You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wo ohun tuntun tí iléeṣẹ́ ológun ń sọ nípa àwọn ọmọogun tó gbìyànjú gbígba ìjọba lọ́wọ́ ọ Tinubu, ohun tójú wọn yóò rí
Ileeṣẹ ologun Naijiria ti sọ wi pe àwọn ọmọogun kan yoo foju ba ile ẹjọ ologun lẹyin ti iwadii pari lori ẹsun iditẹgbajọba ti wọn fi kan wọnlọdun to kọja.
Eyi wa ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ ologun Naijiria fi soju opo ayelujara rẹ pe ọmọ ogun mẹrindinlogun ni ọwọ tẹ ninu oṣu kẹwaa ọdun 2025, ti wọn si ti fi ẹsun iwa ibajẹ ati titapa sofin kan wọn.
Lọdun 2025, ileeṣẹ ologun kọkọ wogile iroyin nipa iditẹgbajọba ṣugbọn ọpọ iwadii, awọn alaṣẹ fidi iṣẹlẹ naa, ti wọn si jẹ ko di mimọ ọmọ ologun mẹrindinlogun yoo farahan ni ile ẹjọ.
Orilẹede Naijiria ni ọpọ itan to da lori ijọba ologun ati ijọba awarawa, ti ọpọ iditẹgbajọba si waye laarin ọdun 1966 si 1993, eyi lo fa ti ibẹrubojo ti wọpọ lọdun to kọja.
Ko ti han tabi daju iye awọn ọmọ ologun ti yoo foju ba ile ẹjọ ṣugbọn awọn alaṣẹ ileeṣẹ ni igbesẹ yii foju waye ni ilana ti ofin la kalẹ, lia si mọdaru.
Atẹjade naa fikun pe gbigbero lati gba ijọba lọwọ aarẹ ti ilu dibo yan tako ofin ati ilana ileeṣẹ ologun Naijiria.
Lọwọ yii lorilẹede Naijiria, iṣoro eto aabo ati ibinu araalu wọpọ, to si jẹ pe ohun lo n fa ti ọpọ iroyin ofege fi n lọ kiri pe awọn ọmọ ologun kan n gbero lati gba ijọba lọwọ Aarẹ to wa lode lasiko yii.
Ọdun 1999 ni o jẹ opin ijọba ologun lorilẹede Naijira, to si jẹ pe lati gba naa ni awọn ologun ti ni awọn yoo tẹriba fun ijọba awarawa.
Ọpọ awọn orilẹede to yi orilẹede Naijira ka ni wọn wa labẹ ijọba ologun lasiko, bi Mali, Burkina Faso, Niger ati Guinea, bo ti lẹ jẹ pe orilẹede Guinea ti pada si ijọba awarawa labẹ iṣejọba Aarẹ Mamadi Doumbouya, ti ilu dibo yan sipo.
Wọnyi ni awọn igba ti Naijiria koju iditẹgbajọba lati ọwọ ologun
Latigba ti Naijiria ti gba ominira ni 1960 ni wọn ti n koju iditẹgbajọba.
Laaarin 1966 si 1999, awọn ologun lo dari Naijiria lai si idiwọ kan, yatọ si asiko ijọba awaraawa ranpẹ to waye ni 1979 titi de 1983.
Awọn iditẹgbajọba to ti waye ni Naijiria:
- Ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kin-in-ni ọdun1966: Ikọ ọjẹwẹwẹ ologun kan doju ijọba Naijiria de, wọn si fopin si ijọba awaarawa akọkọ ti Naijiria ni.
Kaduna Nzeogwu ni ṣọja to ṣaaju awọn ologun naa, wọn si pa awọn olori bii Tafawa Balewa, Ahmadu Bello, Ladoke Akintola, Festus Okotie-Eboh to jẹ minisita eto iṣuna ati awọn ọga ṣọja mẹrin l'Oke-Ọya.
Awọn to gbajọba naa sọ pe awọn fẹ gbogun ti ajẹbanu ati jagidijagan ni, Ọgagun Johnson Aguiyi Ironsi, lo pada di olori orilẹede
- Oṣu Keje ọdun 1966: Iditẹgbajọba eyi lo da oju ijọba Ironsi de. Nigba to si di ọjọ akọkọ ninu oṣu Kẹjọ, Ọgagun Yakubu Gowon di olori Naijiria.
Agunyi Ironsi ati Ọgagun Francis Adekunle Fajuyi to jẹ gomina Iwọ Oorun nigba naa wa lara awọn to ba a lọ.
