Mínísítà tẹ̀lẹ̀ fépo rọ̀bì ní Nàìjíríà farahan níléẹjọ́ fún ẹ̀sùn rìbá tówó rẹ̀ tó £2mílíọ̀nù ní Harrods

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Wọn ti gbe e kalẹ siwaju ile ẹjọ kan nilu London pe owo to le ni miliọnu meji poun owo ilẹ Gẹẹsi ti wọn san ni ileeṣẹ Harolds fun minisita fun epo rọbi nigba naa lorilẹede Naijiria, ẹni ti wọn n fi ẹsun kan bayii pe o gba omilẹgbẹ owo riba lọwọ awọn ileeṣẹ lẹka epo rọbi nipasẹ iṣẹ agbaṣe.

Wọn n fi ẹsun kan Diezani Alison-Madueke ẹni ọdun marundinlaadọrin pe igbe aye irọrun ati igbadun ti ko lẹgbẹ ni wọn ti pese silẹ fun un ni ilẹ Gẹẹsi, eleyi ti ko yọ awọn ile olowo ẹlẹgbẹlẹgbẹ miliọnu pọun, ọkọ bọginni pẹlu awakọ igbalode, irinajo pẹlu baaluu aladani titi kan owo ti iye rẹ jẹ ẹgbẹrun lọna ọgọrun pọun.

Awọn anfani miran to tun gba ni miliọnu mẹrin o le ẹgbẹta ẹgbẹrun pọun ti wọn na fun atunṣe awọn ile kan ni ilu London ati Buckinghamshire, gẹgẹbi wọn ṣe fi to ile ẹjọ to n gbọ ẹjọ rẹ ni Southwark Crown Court leti.

Gbogbo ẹsun maraarun ti wọn wọn kan an lori gbigba riba, ati gbigbimọpọ lati gba abẹtẹlẹ ni Diezani Alison-Madueke ni oun ko jẹbi wọn.

Alison- Madueke ni minisita fun epo rọbi lorilẹede Naijiria laarin ọdun 2010 si 2015 labẹ iṣejọba aarẹ igba naa lorilẹede Naijiria, Goodluck Jonathan.

Wọn sọ fun awọn igbimọ to n gbọ ẹjọ naa pe kaadi isanwo oniṣowo ọmọ Naijiria kan ti orukọ rẹ n jẹ Kọlawọle Aluko ati ileeṣẹ rẹ Tenka Limited ni wọn fi na owo kan lorukọ ni Harolds lorukọ Alison-Madueke.

Wọn tun fi to ileẹjọ naa leti pe minisita tẹlẹ naa ni kaadi iraja aladani to jẹ pe awọn eekan aladanla ni Harolds Rewards Black Tier to jẹ pe wọn gbọdọ ti na owo to le ni ẹgbẹrun mẹwaa pọun lọdun ki eeyan to le gba a.

Wọn tun fi to ileẹjọ naa leti pe o tun fi awọn igba kan gbe ni ilẹ Gẹẹsi nibi ti wọn ti pese ọmọọdọ, aṣọgba atawọn oṣiṣẹ ile miran fun un.

Awọn ileeṣẹ epo ti wọn gba iṣẹagbaṣe olowo iyebiye lọwọ ileeṣẹ epo rọbi Naijiria ni wọn n san owo oṣu awọn oṣiṣẹ naa, gẹgẹbi wọn ṣe fi to ileẹjọ naa leti.

"Iwa riba to nii ṣe pẹlu ileeṣẹ epo rọbi ati afẹfẹ gaasi lorilẹede Naijiria laarin ọdun 2011 si 2015 ni igbẹjọ yii da le lori" gẹgẹbi Aleandra Healy KC to jẹ agbẹjọro olupẹjọ ṣe sọ.

