You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ooni Ogunwusi: Ìròyìn òfégè ló ń lọ kiri pé ìyàwó mí bimọ tuntun
Lẹnu ọjọ mẹta yii ni iroyin tan kalẹ pe olori ni aafin Ile Ife, Naomi Silekunola Ogunwusi ti bimọ ọkunrin lanti-lanti fun Kabiyesi Ọọ́ni Adeyeye Ogunwusi.
Gbogbo eti to si gbọ̀ iroyin naa lo n fo fayọ, ti wọn si n ki ọba alaye naa pe wọn ku oriire ayọ ọmọ tuntun.
Amọ niwọn igba to jẹ pe BBC Yoruba kii bawọn he eera ti ko ni ọmọ ninu, idi ree ta fi kan si aafin Ọọni lati wadi iroyin naa, ka si fi idi otitọ mulẹ nipa isẹlẹ yii.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìròyìn Yàjóyàjó : Donald Trump àti ìyàwó rẹ́ ti lùgbàdì àrùn CoronaVirus
- Ìfẹ́ Yorùbá ló mú mi fi ẹ̀mí wéwu láti kojú ajínigbé ní Kishi - Sunday Igboho
- Buhari, ayẹyẹ kí là ń ṣe gan, ṣé ti ìpànìyàn àbí ìjínigbé? - Aráàlú ń bèèrè
- Ẹ fura, làásìgbò le wáyé ní ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́fà yìí lásìkò ìbò gómìnà Ondo - YIAGA
- Wo ìṣẹ̀lẹ̀ márùn-ún tí kò bá pín Nàíjíríà sí yẹ́lẹ-yẹ̀lẹ
- Bọ́ síta láti ṣe ìwọ́de mọ́ ìjọba Nàìjíríà lónìí, ko rugi oyin - Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá
- Ẹ̀yin ọlọ́pàá 10,000 tí ọ̀gá ọlọ́pàá gbà ṣíṣẹ́ ní 2019, ẹ padà sílé - Iléẹjọ́ pàṣẹ
Amọ abọ iwadi wa ni pe ofuutu fẹẹtẹ, aasa ti ko ni ọmọ ninu gbaa ni iroyin naa, nitori Olori Naomi ko bi ọmọ tuntun.
Bẹẹ si ni Ọọni Ile Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi ti sọ pe, ko si ootọ kankan ninu iroyin to gbode naa pe iyawo oun bimọ.
Nigba to n fidi otitọ ọrọ yii mulẹ fun BBC Yoruba, Agbẹnusọ fun Ọọni, Moses Olafare sọ pe irọ nla ni ahesọ ọrọ naa.
O ni awọn ko kede fun ẹnikankan pe iyawo Ọọni bimọ nitori naa, iroyin ayederu gba a ni ọrọ naa jẹ.
Kaakiri oju opo ayelujara ni iroyin yii ti gbode, ti awọn eeyan kan si ti n fi ọrọ ikini ranṣẹ si Ọọni ati iyawo rẹ, Olori Naomi Silekunola Ogunwusi.
Nibi ti ọrọ yii gbalẹ de, awọn kan ni ọmọ ọkunrin ni ọmọ naa.
Ninu ọrọ ti Olafare sọ, o ni ki awọn to ba n ṣiṣẹ akọroyin ri pe, wọn tẹle ilana iwadii ọfintoto, ki wọn to gbe iroyin jade.
A ko ridi ọrọ fi mulẹ ibi ti iroyin yii ti kọkọ jẹ yọ, ṣugbọn o bẹrẹ lẹnu igba ti awọn eeyan ko ri Olori Naomi nita lasiko ọdun Ọlọjọ to waye.
Eyi lo mu ki awọn kan maa sọ pe, o ṣeeṣe ki iyawo Ọọni ti bimọ ni ṣugbọn nibayii, aafin ti tako iroyin naa.