You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ronke Oshodi-Oke: Ọkọ mi kò mọ̀ pé òṣèré ni mi nígbà tí a pàdé- Ojo
Gbajugbaja oṣerebinrin, Ronke Ojo, ti awọn eeyan tun mọ si Oshodi-Oke, ti sọ pe oun ko ro pe o yẹ bojumu ki eeyan o ma ṣe afihan dukia rẹ lori ayelujara ibaraẹnidọrẹ.
O ni ọpọlọpọ eeyan ni ko ri ounjẹ jẹ ni Naijiria, ti ogunlọgọ awọn ọdọ ko si ri iṣẹ ṣe.
"Ti mo ba wa n fi dukia mi han, ti mo n ṣe afẹfẹyẹyẹ, yoo da bi pe mo n sọ fun awọn eeyan pe wọn o jara mọ iṣẹ to mi.
Ronke Oshodi-Oke ṣalaye ọrọ naa ninu ifọrọwerọ kan to ṣe pẹlu iwe iroyin The Punch.
O tun ṣalaye pe jijẹ gbajumọ oṣere 'ti gba ominira' oun, nitori pe oun kii gbadun ara oun ti oun ba da jade, koda awọn ọmọ oun kii gbadun ara wọn ti awọn ba jọ jade.
O ni eyi ribẹ nitori pe awọn ololufẹ oun ma n fẹ ẹ ya fọto pẹlu oun, ti oun ko si le sọ pe rara, koda ti kop ba wu oun.
Ronke-Oshodi sọ pe ọkọ oun ko mọ pe oṣere ni oun nigba ti awọn pade.
Koda, "ọjọ to wa mi wa sile, ti a si jọ n lọ loju ọna lo to o mọ nitori bi ọpọ eeyan ṣe n wo mi, ti wọn si n naka si mi".
O ni ọkọ oun kii ṣe ololufẹ ere sinima, ṣugbọn o faramọ fun oun.
Nigba ti wọn beere lọwọ rẹ idi ti ko fi fẹ oṣere bi ti ẹ, Ronke sọ pe afojusun oun ni lati fẹ oṣere nigba ti oun wa ni ọmọge.
O sọ pe igbagbọ oun ni pe èdè wọn yoo yera, nitori pe iṣẹ wọn papọ.
- Èmi àti Sanyeri ti tọrọ oúnjẹ jẹ rí nílé oninawo torí ebi, ká tó di gbajumọ oṣere
- Ọ̀rẹ́ wa ni Lawrence jẹ́, àmọ́ ó gbẹ̀yìn dẹ́nu ìfẹ́ kọ abúrò wa - Joshua àti Damilola Bamiloye
- Mi ò to iṣẹ́ Regina Daniels rárá kí n tó fẹ́ ẹ láàrin ọ̀sẹ̀ mẹ́ta, mo sì tún le fẹ́ ìyàwó míì - Ned Nwoko
- Wo àwọn oúnjẹ márùn ún tó ń mú kí àtọ̀ ọkùnrin dára síi
O ni amọ, o pada ye oun pe ko ni i bojumu ki obi mejeeji o ma a ṣe iṣẹ ti yoo ma gba akoko wọn.
"Mo si dupẹ pe mo yi ero mi pada."
O fi kun un pe mama oun ati awọn arabinrin rẹ lo maa n ba oun tọju idile oun lasiko to ba wa ni ẹnu iṣẹ.
Gbajumọ oṣere naa to it n ṣe ere fun bi ọdun mẹtalelogun sọ pe, oun ko le fẹhinti lailai nidi iṣẹ naa, niwọn igba ti oun ba ṣi ni okun ati agbara.
- Àwọn èèyàn tí bẹ̀rẹ̀ sì ní gba abẹ́rẹ́ àjẹsára fún ìdènà àrùn Coronavirus ni ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì
- Ìjọba àpapọ̀ ti kéde àdínkù owó epo bẹntiróòlù sí N162.44 fún lítà kan
- Ìdí rèé táwọn àkàndá ẹ̀dá fi dí iwájú iléeṣẹ́ ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo pa l'Agodi n'Ibadan
- A kò ní padà sílé ìwé àyàfi t́i ìjọba bá san owó oṣù tó jẹ wá - ASUU
- Ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa ìgbésẹ̀ tí Amẹ́ríkà fẹ́ gbé lórí Nàìjíríà nítorí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn