You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Petrol Pump Price: Ọmọ Nàíjíríà ń bèèrè pé níbo ni oúnjẹ́ Kérésì yóò ti wá torí lítà epo tó di ₦170
Awọn ọmọ Naijiria ti ni awọn yoo ranti igba ati akoko aarẹ Buhari lori oye, gẹgẹ bi asiko ti iya, ebi ati iṣẹ peleke si julọ lorilẹede Naijiria.
Awọn ọmọ Naijiria to sọ eyi loju opo Twitter wọn n fesi si ijọba to tun fi owo kun owo epo bẹntirol.
Atẹjade kan ti Ileesẹ to n se katakara epo rọbi lorilẹede Naijiria, PPMC kede pe lati akoko yii lọ, owo lita epo bẹntiro kan yoo di naira marundinlọgọjọ naira ati kọbọ mẹtadinlogun lati ibudo ifọpo(₦155.17).
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo àwọn òṣèré tíátà Yorùbá mẹ́fà tó bẹ̀rẹ̀ eré ṣíṣe láti kékéré
- Bàbá àádọ́rin ọdún fún ọmọ-ọmọ rẹ̀ ọdún mẹ́ẹ̀dógún lóyún, lọ̀rọ̀ bá pèsì jẹ
- Wo iye obìnrin tó bá Ginimbi ọ̀dọ́mọdé olówó kú àti obìnrin to ṣeéṣe kó jogún rẹ̀
- ''Aláàfin kìí ṣe ọkùnrin tí wàá jẹ lásán, tó sì wá sálọ - Aráàlú fèsì fún Olorì Anu
- Wo ọ̀pọ̀ ìgbà tí Ginimbi ọ̀dọ́mọdé olówó ti ṣe àríyá aláṣọ funfun kó tó kú
- Ilé ẹjọ́ tú ìgbéyàwó ọdún mọ́kànlá ká nítórí pé ìyàwó fí ìbálòpọ̀ dun ọkọ rẹ̀
- Ta ni olóògbé Jerry Rawlings, tí wọ́n fún ní àlàjẹ́ 'Junior Jesus'
- Gbogbo ìgbésẹ̀ Aláàfin láti jí mi gbé ló já sí pàbó, n kò le panumọ́ - Olori Anu
- Sé ọlọ́pàá tasẹ̀ àgẹ̀rẹ̀ tàbí fìyà jẹ ọ́ láìtọ́, wo bó ṣe fi ẹjọ́ rẹ̀ ṣùn l‘Eko
Ẹgbẹ awọn to n ta epo ni Naijiria, IPMAN ti wa fi lede wi pe, nisinyii ti ijọba tun ti gbe owo le owo epo, awọn yoo ma a ta lita kan ni iye owo toto N168 to N170.
Eleyii bi awọn ọmọ Niajiria ninu, ti ọpọlọpọ wọn si faraya lori ẹrọ ayelujara.
Lara awọn eniyan jankan jankan lawujọ ati ẹgbẹ to fi ero wọn han ni Minisita fun ọrọ eto ẹkọ ni Naijiria, Obiageli Ezekwesili ati ẹgbẹ ọmọ Yoruba, Afẹnifẹre.
Ezekwesili ni ijọba Buhari ko bikita iru iya ati iṣẹ to wa lorilẹede Naijiria, ati bi aisi iṣẹ ṣe n peleke si lojoojumọ.
O ni lasiko yii ti awọn eniyan ṣẹṣẹ n pada si ipo nitori ajakalẹ arun Coronavirus to mu wọn joko sile fun ọpọlọpọ oṣu lai ri ounjẹ jẹ, ni ele owo epo tun n waye.
Bakan naa ni adari ẹgbẹ Afẹnifẹre, Ayo Adebanjo ni orilẹede Naijiria labẹ iṣejọba aarẹ Buhari ti fihan pe, inu ibanujẹ ni ọpọlọpọ awọn ọmọ Naijiria wa, lai si ọna abayọ fun wọn.
