Sunday Igboho: Gani Adams ní ìwọ́de kọ́ ni Ààrẹ ọ̀nà Kakańfò fi ń bẹ̀rẹ̀ ogun

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ìlànà 'Referendum' nìkan la fi le gba orílẹ̀èdè Oduduwa, kìí ṣe ìwọ́de

Aarẹ Ọnakakanfo, Iba Gani Adams tun ti ja gudugbẹ ọrọ mii silẹ, lori ọrọ ijijagbara Oduduwa Republic ti ajafẹtọ ọmọniyan, Sunday Adeyemo, ti ọpọ mọ si Sunday Igboho, wa lara awọn to n ṣagbatẹru rẹ.

Nigba ti Gani Adams n ba BBC Yoruba sọrọ, Aarẹ Ọnakakanfo sọ pe, ọgbọn lọrọ to wa nilẹ yii gba ki ṣe agbara kaka.

Aarẹ ni gbogbo nkan ti Igboho n ṣe papaa julọ lori ayelujara ni oun n fi oju sununkun wo.

Gani Adams ni awọn si n wo o boya Igboho tootọ ni gbogbo ohun ti Igboho ṣi n ṣe.

O ni oun gan an faramọ ki ẹya Yoruba ya kuro lara orilẹede Naijiria, amọ ọ ni ọna ti eeyan le gbee gba.

''Ọrọ orilẹede ni a n sọ yii o, kii ṣe ọrọ ilu Ibadan tabi ọrọ Sunday Igboho nikan,'' Gani Adams lo sọ bẹẹ.

Aarẹ Ọna Ọ́kakanfo sọ pe eto idibo ''ṣe ẹ fẹ, abi ẹ o fẹ'' ti awọn oloyinbo maa n pe ni ''referendum'''loun faramọ pe o jẹ ọna kan ti Yoruba fi le ya kuro lara Naijiria.

O kilọ fun Igboho pe ko yee wa ọta kun ọta nipa bi o ti n sọrọ ko bakun pe gbe si agbaagba ilẹ Yoruba.

Gani Adams ṣalaye awọn agba to n bu yii gan an le wa wulo fun ijijagbara Oduduwa Republic to ba ya.

O ni Sunday Igboho ni lati kọwọ ọmọ rẹ bọ aṣọ, ki o si tẹẹ jẹjẹ ti o ba fẹ rin jina ninu ijijagbara.

''Awa ni a ja fun eto ijọba awarawa lorilẹede Naijiria, amọ iwọde kọ ni aarẹ fi maa n bẹrẹ ogun,'' Aarẹ Ọnakakanfo lo woye bẹẹ.

Gani Adams ni ti o ba doju rẹ tan, ''ori ti a fi ṣe ewe si wa nibẹ.

O ni nigba naa lawọn eeyan yoo ri agbara aarẹ, ''agbara aarẹ a wa jade.''

O ni ibẹrẹ pẹpẹ ni gbogbo ohun tawọn Sunday n ṣe lori ọrọ Oduduwa Republic.

''Mo n duro de awọn eeyan wa lori ọrọ ''referendum'' ki n to mọ oun maa ṣe,'' Aarẹ Ọna kakanfo lo sọ bẹẹ.

O ni ko si ọjọ iwaju fun orilẹede Naijiria yii mọ, idi si ni yii ti oun fi maa gbaruku ti ọrọ Oduduwa Republic.

''Awa ko le jẹ ki awọn alakatakiti ẹsin maa ju bọmbu lu awọn eeyan wa nilẹ Yoruba, o ni ohun ti a agba nigba ti a gba ominira kọ lo n ṣẹlẹ bayii,'' Gani Adams lo woye bẹẹ.

Aarẹ Ọna kakanfo ni nkan ti awa n wa gẹgẹ bi ẹya Yoruba kọ, ni awọn Hausa ati Fulani n wa.