You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Agbésùnmọ̀mí kọlu Zamfara láago méjìlá òru, jí èèyàn 26 gbé lọ
Ijọba ipinlẹ Zamfara ti fidi rẹ mulẹ pe wọn ti ji eeyan mẹrindinlọgbọn gbe lọ ni ijọba ibilẹ Talatar Mafara, nipinlẹ naa.
Talatar Mafara yii jẹ ọkan lara awọn ijọba ibilẹ ti iṣẹlẹ ijinigbe ti maa n waye lemọlemọ lati ọdun 2021.
Ijọba ibilẹ yii kan naa ni awọn agbesunmọmi ti ji akẹkọọ 300 gbe nile ẹkọ Jangebe Girls' School.
Nigba to n ba BBC sọrọ, alaga ijọba ibilẹ Talatar Mafara, Yahaya Yari Abubakar, sọ pe ikọlu meji ọtọtọ lo waye lopin ọsẹ.
Abubakar sọ pe abule kan ti wọn n pe ni Matuna ni wọn kọkọ kọlu ti wọn ti ji eeyan mẹta lọ ki wọn to tun pada wa.
O ni "Wọn ji eeyan mẹtalelogun gbe lọ, wọn tun yinbọn lu ẹnikan lọwọ ati lẹsẹ. A ti gbe ẹni naa lọ sile iwosan ni Jangebe nibi to ti n gba itọju lọwọ."
Bi ikọlu ọhun ṣẹ waye
A gbọ pe nnkan bii aago mejila oru lawọn agbesunmọmi naa ya bo agbegbe ọhun ti wọn si bẹrẹ si n yinbọn fun odidi wakati meji gbako.
Abubakar ṣalaye pe alupupu lawọn agbebọn naa gbe wa fun ikọlu ọhun pẹlu oniruru ohun ija oloro lọwọ wọn.
O ni aarin adugbo ni wọn gbe igbọn ohun si lori irin onigun mẹta kan ti wọn si bẹrẹ si n yin in lati tu awọn eeyan ka.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, bi wọn ṣe n fi ẹsẹ le awọn eeyan kan lawọn mii ninu wọn n fi alupupu le awọn eeyan mii.
Ẹnu lọlọ yii ni awọn agbebọn tunbọ jawe sobi ikọlu wọn ni Naijiria ti wọn si n ji awọn eeyan gbe lati gba owo itusilẹ.
Lọsẹ to kọja, wọn kọlu Kajuru nipinlẹ kaduna nibi ti wọn ti ji olujọsin 170 gbe ninu ṣọọṣi.
Bo tilẹ jẹ pe awọn kan ninu wọn moribọ, nnkan bii 130 ninu wọn lo ṣi wa lakata ajinigbe bayii.