You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ṣé lóòótọ́ ni ìjọba fọwọ́ òsì júwe ilé fún olóyè lórí ọ̀rọ̀ yíyan Awujale Ijebu?
Ileeṣẹ ijọba nipinlẹ Ogun to n ri si oye jijẹ ati ijọba ibilẹ ati ijọba ibilẹ Ijebu Ode ti wọgile iroyin ẹlẹjẹ kan to n ja kiri pe ijọba ipinlẹ Ogun ti fọwọ osi juwe fun awọn agba oye mẹta niluu Ijebu Ode.
Eyi wa ninu atẹjade kan ti Kọmisana fun ijọba ibilẹ ati oye jijẹ, Ganiyu Hamzat ati alaga ijẹbu Ode, Dara Alebiosu buwọlu fun awọn akọroyin lọjọ Ẹti.
Ṣaaju ni iroyin ẹlẹjẹ naa ni Kakanfo ti Ijebu, Oloye Abimbola Okenla; Lapoekun ti Ijebu, Oloye Tunde Odulaja; ati Madasa ti ijebu, Oloye Lekan Oshifeso, ni ijọba ti yọ kuro ninu igbimọ awọn oloye ni Ijebu.
Ẹwẹ, awọn alaṣẹ nipinlẹ Ogun ti jẹ ko di mimọ pe irọ to jina si otitọ ni eyi, ti ijọba ko si gbe irufẹ igbesẹ bẹẹ.
"Ileeṣẹ ijọba ipinlẹ Ogun to n risi ijọba ibilẹ ati oue jijẹ, pẹlu ajọsepọ ijoba ibilẹ Ijebu Ode, wọgile iroyin ẹlẹjẹ yii, eyi to n si ọpọ eeyan lọna lori ayelujara pe ijọba gba oye lọwọ awọn oloyr bi Kakanfo ti Ijebu, Oloye Abimbola Okenla, Lapoekun ti Ijebu, Oloye Tunde Odulaja, ati Madasa ti Ijebu, Oloye Lekan Oshifeso," atẹjade naa ṣalaye.
Atẹjade tun ṣapejuwe iroyin naa gẹgẹ bii eyi to ni erongba lati omi alaafia ijebu ru lasiko yii.
O fikun pe jijẹ oye ni ilẹ Ijebu jẹ ohun ti ofin ati ilana wa fun, ti ilu ati ijọba si n tẹle ilana naa.
"Oye jijẹ jẹ ohun to ni ofin ati ilana ti wọn tig be kalẹ, a n rọ awọn araalu lati yago fun iroyin ẹlẹjẹ to fẹ da alaafia ilu laamu."
Tẹ o ba gbagbe, Ojoru ọsẹ yii ni ijọba ipinlẹ Ogun fi atẹjade kan sita, ninu eyi ti Kọmiṣanna fun ọrọ oye jijẹ nipinlẹ naa, Ganiyu Hamzat, ti ni ki wọn dawọ eto nipa yiyan Awujale tuntun duro.
Atẹjade ijọba naa sọ pe nitori ati dena wahala ni igbesẹ naa ṣe ṣe pataki.
Wọn ni awon ti gba ọpọ ifisun lori ilana to n lọ lọwọ naa, latọdọ awọn ẹṣọ alaabo ati awọn ti ọrọ oye naa kan.
Eyi naa lo fa a ti awuyewuye fi gbode, pe ijọba Ogun fẹ fipa yan Awujalẹ tuntun le awọn eeyan lori, ki wọn si fi ẹtọ awọn Fusengbuwa dun wọn ni.