Akure shooting: Àlááfíà ti padà sí ìlú Akure, ẹnikẹ́ni kò kú - Deji ilu Akure

Kò sí ẹnikẹ́ni tó kú níbi rògbòdìyàn tó wáyé lánàá - Deji ilu Akure

Irọlẹ ọjọ Aiku, ọjọ kẹfa, oṣu kejila, ọdun 2020 ni iroyin gbode kan pe yinbọn lu eeyan kan ni Ọja Ọba, eyii to wa ni ilu Akure.

Ṣugbọn agbẹnusọ Kabiesi ilu Akure, Oloye Micheal Adeyeye ti sọ pe ẹmi ẹnikẹni ko ba iṣẹlẹ naa lọ.

Ṣaaju ni ileeṣẹ iroyin abẹle kan, ti sọ pe ija bẹ silẹ laarin awọn to n tẹle eegun ati awọn oniṣowo to jẹ ẹya Igbo lẹyin ti wọn ni oniṣowo kan gun ẹnikan to n tẹle eegun naa lọbẹ.

Iroyin ni iṣẹlẹ yii yọri rogbodiyan to pọ to bẹ, ti awọn kan bẹrẹ si n yinbọn.

Wọn ni lẹyin ti awọn agbofinro yọju sagbegbe naa ni alaafia to pada sibẹ.

Ọkan lara awọn agbofinro to yọju sibi iṣẹlẹ ọhun sọ fun awọn akọroyin pe awọn ọdọ ilu Akure kora wọn jọ lati ṣakọlu si awọn oniṣowo naa to jẹ Igbo.

Eyi waye lẹyin ti wọn gbọ pe ọkan lara awọn oniṣowo ọhun ti gun ẹnikan to n tẹle eegun lọbẹ.

Ẹwẹ, agbẹnusọ Deji ti ilu Akure, Oloye Micheal Adeyeye ti sọ fun awọn akọroyin pe ẹni ti wọn gun lọbe ko ku.

Nigba to n sọrọ lorukọ Ọba Ogunlade Aladetoyinbo Aladelusi, Adeyeye ni "mi o gbọ pe ẹnikẹni ku o, wọn gun ọmọ Igbo kan lọbe nigba ti awọn ọdọ kọlu wọn ni Ọdọpetu."

"Wọn ti gbe ọkunrin naa lọ ile iwosan, awọn agbofinro si ti pari aawọ ọhun."