You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Gani Adams: Iléesẹ́ ọlọ́pàá Oyo ṣe àfihàn àwọn afurasí, òníjìbìtì
Ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ti safihan awọn afurasi ọdaran ti ọwọ wọn tẹ jakejado ipinlẹ naa.
Lara awọn afurasi naa ni awọn afurasi ajinigbe to n ṣe ọsẹ ninu igbo Old Oyo Forest Reserve, to wa ni oju ọna Igbeti si Kisi ni agbegbe Oke-Ogun.
Ọwọ tun tẹ awọn to ma n fi owó ṣe sogun-dogoji, to lu ọpọ eeyan ni jibiti nilu Igboho.
- Ọjọ́ ìdájọ́ déé! Wọ́n dájọ́ ikú nípa yíyẹgi fún David West tó ń pa àwọn obìnrin ní PortHarcourt lónìí
- Gbàjarè! Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ agbébọn lo wà nílúù Kishi, National Park - Gani Adams figbe ta
- Gani Adams kilọ f'awọn darandaran
- Ìlànà ‘Referendum’ nìkan la fi le gba orílẹ̀èdè Oduduwa, kìí ṣe ìwọ́de
- Wo àwòrán ńkan tó ń ṣẹlẹ̀ ní ìpádé ìran Yorùbá ní Ibadan báyìí
- Àgbáríjọpọ ẹgbẹ OPC, fijiláńté VGC, Agbẹkọyà ti bẹrẹ ètò aàbò ní ilẹ Yorùbá
Nigba to n sọrọ ni olu ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Oyo, to wa ni adugbo Eleyele nilu Ibadan, Kọmisanna ọlọpaa, Joe Nwachukwu Enwonwu, sọ pe, ọwọ tẹ àwọn agbebọn naa lasiko irinajo ọjọ mẹta ti awọn ọlọpaa ati ọlọdẹ fi n gbọn igbo Kishi yẹbẹyẹbẹ.
Ọgbẹni Enwonwu sọ pe, awọn afurasi naa ni Aare Ona Kakanfo ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams ta àwọn alasẹ lolobo si, nipa iṣẹ buruku ti wọn n ṣe ni agbegbe Oke-Ogun.
O ni "awọn janduku naa fi nkan ijagun oloro dena de awọn olookowo maalu kan, ni ọjọ kẹẹdogun, oṣu Kẹsàn-án, ni nkan bi aago mẹfa irọlẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ẹ gbà mí o! Bí mo ṣe ń dàgbà ni ǹkan ọmọkùnrin mi ń tóbi síi àmọ́ obìnrin ni mi'
- Aya mi, dáríjìn mí fún bí n kò ṣe fi ìfẹ́ hàn tó sí ọ bó ṣe yẹ - Mike Bamiloye
- Wo owó tí Buhari bù fún ẹ̀ka kọ̀ọ̀kan nínú ìṣúná ọdún 2021
- Ìdí tí Gúúsù Akure, Owo àti ìwọ̀orun Ondo yóò fi sọ ẹni tí yóò jáwé olúborí nínú ìbò gómìnà Ondo
- Kẹ̀rẹ̀ kẹ̀rẹ̀ Okonjo-Iweala ń súnmọ́ ipò olórí WTO bọ̀
- Bode George ní Fayose gọ̀, ó fẹnu họra, Fayose ní ''ẹ ò lè pa mí bí ẹ ṣe pa Bola Ige
- Ènìyàn 5, ilé 25 ilé ìtajà 16 àti àwọn ǹkan mírà lo bá ìṣẹ̀lẹ̀ iná náà rìn.
- "Ọkùnrin kọ́ ló ra jeep fún Iyabo Ojo, òógùn ojú mi ni mo fi rà á fun"
- Kanu Ejike fipá bá ọmọ ọdún méje lò pọ̀ nínú sọ́ọ̀bù ìyàwó rẹ̀
Lẹyin naa ni awọn afurasi ajinigbe/adigunjale naa ránṣẹ si ẹbí awọn eeyan naa, ti wọn si gba owo itusilẹ lọwọ wọn."
Lẹyin ti ọrọ naa de ọdọ awọn ọlọpaa, ni wọn gbe igbesẹ pẹlu iranlọwọ àwọn ọlọdẹ, ti ọwọ si tẹ mẹta lara wọn.
"Ibọn AK-49 marun, ọta ìbọn mẹtalelọgọrin, foonu mẹsan, N77,800, ati awọn nkan miran ni wọn ba ba lọwọ wọn."
Bakan naa ni ọwọ tẹ awọn ọmọ ikọ olówó èlé, to lu awọn olugbe ilu Igboho ni jibiti owo to to miliọnu mẹta Naira, N2, 700,000, ko to o di pe wọn sa kuro ni ilu naa lọ si Badagry nipinlẹ Eko.
Ilu Badagry ni ọwọ ti tẹ wọn, nibi ti wọn tun ti n ṣe iru òwò naa.
Nilu Igboho, Noble City Global Concept, ni orúkọ ti awọn onijibiti naa pe ara wọn, ti wọn si lo Achievers Nicor Fund Social Economic Development Scheme ni Badagry.
