You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Mi ò lówó láti ra ìbò àwọn èèyàn, ìdí rèé tí mo fi fẹ́ dupò Gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo lọ́dún 2027- Oriyomi Hamzat
Lẹyìn ọsẹ diẹ sẹyin to ti kede erongba rẹ lati dupò gomina ipinlẹ Oyo labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Accord Party, gbajugbaja agbohusafẹfẹ ati ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn, Alhaji Hamzat Oriyomi, ti salaye idi to fi dije fun ipo gomina ipinlẹ Oyo lọdun 2027.
Oriyomi ṣalaye ninu ọrọ to fi lede loju opo X ati Facebook rẹ wi pe fun ọpọlọpọ ọdun loun ti ja fun ẹtọ oniruuru eeyan ti oun si n pe fun idajọ ododo.
O ni oun ko maa ṣe eleyii nitori pe oun pe gẹgẹ bi eeyan, bi ko ṣe pe oun fẹ ki gbogbo eeyan wa ni alaafia.
Gbajugbaja agbohunsafẹfẹ naa to jẹ oludasilẹ ileeṣẹ redio Agidigbo FM niluu Ibadan sọ pe oun ko figba kan gbero lati gbegba oṣelu tẹlẹ.
Amọ, o ni bawọn eeyan ṣe n pe oun lọtun losi lati dasi ọrọ oṣelu lo faa.
Oriyomi ni ''Lati igba to ti pẹ lawọn agbaagba, awọn olori to lorukọ rere lawujọ atawọn araalu ti n rọ mi lati dupo oṣelu.
Mi o kọkọ kọbi ara si ọrọ naa tori mi o fẹ ṣe oṣelu, ṣugbọn awọn eeyan o dẹkun pipe mi lati dasi ọrọ oṣelu.
Lọdun to kọja ni emi gan an gan an gbadura si Ọlọrun lori ọrọ naa, ti Ọlọrun si sọ fun mi pe ki n tẹsiwaju.
Idi niyii ti mo fi kede erongba mi lati dupo gomina ipinlẹ Oyo laipẹ yii.
Mi o lowo lati ra ibo awọn eeyan, mi o si lagbara ipinlẹ tabi ti ijọba apapọ.
Bakan naa mi o lawọn janduku ti mo le lo lati dunkoko mawọn alatako mi.
Oriyomi ko tun lawọn janduku ti yoo maa ji apoti idibo gbe, mi o lagbara lori ajọ eleto idibo INEC.
Mi o tun lagbara lati yi esi eto idibo, amọ, agbara mi ni atilẹyin awọn eeyan ti wọn n fẹ ilọsiwaju awujọ wa,'' Oriyomi ṣalaye.
Mo nilo atilẹyin gbogbo eeyan ki gbogbo wa le de ilẹ ileri papọ - Oriyomi
Bakan naa tun ni Alhaji Oriyomi sọ pe ejika awọn ọmọ Naijiria ti wọn wa loke okun ni ẹru orilẹede Naijiria wa.
O ni ẹru naa yoo di fifuyẹ pẹlu igbimọ adari to fẹsẹ mulẹ.
Oriyomi tun sọ fun awọn ọmọbibi ipinlẹ Oyo ti wọn wa loke okun wi pe ọrun awọn eeyan bi toun ni ẹru awọn ibatan wọn to wa nile wa nitori aiṣedeedee ijọba.
Gbajugbaja ajafẹtọọ naa rọ awọn ọmọbibi ipinlẹ Oyo to wa loke okun ati gbogbo awọn to wa nile lati fọwọ sowọ pọ pẹlu oun ninu eto idibo to n bọ.
Ilumọọka agbohunsafẹfẹ naa sọ pe ni bayii tawọn eeyan ipinlẹ Oyo ti pe Oriyomi lati wa sin ilu, o ṣe pataki ki gbogbo eeyan ṣe atilẹyin fun un ''ki gbogbo wa le de ilẹ ileri papọ.''
Oriyomi ni ''a nilo atilẹyin yin to fi mọ iranwọlọwọ yin pẹlu owo bakan naa.
Ẹ tun le ṣerawọ fun mi nipa sisọ fawọn ẹbi yin lati dibo fun mi ti akoko ba ti to,'' Oriyomi lo sọ bẹẹ.