Ìjọba ṣàlàyé àtúnṣe tó wáyé lórí àbá ìṣúná 2025 tí Tinubu ń gbé lọ síwájú ílé ìgbìmọ̀ aṣòfin l'Abuja

Aarẹ Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Asiwaju Bola Tinubu/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Aba iṣuna ọdun 2025 ti wọn ti kede ẹ tẹlẹ, pe Aarẹ Bola Tinubu yoo gbe lọ sile igbimọ aṣofin lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kejila ọdun 2024 ko ri bẹẹ mọ, latari awọn atunṣe kan ti ijọba apapọ ṣe lori rẹ.

Ọjọru, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kejila ọdun 2024 ni Aarẹ Tinubu yoo gbe aba naa lọ bayii, gẹgẹ bi igbimọ to n ri si i ṣe sọ.

Ọjọ Aje ni ile igbimọ ti kọkọ buwọ lu aba iṣuna ọhun, eyi Naijiria yoo lo lati 2025 de 2027.

Aba iṣuna ti iye rẹ jẹ 47.96tn naa ni a gbọ pe wọn da duro ki wọn le ṣe awọn atunṣe igbẹyin to yẹ si i.

Minisita eto ọgbin, Sabi Abdullahi, fidi ayipada naa mulẹ fawọn akọroyin l'Abuja, lọjọ Aje, lẹyin ti aarẹ ile igbimọ, Godswill Akbabio, kede ọjọ Iṣẹgun.

'Afikun tabi ayọkuro ko ba owo iṣuna 2025'

Minisita eto iṣuna, Abubakar Bagudu, ṣalaye fawọn akọroyin l'Abuja, pe atunṣe naa ko yi owo iṣuna ọdun 2025 pada rara.

O ni N47.96tn to wa naa lo wa, bẹẹ ni owo ti ijọba fẹẹ ya lọdun tuntun jẹ N9.22tn.

Bakan naa lo ni igbimọ MTEF to n ri si iye owo epo, iye owo dọla si naira ati ọwọngogo ọja ti wa lẹnu iṣẹ.

Gomina ipinlẹ Kebbi tẹlẹ naa ṣalaye, pe dọla marundinlọgọrin ($75) ni Naijiria yoo maa ta àgbá epo kan.

O fi kun un pe '2.06 million barrels', iyẹn agba epo to le ni miliọnu meji ni afojusun Naijiria lojumọ fun ọdun tuntun naa.

Lori iye ti wọn yoo maa ta epo ọhun, Bagudu sọ pe N1,400 si dọla kan ni, bẹẹ ni owo ti yoo wọle jẹ ida mẹrin o le mẹfa (4.6%).

Gbogbo eyi lo ni yoo waye laaarin ọdun 2025 si 2027 ti orilẹede yii yoo fi lo aba iṣuna naa.

Nipa pe ṣe afojusun ijọba yii yoo ṣee ṣe, Bagudu ṣalaye pe o le ṣoro lati ri bẹẹ, ṣugbọn ki i ṣe pe ko ṣee ṣe rara.

O ni afojusun ijọba latilẹ gan-an ni pe ki orilẹede yii maa pese agba epo miliọnu mẹta lojumọ.

'' Ohun ti igbimọ ro ni pe o yẹ ka le pese ju miliọnu mẹta agba epo lọ lojumọ. Ti ẹ ko ba gbagbe, NNPC ti jẹ ka mọ awọn ohun ti wọn tun ti ṣawari ẹ, yatọ si tibi ti wọn ti n ṣiṣẹ wọn tẹlẹ, awọn bii agbegbe Kolmani, Nasarawa ati awọn ibomiran''

Bagudu lo ṣalaye bẹẹ.