You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
#justiceforDonDavis: Orí ayélujára n gbóná janjan fún ariwo ìdájọ́ fún akẹ́kọ̀ọ́ kan níléèwé Kumuyi
Ori ayelujara n gbona janjan lọwọlọwọ ni Naijiria, nitori bi awọn ọmọ orilẹ-ede yii kan se n polongo fun idajọ ododo fun ọmọdekunrin kan ti awọn akẹkọọ to julọ kan se fi ipa ba lopọ.
Don Davis Iniobong Archibong, jẹ ọmọ ọdun mọkanla, to si wa ni ipele eto ẹkọ kinni JSS 1 nile ẹkọ Deeper Life High School, nipinlẹ Akwa Ibom.
Ile ijọsin Deeper Life Bible Church, to jẹ ti Alufa W.F Kumuyi lo ni ile ẹkọ naa, ti oriṣiriṣi akọle bi #justicefordondavis #deeperlifehighschool ati Pastor Kumuyi ni ariwo rẹ n lọ lori Facebook ati Twitter.
Iya ọmọdekunrin ọhun, Deborah Okezie ti kọkọ fi fidio kan sita, ninu eyi to ti fi ẹsun kan pe, awọn akẹkọọ ọkunrin kan to wa ni kilaasi agba nile ẹkọ naa fi ipa ba ọmọ oun lopọ, lai ti ju oṣu meji to wọ ile ẹkọ naa.
Ninu fidio naa ti Deborah Okezie fi sori ayelujara Facebook lọjọ kọkandinlogun, oṣu Kejila, amọ to pada yọ kuro nibẹ, lo ti n fi ọrọ wa ọmọ rẹ, Don David lẹnu wo.
Ninu fidio naa, ọmọkunrin naa sọ pe awọn alaṣẹ mu oun kuro ni ilegbe awọn akẹkọọ to wa ni kilaasi kekere, nitori pe oun n tọ sile, ti wọn si ni ki oun lọ ma a sun si ọdọ awọn akẹkọọ to wa ni SS 1 ati SS 2.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ẹ wo àwọn èèkàn eléré ìdárayá tó bá ọdún 2020 lọ
- Wo ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ igba tí Primate Ayodele gbé síta fọ́dún 2021
- ₦9.4bn ní rìbá táwọn agbẹjọ́rò fún adájọ́ láàrín ọdún mẹ́ta - ICPC
- Ìdí rèé tí ẹ̀mí mi kò fi bọ́ sínú ìdìtẹ̀ gbàjọba tó pa Muritala Muhammed - Obasanjo
- Wọ́n gún ọkùnrin kan lọ́bẹ pa torí ó tako yínyin báńgà sínú Mọ́ṣálásí
- Àwọn àṣà tó milẹ̀ lọ́dún 2020 pẹ̀lú ìtàn lórí bí wọ́n ṣe jáde
- Kò bá wù mí kí n padà sí àwọ̀ tí Ọlọ́run dá mi, wàhálà ni ara bíbó - Bobrisky
- N kò tíì pa ọ̀rọ̀ ìfẹ́ tì, bí mo tilẹ̀ ti kúrò nílé ọkọ - Mercy Aigbe
O sọ pe ni ileegbe awọn akẹkọọ agba naa, ni wọn ti bọ ṣokoto penpe oun, ti wọn si ki ika ọwọ ati ẹsẹ wọn sinu iho idi oun.
Don Davis fikan ọrọ rẹ pe, wọn ko fun oun ni ounjẹ, wọn si tun dẹru ba oun pe "oun yoo di oku, toun ba fi le ṣaroye kankan".
Ileeṣẹ eto ẹkọ nipinlẹ Akwa Ibom, ti kọkọ bẹrẹ iwadii lori ọrọ naa, lẹyin ti ijọba ipinlẹ naa paṣẹ logunjọ, oṣu Kejila, pe ki iwadii waye lori awọn ẹsun ti Arabinrin Deborah fi sita.
Ṣugbọn ninu ọrọ ti Arabinrin naa tun sọ ninu fidio mii to fi sita ni ọjọ kẹrinlologun, oṣu Kejila, o ni diẹ lo ku ki wọn o lu oun ni ọfiisi Kọmisanna fun eto ẹkọ nipinlẹ naa, lasiko to ni ki oun wa sibẹ.
O ni wọn tun dunkooko mọ oun lati yọ fidio naa kuro.
Amọ BBC ko ti le fi idi ẹsun tuntun yii mulẹ, nitori pe a ko ti i gbọ ọrọ lẹnu kọmisana naa.
Bakan naa ni Olukọ Agba fun ile ẹkọ Deeper Life High School, Ndidi Solomon, sọ fun BBC pe, wọn ti fun oun ni iwe idaduro ranpẹ lẹnu iṣẹ, amọ ko sọ ju bayii lọ nitori pe ijọba ti gba akoso ọrọ naa.
Don Davis wa nileewosan lọwọlọwọ
Lati bi ọjọ diẹ sẹyin ni Don Davis ti wa ni ileewosan, nibi to ti n gba itọju. Iya rẹ si sọ fun BBC pe yoo kuro nileewosan ni ọla.
Bakan naa lo tun ṣeleri pe oun yoo fi fidio mii sita, nibi ti ọmọ oun fun'ra rẹ yoo ti sọrọ laijẹ pe oun gba ẹnu rẹ sọrọ.
O sọ pe agbẹjọro oun ti n ṣiṣẹ lori ọrọ naa, ati pe idajọ ni oun n fẹ ko fẹsẹ mulẹ.
Deborah Okezie ṣalaye pe oun fẹ ki idajọ waye lori ọrọ naa, fun gbogbo awọn ọmọ to ti la nkan bẹ ẹ kọja ri.
O ni ọpọlọpọ awọn obi kan ti ba oun sọrọ pe, iru nkan bẹ ẹ ṣẹlẹ si ọmọ wọn, ṣugbọn ibẹru ni ko jẹ ki wọn o sọ sita.
Kini ijọ Deeper Life sọ lori ẹsun yii?
Ni ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kejila, ni awọn alaṣẹ ijọ Deeper Life Bible Church fi atẹjade kan si ori ayelujara Twitter ijọ naa pe, iwadii ti bẹrẹ lori ọrọ naa.
"Ẹnikẹni to ba jẹbi ninu ọrọ naa, yala akẹkọọ tabi oṣiṣẹ ileewe, ko ni lọ laijiya."
Wọn fi kun ọrọ wọn pe, gbogbo ìlú ni yoo mọ abajade iwadii naa.