Ibadan Jungle Justice: Àwọn èèyàn kan ní alárùn ọpọlọ ni Saheed, tawọn mii ni ajínigbé ni

Fun igba ti ko fẹrẹ ṣee ka mọ bayi lẹnu ọjọ mẹta yii ni ilu Ibadan, iṣẹlẹ idajọ ọwọ miran tun waye.

Eeyan meji ọtọọtọ l'awọn ero dana sun lagbegbe ASAS ni Molete ati Oke Ado ni ilu Ibadan lọjọ Aje.

Agbegbe Oke Ado ni wọn ti kọkọ dana sun ọkunrin kan ki ekeji to waye lagbegbe ASAS ni Molete.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amọṣa, oniruru iroyin lo n waye lori ohun to ṣokunfa bi wọn ṣe dana sun arakunrin ti wọn pa lagbegbe Oke-Ado.

Bi awọn eeyan kan ti isẹlẹ naa soju wọn ṣe n wipe ajinigbe ni Saheed, lawọn miran n wipe kii ṣe ajinigbe, aarẹ ọpọlọ diẹ lo n ṣe e.

Awọn to pe e ni ajinigbe ṣalaye pe, Saheed pọn ọmọlangidi ti ọpọ mọ si 'bebi' si ẹyin, eleyii to maa fi n tan awọn ọmọde lagbegbe naa.

Olugbe agbegbe naa kan la gbọ pe o pariwo sita nigba to ni oun ri Saheed to n tan ọmọ ọdun mẹrin kan pẹlu erongba lati ji gbe. Bi aladugbo wa ṣe mọ pe Saheed fẹ ji ọmọde naa gbe ni, ko tii si ẹni to le sọ.

Eyi ni won pe o mu ki ọpọ ero lagbegbe naa ya bo o.

Ọrọ naa tun le sii nigba ti wọn ni wọn ba ẹgbẹrun lọna igba ati aadọta naira lara rẹ.

Ẹwẹ, ọkan lara awọn olugbe agbegbe Odo Ọna nibi ti wọn ni Saheed n gbe ṣalaye pe, aisan ọpọlọ lo n ba Saheed finra diẹdiẹ, ati pe kii ṣe ajinigbe gẹgẹ bi wọn ṣe sọ.

Ẹni naa ti wọn pe orukọ rẹ ni Bamidele Emmanuel salaye pe, iṣẹ agbaṣe ọkọ fifọ ati agbaru lo maa n ṣe fawọn eeyan lagbegbe naa.

O ni iṣẹ dẹrẹba lo n ṣe tẹlẹ ati pe aisan naa de si i lẹyin ti wọn ji ọkọ bọọsi to n wa lọ.

O ni ọlọkọ bọọsi naa ko gbagbọ pe wọn ji ọkọ naa lọ ni, eyi to mu ko fi Saheed sun ni agọ ọlọpaa; lẹyin to kuro ni agọ ọlọpaa naa ni aisan ọpọlọ naa bẹrẹ.

Awọn ọlọpaa ni iwadii ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa

Iṣẹlẹ idajọ ọwọ ti di eyi to n fi ojojumọ waye ni ipinlẹ Ọyọ bayii to si nkọ lominu nibẹ.

Ileeṣẹ ọlọpaa wa bu ẹnu atẹ lu bi awọn eeyan ṣe n fi idajọ si ọwọ ara wọn bayii, eyi ti wọn ni o ti wa n di lemọlemọ, paapaa ni ilu Ibadan ati ipinlẹ Ọyọ lapapọ.

Atẹjade kan lati olu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ṣalaye pe, kọmiṣọna ọlọpaa ni ipinlẹ naa ti jawe ikilọ ranṣẹ sawọn to kundun idajọ ọwọ nibẹ ati pe ẹnikẹni ti ọwọ ba tẹ yoo kabamọ ṣiṣe bẹẹ.

Aráàlú dá iná sun èèyàn méjì n'Ibadan, orí kó ẹni kan yọ

Eeyan meji ọtọọtọ l'awọn ero dana sun lagbegbe ASAS ni Molete ati Oke Ado ni ilu Ibadan lọjọ Aje.

Amọṣa ori ko eeyan kan miran yọ nigba ti awọn oṣiṣẹ ikọ Amọtẹkun gba a silẹ lọwọ awọn ero to n binu naa.

Awọn ọlọpaa ni ko tii si ẹni to lee sọ pato ohun to ṣẹlẹ tawọn eeyan fi da ina sun awọn mejeeji yii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Iṣẹlẹ idajọ ọwọ ti di eyi to n fi ojojumọ waye ni ipinlẹ Ọyọ bayii,eyi to si nkọ ọpọ eeyan lominu nibẹ.

Eeyan ti ori ko yọ naa ni wọn ṣalaye pe, o ṣi n gba itọju lọwọ nile iwosan awọn ọlọpaa to wa lagbegbe Ẹlẹyẹle ni ilu Ibadan.

Ileeṣẹ ọlọpaa bu ẹnu atẹ lu bi awọn eeyan ṣe n fi idajọ si ọwọ ara wọn bayii eyi ti wọn ni o ti wa n di lemọlemọ bayii ni ilu Ibadan ati ipinlẹ Ọyọ.

Atẹjade kan lati ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ ṣalaye pe, kọmiṣọna ọlọpaa ni ipinlẹ naa ti jawe ikilọ ranṣẹ sawọn to kundun idajọ ọwọ nibẹ ati pe ẹnikẹni ti ọwọ ba tẹ yoo kabamọ ṣiṣe bẹẹ.

Iná ẹ̀lẹ́ńtíríkì pa ọlọ́kadà, obìnrin kan ní Ibadan, àjọ IBEDC ní àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwadìí

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe opo ina mọnamọna ti wo pa ọlọkada kan ati obinrin kan lagbegbe Iwo road ni ilu Ibadan.

Gẹgẹ bi iroyin ṣe sọ, ọlọkada naa ati obinrin ọhun n dunadura lori iye owo ni lasiko ti opo ina naa fi wo luwọn ni ina ara waya ori rẹ si pa wọn.

Awọn eeyan agbegbe naa pe orukọ ọlọkada naa ni Kabiru ṣugbọn wọn ni oluyọle ni ọpọlọọ eeyan mọọ si.

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣe oju wọn ṣalaye pe olounjẹ ni arabinrin naa, o si wa si agbegbe naa ni lati wa gba ẹgbẹrun kan naira ti ọkan lara awọn ọlọkọ ero lagbegbe naa jẹ ni ki iṣẹlẹ buruku naa to ṣẹlẹ.

Ki ni Ileeṣẹina mọnamọna, IBEDC sọ nipa iṣẹlẹ naa?

Amọṣa, ileeṣẹ mọnamọna ẹkun Ibadan, IBEDC ti darukọ awọn ti ina gbe naa ti wọn si pe orukọ wọn ni Ọgbẹni Ọladeji Ọlatunji pẹlu Arabinrin Kẹmi Degoke.

Wọn lawọn ba awọn mọlẹbi wọn kẹdun.

Ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Abamẹta, ọga agba ileeṣẹ mọnamọna lẹkun Ibadan, IBEDC, ọgbẹni Jọhn Ayọdele ni awọn ti n ba awọn mọlẹbi naa jiroro lọna ati tu wọn ninu bi o ti wulẹ o mọ.

Bakan naa lo fi kun un pe igbesẹ ti bẹrẹ lori wiwadii bi iṣẹlẹ naa ṣe ṣẹ ati ohun gan to sokunfa rẹ.