Ìgbeyàwó túka nígbà tí afipábánilópọ̀ fi fídíò aya àfẹ́sọ́nà sórí ayélujára
Ile ẹjọ kan nilu Sokoto, ti paṣẹ pe ki wọn o mu ọdọmọkunrin kan to ya fidio ọmọbinrin kan, lẹyin to tipa ni ibalopọ pẹlu rẹ, to si tun fi si ori ayelujara.
Ọjọ igbeyawo ọmọbinrin naa ku diẹ ni iṣẹlẹ naa waye, eyi to mu ki ọkọ afẹsọna rẹ sọ pe oun ko ṣe igbeyawo pẹlu rẹ mọ, lẹyin ti fidio ihoho rẹ jade sori ayelujara.
Ọjọ Aje ni wọn gbe Aminu Hayatu Tafida lọ sile ẹjọ majisireti kan, ti wọn si fi ẹsun ifipabanilopọ, ibanilorukọ jẹ, ati pe o tun sọ ọrọ odi.
- Bíbéèrè fún ìbálòpọ̀ gbogbo ìgbà sọ ìyàwó ilé dèrò ilé ìwòsàn
- Ẹ wo ìṣẹ̀lẹ̀ nípa ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀ tí wọ́n fi kan D'banj ní sísẹ̀-n-tẹ̀lé
- Ó ṣeéṣe kó jẹ́ pé àwọn alágbara ló ń fi agbára hàn lórí arábìnrin tó fẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀ kan kọmíṣọ́nà Kogi -Agbẹjọ́rò
- "Grandpa àti Uncle mi, ń fipá bá mi lòpọ̀ láti ọmọ ọdún mẹ́rin"
Iroyin sọ pe Aminu ati ọrẹ rẹ mẹta ni wọn gbe lọ sile ẹjọ, nitori wọn ran an lọwọ lati pin fidio naa kaakiri ori ayelujara.
Awọn mẹtẹẹta ni Umar Abubakar, Mas'ud Abubakar Gidado, ati Aliyu Shehu Kangiwa.
Ọlọpaa to rojọ tako wọn nile ẹjọ, ASP Samuel Sule, sọ pe awọn ẹsun ti wọn fi kan wọn tako ofin iwa ọdaran nipinlẹ Sokoto.
Awọn mẹrẹẹrin sọ pe awọn ko jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan wọn ọhun.
Agbẹjọro fun Aminu, AY Abubakar, sọ pe ẹsun ti awọn ọlọpaa fi kan onibara oun ko lẹsẹ nilẹ, nitori pe akọsilẹ akọkọ tileeṣẹ ọlọpaa kọ, ko sọ pato ẹsun ti wọn fi kan an.
Bakan naa ni agbẹjọro fun awọn mẹta to ku, Yahaya Gwaza, sọ pe ko si ẹri to fihan pe awọn olujẹjọ lọwọ si isẹlẹ naa.
Eyi si lo mu ki adajọ ile ẹjọ naa, Shu'aibu Ahmad, sun igbẹjọ si ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹwa, lati fun ileeṣẹ ọlọpaa ni aaye lati ko ẹsun ti wọn yoo fi kan wọn jọ.
Bakan naa lo paṣẹ pe ki wọn fi wọn si atimọle titi di igba naa.
Bi iṣẹlẹ naa ṣe waye ree:
Oṣu to kọja ni awọn ọlọpaa agbegbe taa mọ si Hisbah nipinlẹ Sokoto, mu awọn ọdọ naa fun pe, wọn fi fidio to ṣafihan bi ọkan lara wọn ṣe n ba ọmọbinrin kan ni ibalopọ tipatipa, si ori ayelujara.
Iroyin sọ pe oṣu yii lo yẹ ki ọmọbinrin naa ṣe igbeyawo, amọ afẹsọna rẹ ti sọ pe oun ko ṣe mọ, lẹyin ti fidio naa jade.
Oludari ajọ Hisbah, Dokita Adamu Bello Asarawa sọ fun BBC pe, iya ọmọbinrin ọhun sọ fun ajọ naa pe, ọdun 2017 ni ọmọkunrin naa tan ọmọbinrin ọhun lọ sile itura kan, to si ya fidio rẹ nigba to wa ni ihoho, lẹyin to fi ipa balopọ tan.
Amọ, igba ti ọjọ igbeyawo ọmọbinrin naa ku diẹ, lo fi fidio naa sita.
"Ọmọkunrin naa jẹwọ fun wa nigba ti ọwọ tẹ ẹ, pe lootọ ni oun hu iwa naa. Ọwọ wa tẹ ọrẹ rẹ meji, awọn naa si sọ pe ọmọkunrin naa lo ran awọn.
"Nitori naa, ọwọ awọn ọrẹ rẹ mejeeji ni fidio naa gba de ori ayelujara."
Ọmọ ọdun mẹtadinlogun ni ọmọkunrin ọhun nigba ti iṣẹlẹ yii waye, ti eyi obinrin si jẹ ọmọ ọdun mẹrindinlogun.