Lẹ́yìn tí Manchester United pòkọ ìyà fún Arsenal ní Emirates, wo bí tábìlì Premier League ṣe rí báyìí

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Nnkan yan ni idije Premier League lalẹ ọjọ Aiku lẹyin ti Manchester United ba Arsenal lalejo ti wọn si tun na wọn mọle.

Ṣaaju ifẹsẹwọnsẹ naa, Arsenal lo n leke tabili Premier league, bẹẹni Manchester United ṣi n ja rabirabi lati mọ ibi to kan lori ọrọ akọnimọọgba, lẹyin ti wọn le Ruben Amorim ti wọn si yan Michael Carrick gẹgẹ bi akọnimọọgba fidihẹ titi fi gba ti wọn yoo yan ẹni ti yoo di ipo naa mu, lopin saa bọọlu to n lọ lọwọ.

Goolu mẹta si meji ni Manchester United fi na Arsenal mọle. Eyi si ni igba akọkọ ti wọn yoo maa pokọ iya fun wọn ni papa iṣire Emirate ni saa yii.

Pẹlu esi ifẹsẹwọnsẹ yii, ayipada ranpẹ ti de ba ipo mẹrin akọkọ to wa loke tabili naa bayii lẹyin ifẹsẹwọn naa.

Ko si omimi kan to ṣi mi arsenal lẹsẹ loke tente tabili pẹlu bi wọn ṣe n dari awọn ẹgbẹ agbabọọlu yooku pẹlu ami mẹrin.

Ẹgbẹ agbabọọlu Manchester city lo tẹle wọn pẹlu ami ayo mẹrindinlaadọta, Aston villa naa ni ami ayo mẹrindinlaadọta lati di ipo kẹta mu ki Manchester United to gbẹnu le wọn pẹlu ami ayo mejidinlogoji.

Chelsea, Liverpool ati Fulham lo tẹle wọn pẹlu ami ayo mẹtadinlogoji, mẹrindinlogoji ati mẹrinlelọgbọn ni ṣisẹ n tẹle.

Ni isalẹtabiliWolves lo wa ni isalẹ patapata pẹlu ami mẹjọ pere, burnley wa ni ipo kọkandinlogun pẹlu ami marundinlogun ti Westham si ni ogun ami.

Nottingham forest, Leed, ati Crystal Palace tun mẹnu le wọn.