Àgbà òǹṣòwò, Ọ̀túnba Adekunle Ojora jáde láyé

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Agba oniṣowo to tun jẹ baba oloye ni ilu Ile Ifẹ ati Eko, Oloye Ọtunba Adekunle Ọjọra ti jade laye lẹni ọdun mẹtalelaadọrun.

Ninu atẹjade kan ti ẹbi Ọjọra fi sita, wọn ni owurọ ọjọru ni eekan ilu naa jade laye.

Gẹgẹbi ẹbi naa ṣe sọ, Oloye Ọjọra, to tun jẹ baba Sẹnetọ Toyin Saraki, iyawo Bukọla Saraki to figbakan ri jẹ aarẹ ile aṣofin agba Naijiria rọ araalu ninu atẹjade naa lati maa ranti wọn ninu adura.

Wọn fi kun un pe eto isinku agba onisowo naa yoo waye ni ilana pẹlu ẹsin Islam.

Ki o to jade laye, Oloye Adekunle Ọjọra ni Lisa ilu Ile Ifẹ, ati Ọtunba ti ilu Eko.

Ọjọ kẹtala oṣu kẹfa ọdun 1932 ni wọn bi Oloye Adekunle Ọjọra ẹni ti gbogbo eeyan kaakiri ẹka ilu ni Ọtunba Ọjọra., o si jẹ ara awọn sanmọri to n gbe aṣa ilẹ Yoruba ga kaakiri.

Eekan ni Oloye Adekunle Ọjọra laarin agboole ọba ni ilu Eko nibi to ti di oniruuru ipo ati oye mu bii: Olori-ebi idile Ojora; Olori Ọmọọba ilu Eko; Olori idile ọba Ologunkutere ati Adele Ajosun Olori idile oye Aiyeomosan nilu Eko.