You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Petrol price in Nigeria: Ìjọba àpapọ̀ ti kéde àdínkù owó epo bẹntiróòlù sí N162.44 fún lítà kan
Ijọba apapọ ti kede adinku owo epo pẹtiroolu, lati Naira mejidinlaadọjọ si Naira mejilelaadọjọ, ati Kobo mẹrinlelogoji.
Ọjọ kẹrinla, oṣu Kejila ni aṣẹ naa yoo bẹrẹ iṣẹ.
Minisita fun ọrs oṣiṣẹ ati igbanisiṣẹ, Chris Ngige, lo kede aṣẹ naa lẹyin ipade to ṣe pẹlu awọn olori ẹgbẹ oṣiṣẹ loru ọọ Iṣẹgun.
Oṣu Kọkanla ni afikun de ba iye ti wọn n ta lita epo pẹtiroolu, lẹyin ti ileeṣẹ to n mojuto tita eporọbi fi owo kun iye to n ta epo fun awọn alagbata.
Ngige sọ pe ijọba tun ti yan igbimọ kan lati ri i daju pe owo epo pẹtiroolu duro sokju kan.
O ni igbimọ naa yoo jabọ iṣẹ rẹ ni ọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu Kiini, ọdun 2021, nibi ti yoo ṣe agbeyẹwo awọn nkan ti yoo mu ki nkan fi ẹsẹ mulẹ ni ẹka eporọbi.
Bakan naa ni minisita naa sọ pe adinku to ba owo epo kii ṣe lati fi opin si amojuto ti ijọba n ṣe, nitori pe ko ni ipa lori eporọbi.
O ṣalaye pe ko ṣẹyin bi ajọ NNPC ṣe gba pe oun le din owo ti wọn fi n gbe epo wọle, ati eyi to n gba lori iye asiko ti awọn alagbata ba fi gbe epo si ọds rẹ.