Gbogbo ètò ló ti tò láti yọ orúkọ Sunday Igboho kúrò nínú ìwé àwọn ọ̀daràn tí ìjọba ń wá - Olugbon

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Olugbon ti Orile Igbon, Oba Francis Olushola Alao, ti sọ pe gbogbo eto lo ti to bayii lati yọ orukọ ajijagbara fun idasilẹ Yoruba Nation, Sunday Adeyemo ti ọpọ mọ si Sunday Igboho, kuro ninu iwe awọn ọdaran ti ijọba n wa.

Kabiyesi Olugbon fidi ọrọ yii mulẹ lasiko to ba BBC Yoruba sọrọ lọjọ Aje ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu Kinni ọdun yii.

Olugbon ni oun gẹgẹ bi ẹnikan ti n ṣe akiyitan lori bi Igboho yoo ṣe gba ominira rẹ pada ti ijọba yoo si yọ orukọ rẹ kuro ninu iwe awọn ọdaran tawọn ẹṣọ eleto aabo n wa.

Ori ade naa tun sọ pe Olubadan ti ilẹ Ibadan, Ọba Rashidi Ladoja ati Ooni Ile Ife, Ọba Adeyeye Enitan Ogunwusi naa n ṣe akiitiyan lati ri pe orukọ Igboho kuro ninu iwe awọn ọdaran ti ijọba n wa.

''Ohun ti mo mọ ni pe ọrọ Igboho wa lara nnkan ti Olubdan ba Aarẹ Bola Tinubu sọ lasiko ti o ṣabẹwo si aarẹ lọsẹ to kọja.

Mo si mọ pe ọrọ naa fori gun ibikan pẹlu Aarẹ Tinubu.

Ọrọ ọhun ti pari tori inu ijọba dun si akitiyan awa lọba lọba lori ọrọ naa.

Sunday Igboho n pada bọ wale laipẹ, lai jinna.

Ijọba naa n ṣe gbogbo eto ti wọn ni lati ṣe lọwọ bayii lati yọ orukọ Igboho kuro ninu iwe awọn ọdaran ti wọn n wa.

Mo sa ipa mi lori ọrọ yii gẹgẹ bi ẹnikan, Olubadan naa sapa tirẹ, bakan naa ni Ooni Ile Ife naa dasi ọrọ ọhun.

Ki a to ri ọjọ meloo kan bayii, Igboho yoo pada wale, orukọ rẹ yoo si kuro ninu awọn ọdaran ti ijọba n wa,'' Olugbon lo sọ bẹẹ.

Owo Baba Dami ti ṣetan lati pada sile - Koiki

Ṣaaju ni agbẹnusọ fun Igboho, Olayomi Koiki, ti kede loju opo Facebook rẹ pe Owo Baba Dami ti ṣetan lati pada sile lẹyin to ti wa loke okun fun ọdun mẹrin nibi to ti n ṣe atipo.

Koiki naa ni gbogbo eto lo ti to bayii lati fun Igboho ni ominira rẹ pada, lẹyin ti Olubadan ilẹ Ibadan, Olugbon ti Orile Igbon ati Ooni Ile Ife ti dasi ọrọ naa.

Agbẹnusọ Igboho ni ajijagbara fun idasilẹ Yoruba Nation naa maa to gba ominira rẹ pada kete ti ijọba apapọ ba ti pari iṣẹ lori ati yọ orukọ rẹ kuro ninu iwe awọn ọdaran ti wọn n wa.

Ti ẹ o ba gbagbe, lẹyin ti ajọ DSS yabo ile rẹ to wa lagbegbe Soka niluu Ibadan nibi tawọn iṣọmọgbe rẹ kan ti ku lọjọ kinni oṣu Keje ọsun 2021 ni Igboho sa kuro ni Naijiria.

Ẹsun ti wọn fi kan Igboho ni pe o n ko nnkan ija oloro pamọ sinu ile.

Lẹyin naa ni ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari fi orukọ rẹ sinu iwe awọn ọdaran ti ijọba n wa.

Ta ni Sunday Igboho ti ijọba fẹ yọ orukọ rẹ kuro ninu iwe awọn ọdaran ti wọn n wa?

Sunday Adeyemo, ti ọpọ mọ si Sunday Igboho, jẹ gbajumọ ajafẹtọ ẹni to n pe fun idaduro ilẹ Yoruba, Yoruba Nation.

Lasiko to bẹrẹ ipe fun idaduro ilẹ Yoruba, ni oru mọjumọ ọjọ kini, oṣu keje, ọdun 2021 ni awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ, DSS lọ kọlu ile Sunday Igboho.

Wọn pa awọn eeyan meji, ti wọn si ko awọn mẹtala lọ siluu Abuja amọ ori ko Igboho yọ, to si salọ si orilẹede Benin.

Ẹsun ti DSS fi kan Igboho ni pe o n ko ibọn ati awọn ohun ija oloro pamọ lati da ogun silẹ laarin ilu, ti wọn si gbẹsẹle awọn apo asunwọn owo rẹ to wa ni Naijiria.

Ọjọ Aje, ọjọ kọkandinlogun, oṣu keje, ọdun 2021 ni ileeṣẹ eleto aabo Interpol mu Sunday Igboho ni papakọ ofurufu Cadjèhoun to wa ni Cotonou ti ilẹ olominira Benin.

Alẹ ọjọ naa la gbọ pe Igboho n gbiyanju lati ri irin ajo lọ si orileede Germany pẹlu iyawo rẹ Rọpo Adeyẹmọ.

Ọjọ kẹtalelogun, oṣu keje, ọdun 2021 ni Igboho foju ba ile-ẹjọ Cour D'Appel De Cotonou lori ẹsun wi pe o wọ orileede naa lọna aitọ ati nini ayederu iwe irinna orileede naa.

Oṣu mẹsan gbako ni Igboho lo ni ahamọ inu ile ni ilẹ olominira Benin, ko to di pe o gba ominira.

Kete si lo morile ilẹ Germany nibi to n gbe amọ laipẹ yii lo pada wa sile, to si n beere fun ominira pipe ati idapada apo asunwọn owo rẹ tijọba gbẹsẹ le.