Oyo physically challenged protest: Ìdí rèé táwọn àkàndá ẹ̀dá fi dí iwájú iléeṣẹ́ ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo pa l'Agodi n'Ibadan

Sunkẹrẹ fakẹrẹ gbode kan l'Agodi niluu Ibadan lọjọ Aje ọjọ keje oṣu kejila ọdun 2020 yii lẹyin tawọn onipenija ara bọ soju popo lati fẹhonuhan.

Awọn akanda ẹda ọhun to wa lati ijọba ibilẹ mẹtalelọgbọn kaakiri ipinlẹ Oyo lu oju opo ileeṣẹ ijọba to wa lagbegbe Agodi n'Ibadan pa.

Ohun ti wọn n beere ni pe ki ijọba gba awọn onipenija ara sii ninu awọn oṣiṣẹ ti kii ṣe awọn olukọ lawọn ileewe kaakiri ipinlẹ Oyo.

Laipẹ yii ni Gomina Seyi Makinde sọ pe ki ajọ to n ri si ọrọ awọn olukọ gba ẹgbẹrun un meje olukọ, ati ẹgbẹrun un meji awọn ti kii ṣe olukọ nipinlẹ Oyo.

Gomina Makinde tun sọ pe ki wọn gba awọn oṣiṣẹ eleto abo megaadi ẹgbẹjọ.

Amọ awọn akanda eeyan to n ṣe iwọde ṣalaye pe awọn ti ijọba mu ninu awọn ti kere ju.

Wọn ni awọn n rawọ ẹbẹ si Gomina Makinde lati wa nkan ṣe si ọrọ naa.

Awọn olufẹhonuhan naa duro wamu wamu sẹnu geeti to wọ ileeṣẹ ijọba ipinlẹ Oyo eleyi ti ko jẹ kawọn oṣiṣẹ ri aye wọle.

Awọn to ni ipenija ara sọ pe awọn lo sun mọ oṣi ati iṣẹ ju awọn abarapa eeyan lọ.

Ọkan lara awọn akanda ẹda naa to bawọn akọroyin sọrọ, Adegbuyi Adekunle ṣalaye pe ida marun un ninu ọgọrun tii ṣe 350 lo yẹ ki wọn fawọn.

O ni eeyan mọkandinlaadọjọ(149) pere ni ijọba fun ni iṣẹ ninu awọn ti wọn ṣẹṣẹ gba.