Anambra Rape: Ìdí ti mo fi bá ọmọ ọdún méje lòpọ̀- Ejike Kanu

Ọkùnrin ẹni ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n kan ni wọ́n ti fí pánpẹ́ ọba mú nítorí ó fipá bá ọmọ ọdún méje tó jẹ́ aládùgbò rẹ̀ lòpọ̀.

Ejike Kanu ni wọn ni ó tan ọmọ kan wọ sọ́ọ̀bù ìyàwó rẹ̀ níbi tí ó ti fipá bá ọmọ náà lòpọ̀.

Ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún tó wáyé ní Okpoko, ní ẹgbẹ́ Onisha, ìjọba ìbílẹ̀ Ogbaru, ìpínlẹ̀ Anambra bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ọlọ́pàá ti mú u ti wọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí wọ́n lórí ọ̀rọ̀ náà.

Kanu ni iṣẹ́ esù ló mu òun gbé ìgbésẹ̀ náà lásìkò tí àwọn ọlọ́pàá ń bèrè ìdí tó fi hu irú ìwà bẹ́ẹ̀.

Agbẹnusọ ọlọ́pàá ìpińlẹ̀ náà, Haruna Mohammed to fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ sàlàyé pé ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ti dárí ẹjọ́ náà sí ẹ̀ka ìwádìí ìwà ọ̀daran.

" A ti ṣe àbẹ̀wò sí ibi ìṣẹ̀lẹ̀ náà, à sì ti gbé ọmọ ọ̀hún lọ sí ilé ìwòsàn fún àyẹ̀wò àti ìtọ́jú, tí àwọn dókìtà sì fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé lóòtọ́ ni wọ́n fi ipá bá ọmọ náà lòpọ̀.

Bákan náà ni ọkùnrin ọhun jẹ́wọ́ pé lóòtọ́ ni òun fi ipá bá ọmọ náà lòpọ̀, sùgbọ́n iṣẹ́ esù ni.

"Àwọn ajínigbé yìí dájú o, wọ́n fipá bá obìnrin mẹ́rin ló pọ̀ níwájú mi"

Ó ṣojú mi kòró làwọn agbébọn ṣe fipá bá ọmọ ọdún mẹ́wàá lòpọ̀!

Ohun ti oju Musa Adamu, olugbe ilu Mallamawa ri lasiko tawọn agbebọn ṣigun bo abule rẹ fọjọ meji kọja afẹnusọ.

Baba ọlọmọ mẹwa yii, to ni iyawo meji sọ fun BBC pe awọn agbebọn to le ni aadọta lo yabo abule awọn ni ipinlẹ Katsina, nila oorun ariwa Naijiria.

O ni lowurọ ọjọ Aiku ti wọn wa ba awọn loko, awọn ọdaran yii gbe ọrẹ oun ati awọn eeyan miran to n ṣiṣẹ loko lọjọ naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni "Inu oko ni mo wa pẹlu ọrẹ mi, ti awọn ẹni a wi yii de lori alupupu, ti wọn si di ibọn mọra. Ki a to mọ ohun to ṣẹlẹ, wọn ko wa si ori ọkada, ti wọn si gbewa lọ si oko miran."

''Lapapọ, eeyan mejila ni wọn ji gbe ni abule Mallamawa''

O tẹsiwaju pe ''awọn obinrin mẹrin wa laarin wa, ọmọge mẹta ati adelebo kan. Nisoju mi ni wọn se fipa ba awọn mẹrẹẹrin lopọ.

Ọmọdebinrin, ọmọ ọdun mẹwa kan to wa laarin wọn kan n sunkun ni bi wọn ṣe n fipa ba a lopọ''

Adamu ni wọn sọ fun adelebọ kan ti wọn fipa ba lopọ pe, awọn ko ni tusilẹ nitori pe awọn gbadun rẹ.''Wọn daju gan ni.''

Ede fulani lawọn agbebọn naa n sọ

Adamu sọ pe awọn agbebọn naa ti wọn wọ aṣọ Fulani, ti wọn si tun n sọ ede wọn, sọ pe awọn fẹ gba miliọnu kan naira lọwọ ẹni kọọkan.

Nipa ti ounjẹ, Adamu to ribi moribọ sisọ loju rẹ pe okele tuwo kọọkan ni wọn n fun awọn lọsan ati alẹ.

"Eeyan ko le pe nnkan ti wọn n fun wa lounjẹ rara nitori gbẹmi ro lasan ni. Okele kan tuwo laarọ, lọsan ati alẹ ni wọn n fun wa lojumọ''

Musa salaye pe nigba ti awọn ajinigbe yii sun, lawọn ribi tu okun, tawọn si yọ salọ.

''Emi ati ọrẹ mii ribi tu okun nigba ti wọn sun lọ. Ohun to dun mi ni pe a ko ribi doola awọn eeyan mẹwa to ku.T i a ba fi ni ka ran wọn lọwọ, aṣiri ko ba tu''

Tijo tayọ ni Adamu fi darapọ mọ ẹbi rẹ pada, to si ni yoo ṣe diẹ ki oun to pada soko.

Agbẹnusọ ọlọpaa nipinlẹ Katsina, Gambo Isah fidi iṣẹlẹ yii mulẹ fun BBC, to si ni awọn n ṣapa lati doola awọn ti wọn jigbe.

O ti ṣe diẹ ti ipinlẹ Aarẹ Buhari, iyẹn Katsina ati awọn ipinlẹ mii ni iwọ oorun ariwa Naijiria, ti n koju ipenija aabo lọwọ awọn ajinigbepawo.

Lọjọ Kẹwa oṣu Kẹfa ọdun 2020, eeyan mẹwa lawọn agbebọn pa ni Faskari ti wọn si tun pa eeyan mẹẹdogun loṣu to tẹle.

Iṣẹlẹ keji yi waye ni ilu Yargamji ni ipinlẹ Katsina yi kan naa.