₦130b owó ìpínlẹ̀ Osun ni ìjọba àpapọ̀ dìmú láti ọdún kan sẹ́yin – Ademola Adeleke

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke ti ke si ijọba apapọ ko jọwọ owo ijọba ibilẹ to tọ si ipinlẹ naa to wa lọwọ ijọba apapọ.

Iye owo ohun lo to ₦130 biliọnu.

Adeleke sọ pe owo naa ti ko tẹ ijọba ipinlẹ ọhun lọwọ n ṣakabo fun idagbasoke rẹ paapaa fun awọn eeyan to wa ni igberiko.

Ninu ọrọ kan to ba awọn eeyan ipinlẹ naa sọ lọjọ Aje, Adeleke sọ pe ile ẹjọ lo le awọn alaga kansu ti wọn wa lawọn ọọfisi ijọba ibilẹ nipinlẹ naa fun nnkan bii odidi ọdun kan gbako.

Gomina ọhun ni "ile ẹjọ lo yọ wọn nipo, kii ṣe ijọba mi.

O ni eto idibo ijọba ibbilẹ mii ti wọn ṣe lo wa ni ibamu pẹlu aṣẹ ile ẹjọ, ki wọn to burawọle fun awọn alaga kansu tuntun lọjọ kẹtalelogun, oṣu, ọdun 2025.

O wa bu ẹnu atẹ lu bi awọn kan ti wọn ko lẹtọ lati wa ni ọọfisi ọba ibilẹ naa ijṣe n lọ sibẹ lodi si aṣẹ ile ẹjọ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, gomina ana, Gboyega Oyetola n ṣatilẹyin fun awọn kọlọrọsi ẹda naa, eyii to le ṣakoba fun ijọba awarawa.

O sọ siwaju si pe awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ naa to yẹ ki wọn bẹrẹ iṣẹ ni awọn ọlọpaa atawọn janduku to n ṣiṣẹ fun oloṣelu le pada.

Ninu ọrọ rẹ lo ti mẹnuba owo to yẹ ki ijọba apapọ fi ṣọwọ si ipinlẹ naa amọ to kọ jalẹ lati ṣe bẹẹ.

Adeleke sọ pe lati inu oṣu keji ọdun 2025 ni ijọba apapọ ti kọ lati fi owo to yẹ fun ijọba ibilẹ ti apapọ owo naa jẹ ₦130b ranṣẹ.

O ni owo naa ṣe pataki lati san owo oṣu awọn olukọ ile ẹkọ alakọbẹrẹ, awọn nọọsi, awọn oṣiṣẹ eto ilera nile iwosan alabọde bii 332 to wa nipinlẹ naa, to fi mọ owo oṣu awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ, awọn lọbalọba atawọn oṣiṣẹfẹyinti.

Gẹgẹ bi Adeleke ṣe sọ, ijọba ipinlẹ naa ni lati lọ wa ọna mii lati wa owo to fi n san owo oṣu awọn ti ọrọ naa kan lati ọdun kan sẹyin, eyii ti ko ṣeeṣe mọ.

O juwe ipo ti ipinlẹ naa wa lai si owo yii gẹgẹ bii ipo to nira ati eyii ti ko bojumu.

Adeleke tun fẹsun kan ile ifowopamọ United Bank for Africa (UBA) pe o n gba ki awọn ti ko gba aṣẹ tọwọ bọ apo ijọba ipinlẹ ọhun.

O wa bere boya irufẹ nnkan bẹẹ le ṣẹlẹ lawọn ilu bii New York tabi ilu London ti ile ifowopamọ naa ti ni awọn onibara.

Lẹyin naa lo rawọ ẹbẹ si Aarẹ Bola Tinubu ko gbe igbesẹ lori ọrọ naa ko si jọwọ owo ọun fun anfani awọn eeyan ipinlẹ Osun.

Bo tilẹ jẹ pe o ni Aarẹ Bola Tinubu ko lọwọ ninu iya to n jẹ ipinlẹ Osun lọwọ yii, o rọ Aarẹ ko maṣẹ kawọ gbera lori ọrọ naa.

O tun rọ awọn eeyan ipinlẹ naa ki wọn maṣẹ ṣe si ofin nitori ijọba oun ko ni dẹkun ati maa ṣiṣẹ fun anfani gbogbo wọn.