Jide Kosoko di ọmọ oyè Oloja ìlú Eko

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Idile Ọba Kosoko, Kosoko Royal Family, ti kede agba oṣere tiata, Ọmọọba Jide Kosoko, gẹgẹ bii ọmọ oye Oloja ti ilu Eko.

Jide Kosoko funra rẹ lo fidi iroyin naa mulẹ fun BBC Yoruba ninu ifọrọwerọ kan amọ o ni oun ko tii le sọrọ pupọ nipa rẹ bayiii titi di igba ti awọn mọlẹbi yii kede ọjọ iwuye.

Aga oye naa lo ṣofo lẹyin iku Oloye Adebola Ige to waye lọjọ kẹtalelogun, oṣu Kejila, ọdun 2017.

Agba oṣere naa ni olori ẹbi Kosoko, Mutiat Ali-Balogun kede, to si fa ọwọ rẹ soke nibi ipade ẹbi wọn to waye lagbegbe Lagos Island, niluu Eko.

Bi ọrọ ikede oye naa ṣe waye

Igbesẹ lati kede Jide Kosoko yii lo waye lẹyin ti ẹbi Akinsanya Olojo, to jẹ ọkan lara idi mọlẹbi Ọba Kosoko rọ gomina Babjide Sanwo-Olu ko yan Abiola Olojo-Kosoko gẹgẹ bii Oloja ilu Eko.

Ninu oṣu Kejila, ọdun 2025, ileeṣẹ iroyin abẹle Punch jabọ pe mọlẹbi sọ pe ọgbẹni Abiola lawọn yan lọjọ kejila, oṣu Kejila, ọdun 2020 amọ wọn ko ṣe iwuye rẹ fun odidi ọdun mẹrin gbako.

Ẹbẹ naa lo wa ninu atẹjade kan si gomina, ti wọn tun fi ṣọwọ si awọn eeyan pataki ni ijọba bii adajọ agba ipinlẹ naa, akọwe ijọba, kọmiṣọna fun ọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ, olori idile Kosoko, atawọn mii.

Akọwe idile Akinsanya Olojo-Kosoko, Theophilus Olojo-Kosoko, sọ pe mọlẹbi naa ti kọ lẹta kan lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun 2025, wọn si ti fi ṣọwọ si awọn ti ọrọ kan lati ṣiṣẹ lori rẹ.

Ọjọ iwuye

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, oṣere naa sọ pe ọjọ iwuye loun n duro de bayii fun awọn mọlẹbi lati kede.

Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, Ọba ilu Eko, Ọba Rilwanu Akiolu, ni yoo ja ewe oye le Jide Kosoko lori gẹgẹ bii aṣa ilẹ naa ati bi wọn ṣe maa n ṣe e lati igba iwasẹ.

Kosoko, to kẹkọọ nipa owo ṣiṣẹ nile ẹkọ Yaba College of Technology ipinlẹ Eko bẹrẹ iṣẹ tiata lọdun 1974 ninu ere Maknjuola ti wọn gbe jade lori ẹrọ amohunmaworan lọdun naa lọhun.

O ti kopa ninu oriṣiriṣi iṣẹ tiata ni ede Yoruba ati ni ede Gẹẹsi ni Naijiria.

Jide Kosoko jẹ ọkan lara awọn oṣere ti irawọ wọn tan julọ nidi iṣẹ tiata ni Naijiria, ati ọkan lara awọn ti araye bu iyi fun julọ nidi iṣẹ ọhun.