Ghana 2020 election: Jean Adukwei Mensa,Tani akíkanjú obìnrin tí yóò kéde èsì ìbò aàrẹ Ghana?

    • Author, Princess Igho Williams
    • Role, Broadcast Journalist, BBC News Pidgin

Jean Adukwei Mensa ni ẹni ti gbogbo eeyan yoo maa foju si lara gẹgẹ bi alaga ajọ eleto idibo Ghana lọdun 2020.

Ohun ni yoo mojuto eto idibo ti ikede ẹni to ba jawe olubori yoo si tẹnu rẹ jade ninu idibo ti yoo waye lọjọ Keje osu Kejila ọdun yi.

Ṣaaju asiko yi ni ajọ eleto idibo Ghana ti ni awọn yoo ri pe idibo ti ko laahẹ ninu waye koda wọn tun pese nọmba ibaraẹnisọrọ tawọn eeyan le pe si ti wọn ba ri aiṣedede kankan.

Nọmba naa ti wọn ko ni sanwo lati pe si ni (0800-100-100).Anfaani wa lati pe nọmba yi lati ago mẹfa aarọ di ago mẹfa irọlẹ.

Die ree lara ohun to yẹ ko mọ nipa alaga ajọ eleto idibo Ghana [Jean Adukwei Mensa].

  • Jean Adukwei Mensa jẹ agbẹjọro ọmọ ilẹ Ghana oun si ni alaga ajọ eleto idibo il naa.
  • Saaju ko to di alaga,o lo ọdun mejidinlogun ni ileeṣẹ to n mojuto ọrọ aje,Institute of Economic Affairs (IEA) nibi to ti di ọga agba to si kopa ribiribi lati mu idagbasoke ba ijọba awarawa ni Ghana
  • Jean Mensa kẹkọ nileewe girama St. Mary Senior High School. Fasiti University of Ghana lo ti kẹkọ gboye imọ ofin lọdun 1993.
  • O di amofin ni ọdun 1996. Jean Mensa tun kẹkọ siwaaju si ni Harvard Business School (2018).
  • Jean Adukwei Mensa bọ sipo gẹgẹ bi alakoso eto idibo Ghana lọjọ kẹtalelogun oṣu Keje, 2018 lẹyin ti wọn yọ ẹni to wa nibẹ kuro.
  • O ti n ba iṣẹ imọ iwadii to si n dari ipolongo bọ o to ogun ọdun.
  • O bawọn kopa ninu agbekalẹ awọn eto bi abadofin igbejọba kalẹ ọdun 2012,atunto iwe ofin Ghana ọdun 1992 ati abadofin to n risi bi wọn ṣe n ṣagbatẹru ẹgbẹ oṣelu.
  • Ajọ African Network of Entrepreneurs (TANOE) fi orukọ Mensa s'ara awọn ọgọta akikanju adari obinrin ni Ghana fọdun 2017.
  • Ọpọ ami ẹyẹ lo ti gba to fi mọ Excellent Leadership Award (2013) ati Young Professional Role Model in Governance Award ti ikọ Young Professionals and Youth Coalition Initiative fi da lọla ni 2014.