Davido and Burna boy fight in Ghana: Kí ló fa gbas-gbos láàrín Davido àti Burna boy lórílẹ̀èdè Ghana?

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Meji ninu awọn eekan akọrin takasufe lorilẹede Naijiria, Davido ati Burna Boy ba ara wọn wọ ijakadi ni ile ijo kan lorilẹede Ghana.

Iroyin sọ wi pe awọn mejeji yii gbena woju ara wọn nigba ti Burnaboy wọ ile ijo kan nibi ti Davido ti n gbafẹ.

Awọn fidio kan to wa lori ayelujara n ṣe afihan bi Davido ṣe gbarata ṣugbọn ti awọn eeyan n dii mu.

Amọṣa ko si ẹni tii lee sọ ohun gan to fa ija naa ṣugbọn awọn tọrọ naa ṣoju wọn ni Davido ti kọkọ wa ninu ile ijo naa ki Burnaboy to de.

Yatọ si eyi, awọn fidio kan naa tun n fihan pe eekan akọrin miran, Whizkid pẹlu wa ninu ile ijo yii pẹlu ṣugbọn ti ko da si wahala to n lọ naa.

Ohun ti Davido kọ soju Twitter tawọn ololufẹ rẹ fi n gbarata.

Amọṣa, ninu ọrọ kan to fi si oju opo Twitter rẹ, eyi ti ọpọ ri gẹgẹ bi esi si ohun to ṣẹlẹ naa, Davido kọ ọ pe, "Emi yoo kuku fi iṣẹ orin yii silẹ fun yin" eleyii si ti mu ki awọn ololufẹ rẹ maa sọ ọrọ loriṣiriṣi.