You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
'Níṣe ni ẹ̀jẹ̀ bo gbogbo wa' - ẹni tó móríbọ́ níbi ìkọlù àwọn ajínigbé ní Kaduna ṣàlàyè
- Author, Madina Maishanu
- Role, BBC Africa
- Reporting from, Kurmin Wali
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4
Apa nla wa lori Sarah Peter to si n yọ ẹjẹ, lẹyin to moribọ lọwọ awọn ajinigbe agbebọn ti wọn ku ni ẹsẹ.
Sarah, ki i se orukọ rẹ gangan, wa ni ile ijọsin ni apa ariwa orilẹede Naijiria lọjọ Aiku nigba ti awọn agbebọn kọlu ile ijọsin naa, ti wọn si ji awọn olujọsin gbe, ti wọn si ni ki wọn ma fi ẹsẹ rin.
Arabinrin yii, ẹni ọgọta ọdun ni wọn fidi ibọn jan ni ori pe ko rin ni kiakia.
"Ẹjẹ wa ni gbogbo ayika," o sọ, to si n nawọ si ibi ti ap awa lara rẹ.
"Iya jẹ mi," o fikun, o han pe eru n to lakọja si n ba lẹyin ọjọ mẹta.
"Wọn n wọ mi nilẹ, lẹyin t imo sọ fun wọn pe n ko le rin mọ. Mo ni lati ṣa pamọ sib ikan titi n ko fi ri wọn mọ. O rẹ mi si ara, mo wọ pada si inu ilu pada ni."
Ọpọ eeyan ni wọn gbe ni ẹka ile ijọsin Cherubim and Seraphim Movement Church ati ile ijọsin mii ni agbegbe Kurmin Wali, abule kan ti ko jina si olu ilu Abuja.
Eeyan mọkanla ri anfani lati sa mọ awọn agbebọn naa lọwọ, to fi mọ Sarah, o le ni eeyan 116 ti wọn ko le sọ ibi ti wọn wa bayii, gẹgẹ ajọ CAN se ṣalaye.
Ibẹrubojo ni awọn araalu naa wa bayii, ti ẹru si n ba wọn pe ki awọn agbebọn ma tun kọlu wọn.
Awọn alaṣẹ ko ti sọ iye eeyan pato ti awọn agbebọn ji gbe.
Kurmin Wali wa ni tosi ipinlẹ Kaduna, jẹ ibudo ipamọ fun awọn agbebọn ti wọn n ji awọn gbe ni agbegbe naa.
Ko si ẹgbẹ kankan to ti jade sita pe awọn ni awọn wa lẹyin ikọlu naa.
Sisan owo itusilẹ lorilẹede Naijiria jẹ ohun to tako ofin ṣugbọn ni ọpọ igba owo ni awọn ajinigbe yii ma n gba ki wọn to tu awọn eeyan silẹ.
Olori ilu naa ni awọn araalu ti n gbe ninu ibẹrubojo fun igba diẹ bayii. Awọn araalu si n rọ ijọba pe ki wọn mojuto eto aabo, ti wọn si fẹsun kan wọn pe wọn ko fẹ ki wọn sọrọ sita lẹyin ikọlu naa.
"Wọn sọ fun wa pe a ko gbọdọ sọ nkankan sita, wọn fẹ pa wa lẹnu mọ ṣugbọn a ni lati sọ itan wa. Bakan naa ni wọn ko jẹ ki awọn akọroyin raye wọ inu ilu," eyi ni ọdọmọkunrin kan, ti ko fẹ ki a darukọ oun.
A lo le sọ boya otitọ ni eyi ṣugbọn Gomina ipinlẹ Kaduna, Uba Sani sọ fun BBC pe awọn fẹ fidi iroyin naa mulẹ ki wọn to fi atẹjade sita.
Ileeṣẹ BBC na koju iṣoro ki a to le de Kurmin Wali, lẹyin ti oloṣelu ati ẹsọ alabo gbiyanju lati gbegi da wọn lọna.
Ṣugbọn a ri daju pe a wọ ilu naa, ti a si de sibi ti iṣẹlẹ naa ti waye.
Ọpọ nnkan bi iwe adura ni wọn da silẹ pẹlu aga ati awọn irinsẹ orin.
Gomina Sani wa si ilu Kurmin Wali lẹyin ọjọ mẹta ti iṣẹlẹ naa waye, to si ṣe ileri pe wọn yoo da ibudo awọn ọmọ ologun silẹ, ile iwosan ati ọna igbalode si agbegbe naa.
Bakan naa lo kede pe ijọba yoo pese ohun iranwọ fun awọn eeyan to lugbadi iṣẹlẹ naa, to fi mọ eto ilera.
"A ko le gbe wọn kuro ni agbegbe nitori wọn ni lati dako…. ṣugbọn a mari daju pe a pese aabo fun wọn, a nilo ibudo awọn ọmọ ologun laaarin agbegbe yii ati igbo Rijana, o sọ fun BBC.
O fikun pe iṣẹ n lọ lọwọ bayii lati doola ẹmi awọn eeyan to si w ani igbekun awọn ajinigbe naa.