Jerry Rawlings: Ààrẹ orílẹ̀-èdè Ghana nínú ìjọba ológun àti alágbádá

Ààrẹ orílẹ̀ èdè Ghana nígbà kan rí, Jerry Rawlings ti jáde láyé, lẹ́yìn tí ó koju àìsàn ránpẹ́

Ìròyìn sọ pé, Rawlings dágbére fáyé ní ilé ìwòsàn Korle-Bu ní ìlú Accra lówùrọ̀ òní ọjọ́ ọjọ́bọ, ọjọ́ kejìlá, oṣù kọkànlá, ọdún 2020.

Rawlings jẹ́ òṣìṣẹ́ ológun ní orílẹ̀ èdè Ghana nígba kan rí, ki ó tó dara pọ̀ mó òṣèlú alágbáda, tó sí jẹ ààrẹ Ghana ládún 1981 títí di ọdún 2001.

Ẹni ọdún mẹ́tàléláàdọ́rin ni Rawlings lásìkò tó jáde láye

Oun ló sáájú ìdìtẹ̀ gbajọba tó sí dárí ìlú di ọdún 1992, kí o tó dara pọ̀ mọ́ ìjọ̀ba alágbáda, tó si jẹ fún sáà méjì míràn.

Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn ṣe sọ, ó ti tó bi ọ̀sẹ̀ kan ti Rawlings ti wa ní ilé ìwòsàn Korle Bu.

Tani Jerry John Rawlings gan?

J.J Rawlings jẹ́ ọmọ bíbí orílẹ̀-èdè Ghana tí a bi ni ọjọkejilélógún, oṣù kẹfa, ọdún 1947 ni ìlú Accra Ghana

Iya Jerry jẹ ọmọ ìlú Keta ni ẹkun Volta ti bàbá rẹ́ sì jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Scortland

O lọ ilé ẹkọ́ Achimota ni bi ti ó ti gba ìwé ẹrí ilé ẹ̀kọ́ Girama ni ọdún 1966

O forukọ silẹ̀ gẹ́gẹ́ bi ọmọ ológun ojú ofurufu ninú oṣù kẹjọ ọdún 1967 ti o si di gba ìdánilọ́kọ̀ọ́ ni ilé ẹkọ́ ìkọ́ni Ghana ni Teshie ni Accra

Nínú oṣù kẹta ọdún 1968 wọn gbe lọ sí agbègbè Takoradi ni ìhà ìwọ̀-òòrùn Ghana láti tẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀.

Ó kẹ́kọ̀ọ́ jáde ni oṣù kíní ọdún 1969 gẹ́gk bi awakọ ofurufu, ti o si gba oyè "Speed Bird Throphy" èyí ni oyè tó ga jùlọ fún awakọ̀ ofurufú.

O gba oyè Flight-Lieutenant nínú oṣù kẹrìn ọdún 1978 ti ó si jẹ́ òṣìṣẹ́ tó jáfáfá láàrìn àwọn akẹgbẹ̀ rẹ̀

Àsìkò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi ọmọogun òfurufú ní Ghana yìí ló ri irú àwọn ìwà ìbàjẹ́ tó wà láàrìn àwọn olórí ìlú, ìwà ajẹbanu àti fífi ẹtọ́ àwọn ará ìlú dùn wọ́n.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nínú oṣù kaàrún ọdún 1978 Rawlings àti awọn mẹ́fà míràn fara han níwájú ilé ẹjọ àwọn ọmọogun pé wọn n dìtẹ̀ láti gba ìjọba.

Sùgbọ́n àwọn ènìyàn ìlú Ghana figbe ta pàápaàá jùló lẹ́yìn tí wọ́n ka atẹjade rẹ nílé ẹjọ tó sì sọ síbẹ̀ pé gbogbo ìwà àìtọ́ tó n wáye láwùjọ ló mú kí òun gbé ìgbésẹ̀ náà.

Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn ọmọogun ofurufu àti àwọn ara ilú JJ Rawlings saaju ìfẹhonu han eyi to àwọn ìgbìmọ̀ adájọ nile isẹ́ ọmọogun kuro lori oye èyí sì ló bi Armed Forces Revolutionary CouncilC AFRC).

Rawlinmgs lo jẹ alágba igbimọ tuntun yii ti ó sì bẹ̀rl si ni lọ láti ojúlé dé ojúlé láti ṣe afonumọ ilú, èyí ni láti fọ àwọn ológun àti ará ilú mọ́ kúrò nínú ìwà ajẹbanu àti láti mú ki àwọn ará ilú bẹ̀rẹ̀ sí ni ṣe amúlò ìwà tó ta láwùjọ.

Ní ọjọ́ kẹrìnlélógún, oṣù kẹsàn ọdún 1979 ìgbìmọ̀ AFRC gbé ìjọba fún àwọn àlágbádá lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú People's National Party (PNP) lábẹ́ ààrẹ Hilla Limann.

N íọjọ́ kọkanlelọ́gbọ̀n ọṣù kejìlá, ọdún 1981 Rawlings sáájú ẹka kan ninu ilé iṣẹ́ ọmọogun láti ditẹ gbàjọba lọ́wọ́ PNP lábẹ́ ẹgbẹ́ Provisional National Defence Council (PNDC) ẹgbẹ ti Flt-Lt. JJ Rawlings dá sílẹ̀ jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ológun àti alágbádá.

Ó fi ilé iṣẹ́ ọmọogun sílẹ̀ ni ọjọ́ kẹrinlá, oṣù késán, ọdún 1992 tí ó sì dá ẹgbẹ́ òṣèlú Nationa Democratic Congress (NDC) silẹ̀, ó dupò ààrẹ o si wọlé lọ́dún 1992, bákan náà lo wọlé lọ́dún 1996

O gba oníruurú oyè to fi mọ́ ti àjọ aw\on to n fòpin si ebi lọ́dún 1993, ó gboye ẹ̀kọ́ lóríṣríṣi pẹ̀lú