Òkùnkùn birimù bí ìtàkùn iná mọ̀nàmọ́ná Naijiria tún ṣe da'ṣẹ́ sílẹ̀ fún ìgbà kejì lọdún 2026

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Okunkun birimu lẹyin ti itakun ina mọnamọna orilẹede Naijiria tun daṣẹ silẹ fun igba keji ninu ọdun 2026 yii.

Lasiko ti iroyin yii jade, a gbọ pe ileeṣẹ to n pese ina ọba ni Naijiria ko ri ina kankan pin fun awọn ileeṣẹ apinaka mọkanla mọ.

Ọjọ Ẹti ọsẹ to kọja ni itakun ina mọnamọna naa kọkọ da iṣẹ silẹ ninu ọdun 2026 yii.

Eyi waye lẹyin ọsẹ diẹ ti iru iṣẹlẹ ọhun ti kọkọ waye lọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Kejila ọdun 2025 to kọja eyi to ju ọpọ eeyan ni Naijiria si okunkun birimu.

Gẹgẹbi bi ohun tawọn alaṣẹ ileeṣẹ to n pin ina lorilẹede Naijiria sọ, agbara ina to wa ninu aka ipinna mọnamọna ja lati ẹgbẹrun mẹrin abọ mẹgawaati bọ si mẹgawaati odo laaarọ oni ọjọ Iṣẹgun.

Oriṣiiriṣii idi ni a gbọ pe o n ṣokunfa itakun ina mọnamọna to n daṣẹ silẹ loorekoore ni Naijiria.

Awọn akọṣẹmọṣẹ nipa ina mọnamọna sọ pe ai maa ṣe atunṣe to yẹ loorekoore lori awọn waya ina wa lara awọn nnkan to n fa a.

Awọn mii tun sọ pe ai maa pese ina ọba to to naa le maa jẹ ki itakun ina mọnamọna maa daṣẹ silẹ loorekoore.

Ni nnkan bii ago mọkanla aarọ oni ọjọ Iṣẹgun ni itakun ina mọnamọna Naijiria daṣẹ silẹ ti ọpọ ko si ri ina lo mọ lẹsẹ kẹsẹ.

Iroyin fidi rẹ mulẹ pe lẹsẹ kẹsẹ ti itakun ina ọhun daṣẹ silẹ naa ni gbogbo awọn ẹrọ amunawa to n gba ina lati ara rẹ ko ri ina kankan lati pin mọ fawọn ileeṣẹ apinaka mọkanla.

A ko tii le sọ nnkan to ṣokunfa bi itakun ina mọnamọna tun ṣe daṣẹ silẹ lonii.

Awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ TCN to n ri si ipese ina ni Naijiria ko tii sọrọ lori nnkan to ṣẹlẹ gan an.