Awọn iditẹgbajọba mejeeji yii lo bi ija ẹlẹyamẹya, to pada di ogun abẹle.
Lẹyin ti ogun pari, loṣu Kẹwaa ọdun 1970, Ọgagun Gowon loun yoo ri i pe ijọba ṣọja pari lọjọ akọkọ oṣu Kẹwaa ọdun 1970, ṣugbọn ni 1974, o tun sun un siwaju.
- 1975: Ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Keje ọdun 1975: Ọgagun Joseph Nanven Garba, ọrẹ timọtimọ fun Gowon, kede lorii Radio Nigeria, pe oun atawọn ologun kan ti pinnu lati gbajọba lọwọ Gowon.
Ko si ipaniyan ninu iditẹgbajọba yii, nitori Gowon ti rin irinajo lọ si oke okun lati ṣe eto kan ti Organisation of African Unity, gbe kalẹ, ni Kampala.
Ọgagun Murtala Muhammed lo gbajọba lọwọ Gowon, nigba ti Ọgagun Olusegun Obasanjo jẹ igbakeji rẹ.
- 1976: Ọjọ kẹtala, oṣu Keji ọdun 1976: Wọn pa Murtala Muhammed ninu iditẹgbajọba, wọn si pa dẹrẹba rẹ ati amugbalẹgbẹẹ to n ṣọ ọ.
Bakan naa ni wọn pa Ibrahim Taiwo, gomina ologun ipinlẹ Kwara nigba naa.
Eyi lo sọ Obasanjo di olori orilẹede Naijiria, lẹyin iku Murtala.
Ijọba Naijiria kede pe Ọgagun Bukar Suka Dimka, lo lewaju iditẹgbajọba naa, pẹlu erongba lati da Yakubu Gowon pada sijọba.
Wọn mu eeyan 125 lori iditẹgbajọba yii, eeyan 32 si gba idajọ iku. Lara wọn ni Dimka ati Ọgagun Illiya D. Bisalla. Obasanjo lo pada ṣeto idibo to gbe Shehu Shagari wọle si ijọba alagbada.
- 1983: Ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kejila ọdun 1983: Awọn ọga ṣọja kan kora jọ, fopin si ijọba alagbada ẹlẹẹkeji. Wọn le Shagari danu, Oloogbe Ọgagun Sani Abacha to kede opin ijọba naa si ṣapejuwe rẹ bii ijọba alajẹbanu.
Wọn pa Brigadier Ibrahim Bako lasiko ti wọn fẹ mu Sahagari l'Abuja, Ọgagun Muhammed Buhari si di olori Naijiria.
- 1985: Ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹjọ ọdun 1985: Ikọ ologun ti Ọgagun Ibrahim Babangida lewaju, gba ijọba mọ Buhari lọwọ, wọn pe e ni iditẹgbajọba aafin.
Buhari rin irinajo lọ siluu Eko nigba naa ni, igbakeji rẹ, Ọgagun Tunde Idiagbon, si rin irinajo lọ si Saudi Arabia fun iṣẹ ẹ̀sìn, ki wọn too de ni wọn ti gbajọba mọ wọn lọwọ.
Ọgagun Joshua Dogonyaro lo kede iditẹgbajọba naa lorii redio laaarọ, ki Babangida to ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ.
Babangida sọ pe ijọba to duro tandi soju kan ni Buhari n ṣe lo jẹ kawọn gba a mọ ọn lọwọ, o ni ko kunju oṣunwọn.
- 1990: Ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹrin ọdun 1990: Awọn ologun ti Ọgagun Gideon Orkar, dari, kọju ija si Bareke ologun; Dodan Barracks, ni igbiyanju lati gbajọba Babangida.
Ṣugbọn Babangida raye sa lọ, rogbodiyan naa si pari lẹyin wakati mẹwaa.
Awọn ọga ologun sọ pe ẹyin Babangida ni awọn wa, eeyan mejilelogoji (42) ni wọn lo jẹbi ẹsun yii, gbogbo wọn ni wọn si yinbọn pa loṣu Keje ọdun 1990.
- 1993: Nigba ti ẹnu bẹrẹ si i kun Babangida ju, pe ko gbe ijọba fun alagbada, ṣọja yii yẹba nipo agbara, o si yan Ernest Shonekan bii olori ijọba Fidi-hẹ-ẹ lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹjọ ọdun 1993.
Ṣugbọn ijọba Shonekan ko ju oṣu mẹta lọ.
Ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kọkanla ọdun 1993 ni Ọgagun Sani Abacha le e danu, lẹyin ti wọn fagile ibo June 12 ti MKO ti gbegba oroke.