"Lasiko naa, gbogbo awọn to fẹ gba iṣẹ agbaṣe lọwọ ileeṣẹ ipọnpo rọ̀bi Naijiria atawọn isọmọgbe rẹgbogbo ni wọn n fun Alison-Madueke ni owo lọna kan tabi omiran."

Healy tun sọ pe, "o ṣeeṣe ko ṣajeji lara pe nilẹyi la ti n gbọ ẹjọ nipa iṣẹlẹ to ṣẹlẹ nipa riba gbigba nileeṣẹ epo rọbi lorilẹede Naijiria."

"Aye ti lu jara wọn. Riba ati abẹtẹlẹ n ba ọja agbaye jẹ.

"Pataki lo si jẹ fun anfani araalu lati rii pe awọn ohun to n ṣẹlẹlorilẹede wa ko maa ṣe agbodegba fun iwa ibajẹ lorilẹede miran."

Bakannaa ni wọn tun fi awọn fọto ile nla kan ti wọn pe ni The Falls to wa ni Gerrard's Cross, ni Bukinghamshire, eyi ti oniṣowo ọmọ Naijiria kan, Ọlajide Ọmọkore to ni ileeṣẹ Atlantic Energy ra ni ọdun 2010 han igbimọ igbẹjọ ileeẹjọ naa.

Lati ọdun 2011 ni wọn ni Alisson-Madueke ti n lo yara sinima aladani ile naa funrarẹ. Wọn fi to ileẹjọ naa leti pe igba mẹta si mẹrin lo ti lo sibẹ laarin ọdun meji, to si lo ọsẹ mẹfa ni ile kan lati kọ iwe kan nipa aarẹ orilẹede Naijiria.

Lara awọn to ṣiṣẹ fun un nibẹ ni alase kan ati awakọ kan , ti wọn ni oun pẹlu lo maa n ba ra nnkan wale.

Wọn ni eyi ati atunṣe ti owo rẹ to ẹgbẹrun lọna ọọdunrun pọun ni ileeṣẹ Tenka Limited san owo rẹ. Wọn tun sọ fun ileẹjọ naa pe Aluko tun gba iṣẹ agbaṣe ẹẹgbẹlẹgbẹ miliọnu lọwọ ileeṣẹ epo Naijiria naa.

Ileẹjọ naa tun tẹti gbọpe laarin oṣu karun un ọdun 2011 ati oṣu kinni ọdun 2014, ẹgẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta pọun ni wọn tun san gẹgẹbi owo ile ile meji ni agbegbe Central London nibi ti Alison-Madueke ati iya rẹ n gbe.

Awọn iwe ti wọn gba nileeṣẹ Tenka lorilẹede Naijiria fihan pe ileeṣẹ naa lo san awọn owo yii.

Alison joko sinu apoti aga ijẹjọ lẹgbẹ eekan adari ileeṣẹ lẹka epo rọbi, Ọlatimbọ Ayinde ẹni ọdun mẹrinlelaadọta, ti wọn fi ẹsun kan kan to niiṣe pẹlu sisan riba fun Alison-Madueke ati ẹsun miran pe o fun oṣiṣẹ ilẹokeere kan ni riba.

Ẹgbọn Alison-Madueke ọkunrin, to figbakan ri jẹ biṣọọbu agba Doye Agama ẹni ọdun mọkandinlaadọrin pẹlu n jẹjọ ẹsun riba.

Ayinde ati Agama pẹlu ni awọn ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn.

Ọsẹ mejila ni ireti wa pe igbẹjọ naa - to n tẹsiwaju- yoo fi waye.

Ipa ribiribi ni epo rọbi ati afẹfẹ gaasi n ko ninu ọrọ aje orilẹede Naijiria, bi o tilẹ jẹ wi pe awọn mẹkunnu ko tii ri anfani rẹ.

Naijiria jẹ ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ ajọ awọn orilẹede to n wa epo rọbi lagbaye, (Opec), ti wọn gbe kalẹ lati mojuto ipese epo ati iye rẹ lagbaye.