You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa Alex Pretti, arákùnrin táwọn agbófinró ICE pa ní Minneapolis, tí ikú rẹ̀ ń dá èdèàìyedè sílẹ̀ l'Amerika
- Author, Jacob Phillips
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4
Arakunrin kan ti awọn agbofinro ijọba apapọ lorilẹede Amẹrika yinbọn fun ni ilu Minneapolis, lawọn eeyan ti darukọ rẹ gẹgẹ bii Alex Pretti, ẹni ọdun mẹtadinlogoji ti wọn ni iṣẹ nọọsi lo n ṣe.
Awọn to mọọ sọ wi pe ẹni to fẹran lati maa jade ni, nitori pe o fẹran lati maa gun awọn oke pẹlu kẹkẹ, wọn ni oun pẹlu darapọ mọ iwọde lẹyin ti awọn agbofinro aṣọbode ICE ti kọkọ yinbọn pa arabinrin Renee Good, ẹni ọdun mẹtadinlogoji ninu ọkọ rẹ loṣu to kọja.
Oniruuru ọrọ lawọn eeyan ti n sọ nipa bi iku oloogbe naa ṣe waye.
Ajọ to n mojuto abo ilu lorilẹede Amẹrika, DHS sọ pe awọn agbefọba to yinbọn pa a fi ibọn daabo bo ara wọn ni, lẹyin ti Pretti ẹni ti wọn sọ ei pe o mu ibọn dani, kọ lati jọwọ ara rẹ fun awọn agbofinro naa. Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn, awọn oṣiṣẹ ijọba kan atawọn mọlẹbi oloogbe naa, sọ wi pe irọ nla ni.
Ninu awọn fidio iṣẹlẹ naa to jade sita ko si ibi kankan ti o ti jọ pe o fi ohun ija kankan dunkoko mọ awọn agbofinro naa.
Awọn mọlẹbi rẹ ni Pretti ko figba kankan ni itahunsi pẹlawọn agbofinro, tabi tẹ oju ofin mọlẹ ri
Ẹka itọju iṣẹlẹ pajawiri ni ileewosan Minneapolis Veterans Hospital ni Pretti ti n ṣiṣẹ, gẹgẹbi atẹjade kan ti awọn ẹbi rẹ fi sita. Wọn fi to ileeṣẹ akoroyinjọ Associated Press (AP) pe igbesẹ Aarẹ Trump lati gbogun ti awọn atipo lo bii ninu to fi lọ darapọ mọ iwọde naa.
Iya Pretti ṣalaye pe, ọmọ oun kan sara si igbesẹ Aarẹ Trump lori idaabobo ayika.
O fi kun un pe: "Jadejade ni nigba aye rẹ. Oun ati aja rẹ ni wọn si maa n lọ si ibikibi to ba n lọ. O fẹran orilẹede yii, ṣugbọn o korira oun ti awọn eeyan n ṣe ninu rẹ."
Awọn ẹbi rẹ ni ko si ohun to da oun atawọn agbofinro papọ ri nigba kọọkan, lẹyin boya ki wọn ja tikẹẹti fun tori ofin irinna. Gẹgẹbi ileeṣẹ akoroyinjọ AP ṣe sọ, kọsilẹ ile ẹjọ fihan pe ko hu iwa ọdaran ri nigbakankan.
"Ẹ jọwọ ẹ ba wa wa idi otitọ jade nipa ọmọ wa'
Lẹyin ti wọn ri fidio ti o jade tawọn kan n sọ pe "agbesunmọmi abẹle" lọmọ wọn, awọn mọlẹbi Pretti ti fi atẹjade sita ninu eyi ti wọn ti n sọ pe, " irọ ni ijọba n pa nipa awọn ọrọ ti wọn sọ nipa ọmọ wa"
Wọn ni fidio iṣẹlẹ naa fihan pe Pretti ko mu ibọn kankan dani lasiko ti awọn agbofinro ijọba apapọ kọluu.
"Ẹ jọwọ ẹ ba wa wadii otitọ nipa ọmọ wa. Eeyan daadaa ni, "
Iyawo rẹ tẹlẹ gan tun ṣalaye pe, Ẹgbẹ oṣelu Democratic ni Pretti dibo fun, o si ti darapọ mọ oniruuru iwọde lẹyin iku George Floyd latọwọ ọlọpaa kan lọdun 2020.
O ni Pretti le maa pariwo mọ awọn agbofinro lasiko iwọde o, amọṣa kii ṣe eeyan to le ba agbofinro fa wahala.
Ọmọ orilẹede Amẹrika ni Pretti, ilu Illinois ni wọn bii si. Oloogbe Alex Pretti dagba si Green Bay, Wisconsin nibi to ti gba bọọlu afẹsẹgba, bọọlu afi ponpo gba-baseball, to si tun sa ere ori papa fun ile ẹkọ giga Preble High School. Bakannaa lo wa ninu ẹgbẹ Boys scout to si tun darapọ̀ mọ ẹgbẹ akọrin Green Bay Boy Choir.
O lọ silẹ ẹkọ giga fasiti Minnesota, nibi to ti kẹkọ gboye imọ ijinlẹ nipa ara, Baọlọji,awujọ ati ọrọ ayika, gẹgẹbi awọn ẹbi rẹ ṣe sọ.
O ṣiṣẹ gẹgẹbi oluwadi imọ ijinlẹ ki o to pada lọ kawe sii lati kẹkọ gboye nọọsi.
Ilu Winsconsin lawọn obi Pretti n gbe, wọn si ni awọn ti sọ fun laipẹ yii pe ko rọra ṣe pẹlu ọrọ iwọde.
Micheal Pretti to jẹ baba Alex ṣalaye fun AP pe: "A ṣe ba sọ ọrọ yii ni nnkan bii ọsẹ meji sẹyin, pe lootọ a o ni ko maa lọ se iwọde o ṣugbọn maṣe ṣe nnkan kan to ku diẹ kaato nibẹ"
"O si sọ pe oun ti gbọ. Oun naa mọ."
Bakan naa lawọn ẹbi rẹ tun sọ pe lootọ lo ni ibọn ilewọ, to si gba iwe aṣẹ lati gbe ibọn ilewọ dani ni ipinlẹ Minnesota - ṣugbọn awọn o rii kogbe e dani ri.
Ọga ọlọpaa Brian O'Hara pẹlu fidi rẹ mulẹ fun ileeṣẹ iroyin CBS to jẹ alabaṣiṣẹpọ BBC lorilẹede Amẹrika, pe oun gbagbọ pe o ni iwe aṣẹ lati gbe ibọn dani.
Awọn aladugbo rẹ sọ pe eeyan jẹjẹ ti kii sọrọ pupọ ni
"Eeyan daadaa ni" lọrọ ti Sui Gitar to n gbe ni isalẹ ile ti Pretti gbe sọ fun AP. O ni ọdun mẹta sẹyin lo ko wọ ile naa.
"Mio roo ri pe eeyan to le gbe ibọn dani ni"