere.

Bolatito Ogunsola

Bolatito ni iyawo kekere to gbẹyin ninu awọn iyawo Isho Pepper, Aina Orosun si ni ọpọ eeyan mọ si.

Bolatito ko ipa manigbagbe ninu iṣẹ tiata lasiko ti ọkọ rẹ, Ishola Ogunsola wa loke eepẹ, sugbọn lẹyin ti ọkọ rẹ ku tan, oju obinrin naa ko han mọ ninu ere tiata.

Nibayi to pe ọdun mejidinlọgbọn ti Olusola Isola Ogunsola jade laye, to si fi ọpọ ọmọ silẹ saye lọ, a si n gbadura pe ki ọba oke tẹ si afẹfẹ rere, ko si di idile to fi silẹ saye lọ mu sinsin.