Adebanjọ ni iroyin to n pa oun lẹkun ni wi pe, iṣejọba aarẹ Buhari ti fihan pe ko si ohun rere kan to le e jade nibẹ.
Amọ lara awọn ọmọ Naijiria to fi ero wọn han lori ẹrọ Twitter ni, oun dupẹ lọwọ aarẹ Buhari nitori o mu aye le fun awọn eniyan ni asiko rẹ, ti ọpọ yoo si ma a ṣe apejuwe rẹ gẹgẹ bi aarẹ ti ko naani awọn araalu.
Ẹlomiran ni afikun owo epo yii yoo mu ki owo oṣu awọn eniyan di radarada, ti ko si ni si igbẹkẹle kankan fun awọn eniyan.
Ọpọlọpọ awọn ọmọ Naijiria ni awọn ko tilẹ reti ki awọn jẹun ni ọdun keresi to n bọ lọna yii, nitori atijẹ atimu ti di inira fun awọn eniyan lorilẹede Naijiria.
Petrol Pump Price: Ìgbà kẹ́rin rèé tí NNPC yóò fi owó kú owó epo láàrin oṣù márùn-ún
Ileesẹ to n se katakara epo rọbi nilẹ wa, PPMC, to wa labẹ ẹka ileesẹ NNPC, ti kede afikun owo jala epo Pẹtiroolu lorilẹede yii.
Atẹjade kan ti ileesẹ naa fisita ni Ọjọru kede pe lati akoko yii lọ, owo lita epo pẹtiro kan yoo di naira marundinlọgọjọ naira ati kọbọ mẹtadinlogun (₦155.17).
Lita epo pẹtiro kan si lo wa ni Naira mẹtadinlaadọjọ tẹlẹ (₦147.67) eyi to mu ki afikun owo to ba lita epo kan bayii jẹ naira mẹjọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo ọ̀pọ̀ ìgbà tí Ginimbi ọ̀dọ́mọdé olówó ti ṣe àríyá aláṣọ funfun kó tó kú
- Iléeṣẹ́ ológun sọ ikọ̀ ọdẹ́ ìbílẹ̀ JTF di ológun ní Borno, ẹ̀yà yókù ní Nàíjíríà fọnmú
- ''Aláàfin kìí ṣe ọkùnrin tí wàá jẹ lásán, tó sì wá sálọ - Aráàlú fèsì fún Olorì Anu
- Ilé ẹjọ́ tú ìgbéyàwó ọdún mọ́kànlá ká nítórí pé ìyàwó fí ìbálòpọ̀ dun ọkọ rẹ̀
- Ta ni olóògbé Jerry Rawlings, tí wọ́n fún ní àlàjẹ́ 'Junior Jesus'
- Gbogbo ìgbésẹ̀ Aláàfin láti jí mi gbé ló já sí pàbó, n kò le panumọ́ - Olori Anu
- Sé ọlọ́pàá tasẹ̀ àgẹ̀rẹ̀ tàbí fìyà jẹ ọ́ láìtọ́, wo bó ṣe fi ẹjọ́ rẹ̀ ṣùn l‘Eko
Atẹjade naa ni oni, ọjọ Ẹti ni afikun owo epo naa yoo bẹrẹ.
Gẹgẹ bi alaye ajọ PPMC, owo ti lita epo pẹtiro n ba wọle lati oke okun ti di ₦128,89 bayii, dipo ₦119.77 to wa losu kẹsan ati ikẹwa to kọja.
O ni afikun naira meje to ba owo ti epo n ba de naa yoo mu alekun ba owo lita epo rọbi kan.
Bẹẹ ba gbagbe, lati inu osu Kẹfa ti ijọba ti yọwọ kuro ninu ipese owo iranwọ fun epo rọbi, igba kẹrin ree ti lita epo pẹtiro yoo gbowo lori.