You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àwọn mọ́kànlá tí wọ́n jí gbé ní Kwara sá mọ́ ajínigbé lọ́wọ́, ó ku ọmọ ọdún méjì lákàtà wọn
Awọn araalu Isapa ni ijọba ibilẹ Ekiti, ni ipinlẹ Kwara ti awọn ajinigbe ji gbe lọ ti gba ominira bayii.
Wọn gba ominira yii lẹyin ti wọn sa mọ awọn ajinigbe to gbe wọn lọwọ.
Ohun to ṣe ni laanu ni pe, ọmọ ọdun meji to jẹ ọmọ ọkan lara awọn ti wọn ji gbe ọun ko mori bọ.
Ni ọjọ kẹrinlelogun osu kọkanla ọdun to kọja ni awọn ajinigbe ya wọ ilu naa ti wọn si ji eeyan mọkanla gbe sa wọ inu igbo lọ.
Gbogbo igbiyanju awọn ẹbi ati ilu Isapa lati doola awọn ti wọn ji gbe yii si lo ja si pabo.
A mọ, ni ọsẹ to kọja, a gbọ wi pe, ori ti ko wọn yọ lẹyin ti wọn sa mọ awọn ajinigbe naa lọwọ.
Báwo ló ṣe ṣẹlẹ̀ gan-an
BBC Yoruba kan si olu ọdẹ ilu Isapa, akọni Adeyeye lori ago, leyi to salaye bi ori ṣe ko wọn yọ.
"Awọn ajinigbe yii pe lọjọ kan wi pe alaboyun to wa lara awọn ti awọn ji gbe se aisan, awọn o si fẹ ko ku si akata awọn.
"Wọn wa ni ki a tete gbe owo millionu mẹrin (N4million) wa ki awọn si jọwọ alaboyun naa fun wa.
"A sare wa owo naa, a si gbee ran awọn ọkunrin meji kan".
Àwọn ajínigbé jọ̀wọ́ aláboyún, mú àwọn tí wọ́n gbé ránsọ́mù lọ mọ́lẹ̀
"Nigba ti wọn de ibẹ, awọn onisẹ ibi yii gbe alaboyun de ibi ti yoo ti mọna pada si ile, sugbọn wọn mu awọn meji ti wọn gbe owo lọ mọlẹ, wọn si n bere ransọmu lori awọn naa.
"Alaboyun yii dele, inu wa dun, amọ ọkan wa tun gbọgbẹ nitori yatọ si owo ti a san, eniyan meji ni wọn fi rọpo eniyan kan fun wa.
"Kaka ti wọn o fi dinku si mẹsan-an, ni ṣe ni wọn le di mọkanla".
Olu ọdẹ naa sọ pe alayee ti wọn se fun oun nigba ti wọn de ni pe, awọn ajinigbe naa le ni ọgbọn niye sugbọn eeyan meji pere ni wọn maa n fi sọ awọn nigbati awọn yooku ba jade.
"Wọn salaye fun mi pe, lọjọ kan, wọn jade lọ bi wọn ṣe maa n se, wọn si fi eeyan meji sọ awọn.
"Eyan kan gbe ibọn, eeyan kan gbe ada, sugbọn ni aarin kan eeyan to gbe ibọn sere lọ, o wa ku alada nikan.
"Gbogbo awọn ọkunrin ni wọn fi sẹkẹ de lẹsẹ sugbọn wọn o so awọn obinrin rara.
"Toun ti sẹkẹsẹkẹ lẹsẹ, awọn ọkunrin tiraka, wọn gidi alada yii latẹyin, bi wọn ṣe mu ni awọn obinrin bẹ sinu igbo wọn si n salọ lọtọọtọ gẹgẹ bii wọn ṣe gbimọ rẹ.
"Wọn fi ipa yọ kọkọrọ lapo rẹ lati tu ide ẹsẹ wọn sugbọn o fi ada ọwọ rẹ sa ikan lori bi wọn ṣe n se eyi.
"Sugbn wọn o duro, gbogbo wọn sa mọ-an lọwọ ayafi arabinrin kan ti ọmọ ọdun meji ọwọ rẹ o jẹ ko raye sare daada.
"O ri obinrin yii mu pada si ibuba wọn, a mọ obinrin yii pada raye sa mọ-an lọwọ sugbọn ko gbe ọmọ ọdun meji rẹ dani lọtẹ yii.
Olu ọdẹ naa sọ pe inu awọn dun gan-an nitoripe gbogbo wọn ni wọn ti dara pọ ẹbi wọn nile.
O ni ẹni ti o de gbẹyin ni iya bẹskẹ to de ni ọjọ meji sẹyin, ọjọ kẹrinlelogun, osu yii.
O ni ọmọ ọdun meji nikan lokun lakata awọn ajinigbe bayii.