Mercy Aigbe: Ara ń ta mí lórí bí Èṣù ṣe dojú kọ ìgbéyàwó tó ń dàrú lójoojúmọ́

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ilumọọka osere tiata nni, Mercy Aigbe ti sọrọ nipa igbeyawo ati iha to kọ si.

Osere tiata naa, to sọrọ naa loju opo Instagram rẹ tun ni oun sẹsẹ gbe sinima kan jade ni to da lori igbeyawo, eyi to gbe akọle rẹ ni 'Ki ni Igbeyawo'.

Mercy ni bi o tilẹ jẹ pe oun ti kuro lọdọ oun, sibẹ oun ko tii sinmi lori ọrọ ifẹ, oun ko si lee pa ifẹ ti laelae.

"Awọn eeyan maa n bi mi pe Mercy, se o ko ni pada lọ sọdọ ọkọ rẹ mọ ni tabi tun ọkọ miran fẹ? Amọ otitọ ibẹ ni pe n ko mọ idahun fun ibeere yii.

Okoowo mi ni mo gbajumọ, mo n tọju awọn ọmọ mi ati isẹ ti mo yan laayo. Nigba to ba ya, ohunkohun to ba yọju nipa ọrọ ifẹ ati igbeyawo, maa mọ bi maa se yanju rẹ."

Gẹgẹ bii osere sinima, a da bii ojisẹ Ọlọrun to yẹ ko maa tọ awọn araalu sọna ni, ki wọn si maa ri ẹkọ kan abi omiran kọ ninu awọn ere ta ba n gbe jade.

Mercy ni igbeyawo ko yẹ ko dabi igba ti a mu ni lẹru. O ni o yẹ ko jẹ ifọwọsowọpọ ni , ki ẹnikan ninu igbeyawo gba ẹnikeji laaye lati dagba, ko si le da nnkan se.

O fikun pe o maa n bani ninu jẹ bi ọpọ igbeyawo se n fori sanpọn, paapa nitori bi awọn eeyan kan se maa n se igbeyawo nitori awọn idi ti ko yẹ.

"Bi igbeyawo se n dojude n ba mi lẹru. O dabi ẹni pe esu mọọmọ dojukọ igbeyawo bayii ni, to si n baa jẹ, ti ọpọ lọkọ-laya si n ronu pupọ nipa igbeyawo wọn to fori sanpọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Osere tiata naa wa n gbarata pe ki lo de tawọn eeyan yoo fi owo iyebiye ra asọ ẹbi fun ayẹyẹ igbeyawo amọ lẹyin osu diẹ ni iru igbeyawo bẹẹ yoo fi ori sanpọn.

O wa n gba wọn nimọran pe ti wọn ba ti ri daju pe awọn ko ba ara awọn mu tabi ti iwa wọn ko papọ, yoo dara ki wọn mase se igbeyawo.

Bakan naa ni Mercy ni ifarada se koko ninu igbeyawo, ti tọkọtaya yoo si ni iwa ipamọra amọ oun tako igbeyawo to ba ni iwa ipa ninu, eyi to le mu okun ẹmi wọn lọ lojiji.

"Lootọ ni awọn ọkunrin jẹ ori amọ o yẹ ki wọn mọ pe awa obinrin ni ọrun, bi ko ba si si ọrun, ori ko le duro, nitori naa lo se yẹ ki asọyepọ ati igbọraẹniye wa laarin lọkọ-laya."

O wa gba awọn tọkọ-taya nimọran pe ki wọn sa asala fun ẹmi wọn nibi ti iwa ipa ba ti wa ninu igbeyawo, ẹ mase fara daa tabi duro sibẹ.

"Awọn ọrọ eebu mii gan buru ju ki wọn na eeyan lọ. Ti ọkan ninu lọkọlaya ba si maa n binu pupọ, iru ẹni bẹẹ gbọdọ lọ fun igbani nimọran abi itọju."