Mercy Aigbe, Lateef Adedimeji: Ìdáhun yi bọ́bọ́ lẹ́nu àwọn òṣèré

Nibi apejẹ aṣalẹ kan lati fi ami ẹyẹ da awọn oṣere tabi apanilẹrin lọla to waye eyi ti SoundCity ṣagbekalẹ rẹ ni a ti ṣe kongẹ awọn oṣere Yollywood ti ẹ fẹran.

Kété ti akọroyin BBC Yoruba de iwaju gvbajugbaja ọdọ oṣere Lateef Adedimeji ni ẹrin ti bẹrẹ to ti n fi ọgbọn bẹbẹ pe Yoruba oun ko daju to o - eyi tumọ si pe ori itage yatọ si ẹyin itage.

Bakan naa ni mọlumọọka oṣerebinrin Mercy Aigbe naa gbiyanju niwọnba tirẹ lẹyin to n sa lati dahun ibeere to ni ṣe pẹlu ede Yoruba.

Ko yọ oṣere Ayoola Ayolola silẹ toun naa si gbiyanju ni bi o ṣe dantọ mọ ninu ede abinibi rẹ.