You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
2020 in Retrospect: Ajibade Babalade, Michael Ojo, Razak Oyadeyi wà lára àwọn tó kú lọdún yìí
Ọdun 2020 lamilaka, to si jẹ ọdun manigbagbe paapa julọ pẹlu ajakalẹ arun Covid-19 to ṣọṣẹ jakejado agbaye.
Lorilede wa Naijiria, a mọ riri ajakalẹ yii lara pẹlu awọn eeyan ti iku mu ẹmi wọn lọ nitori ajakalẹ arun Coronavirus naa, eyi to tun mu ki idenukọlẹ ba eto ọrọ aje titi di akoko yii.
Bi a ba wo agbo osere ere idaraya, awọn tó ba ọdún yi lọ yala lati ipasẹ Covid-19 tabi nnkan mii, pọ yanturu.
Díẹ ree ninu awọn alaisi ta le tọka si:
Ajibade Babalade:
Lọjọ kẹrin oṣu Kẹsan ni agbẹyin fun ìkọ Super Eagles dagbere faye ni Ibadan .
Babalade, to jẹ ẹni ọdun mejidinlaadọta ṣe aarẹ diẹ, ti won sì gbé lọ sí ilé ìwòsan agba fasiti Ibadan, UCH níbi to padà ku si.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ igba tí Primate Ayodele gbé síta fọ́dún 2021
- ₦9.4bn ní rìbá táwọn agbẹjọ́rò fún adájọ́ láàrín ọdún mẹ́ta - ICPC
- Ìdí rèé tí ẹ̀mí mi kò fi bọ́ sínú ìdìtẹ̀ gbàjọba tó pa Muritala Muhammed - Obasanjo
- Wọ́n gún ọkùnrin kan lọ́bẹ pa torí ó tako yínyin báńgà sínú Mọ́ṣálásí
- Ìjọba kéde ọjọ́ tuntun fún ṣíṣí afárá Third Mainland Bridge
- Àwọn àṣà tó milẹ̀ lọ́dún 2020 pẹ̀lú ìtàn lórí bí wọ́n ṣe jáde
- Kò bá wù mí kí n padà sí àwọ̀ tí Ọlọ́run dá mi, wàhálà ni ara bíbó - Bobrisky
- Nàíjíríà yóò gbóná janjan lẹ́yìn ìbò ààrẹ 2023 àyàfi... - Primate Ayodele sọ àsọtẹ́lẹ̀
- N kò tíì pa ọ̀rọ̀ ìfẹ́ tì, bí mo tilẹ̀ ti kúrò nílé ọkọ - Mercy Aigbe
Ajibade jẹ ogbontarigi agbẹ́yìn to soju Naijiria ninu ikọ Super Eagles, to si ba wọn gba ife ẹyẹ bàbà lọdun 1992 ninu idije AFCON to waye ni Senegal.
Chineme Martins:
Ikú agbabọọlu ẹni ọdun mẹtalelogun yii dun ọpọ eeyan nitori igbagbọ wọn ni pé ti Naijiria ba ni eto ilera tó péye lori papa iṣere Lafia ni, ko bà maa ku.
Lọjọ Kẹjọ oṣù Kẹta ni Martins dagbere faye lasiko Ifẹsẹwọnsẹ ẹgbẹ agbabọọlu rẹ, Nassarawa United ninu liigi bọọlu Naijiria, NPFL.
Sadede ni Chineme daku lori papa ni abala keji ifẹsẹwọnsẹ naa nigba ti Nassarawa United n koju Katsina United.
John Felagha:
Ọgbọnjọ oṣu Kẹjọ ni aṣọle nigba kan ri fún ìkọ U17 ati U20 Naijiria kú ní Senegal.
Felagha jẹ ọkan lára ìkọ Golden Eaglets nigba ti won gba baba ni Switzerland lọdun 2009, bo ti le jẹ wipe ko ribi dé ojú ile lasiko idije naa.
Razak Okedeyi:
Okedeyi jẹ ọkan lára àwọn adari idije bọọlu alapẹrẹ basket ball ni Naijiria ki ọlọjọ to dé.
Bẹẹ lo tun jẹ oguna gbongbo ọmọ ẹgbẹ àwọn rẹfiri bọọlu alapẹrẹ ni Naijiria.
Lasiko idije ti Total sagbatẹru rẹ nibẹrẹ ọdun yii lawọn eeyan ri Okedeyi kẹyin.
Okedeyi jẹ alukoro ẹgbẹ awọn to n gba bọọlu alapẹrẹ nilu Eko ṣaaju ikú rẹ.
Deborah Onu:
Ikú ọmọdebinrin yii jẹ eyi ti a ko ba ti kéde ka ni wọn tete mọ nkan to n ṣe pato.
Ìdí ni pé ọtọ ní nkan t'awon onimọ ilera n tọju rẹ fún amọ nigba ti wọn yóò fi mọ nkan to se gangan, ẹpa ko boro mọ.
Gbajumọ ababọọ̀lu alapẹrẹ ni ọmọ ọdun mẹrindiinlogun naa, to si sẹsẹ fẹ joko kọ idanwo asejade ile ẹkọ girama agba ni, ki iku to pa oju rẹ de.
Ọjọ kejidinlogun osu Kẹrin lo dagbere faye pe o digbose.
Michael Ojo:
Ọmọ Naijiria ati ilẹ Amẹrika yii ku nitori ọkan rẹ to sọsẹ silẹ lasiko igbaradi lori papa ere bọọlu alapẹrẹ.
Ni papa isere idaraya Partizan ti ìkọ Crvena Zvezda, lorileede Serbia ti n gbaradi lo ti daku.
Nígbà tí wọn yoo fi gbé dé ilé iwosan kan lagbegbe naa, o ti dakẹ.
Aremu Adu:
Olukọni ere idaraya naa jẹ ilumọọka nibi ka maa ṣatọna awọn ọjẹ wẹwẹ ere idaraya nipinlẹ Eko.
Ọjọ Kẹwa oṣù Kaarun ọdun 2020 lo ki ayé pe o digba.
Ọpọ lawọn elere idaraya ni Naijiria ti wọn ti tipasẹ Coach Adu gun oke agba nidi ere idaraya.
Ninu awọn to kọ la ti awọn to ti wa nilẹ Amẹrika nibi ti wọn ti n tẹsiwaju pẹlu ẹkọ wọn.
Emmanuel Ibah:
Ninu awọn ti ajọ ere bọọlu Naijiria NFF padanu lọdun 2020 ni Emmanuel Ibah wa.
O jẹ alakoso NFF lagbegbe Guusu Naijiria, to sì tun jẹ alaga ẹgbẹ ere bọọlu ni Akwa-Ibom titi di igba to fi faye silẹ.
Ẹni ọdun mọkanlelọgọta lo jẹ lasiko ti ọlọjọ dé.