NAPTIP kéde pé àwọn n wá Speed Darlington fún ẹ̀sùn hihu ìwá kòtọ̀ọ́ pẹ̀lú ọmọdé

Oríṣun àwòrán, Speed Darlington/Instagram
Ọjọ Ẹti, ọjọ kẹtadinlogun oṣu Kẹfa ọdun 2025 ni NAPTIP kede loju opo X rẹ, pe awọn n wa Speed Darlington fun ẹsun ifipabanilopọ, idunkooko lori ayelujara ati ṣiṣẹ alami lori ayelujara.
Ajọ naa kede pe ẹnikẹni to ba mọ bi ọwọ ṣe le tẹ olorin yii, ki iru ẹni bẹẹ kan si awọn kia.
Akọrin taka-sufee, Darlington Okoye tawọn eeyan mọ si Speed Darlington, ti tako bi ajọ to n gbogun ti kiko awọn eeyan lọ soko ẹru, National Agency for the Prohibition of Trafficking in Persons, (NAPTIP) ṣe kede rẹ bii ẹni ti wọn n wa.
Ọkan lara awọn olorin ti ẹnu ki i sin lara wọn lagbo orin taka-sufee ni Darlington Okoye, tawọn eeyan tun mọ si Akpi.
Ninu ifọrọwerọ kan to ṣe lọjọ Abamẹta, Darlington sọ pe oun ti fi ọrọ naa le agbẹjọro oun lọwọ
" Ẹru o ba mi. Wọn o lẹtọọ kankan lati kede mi bii ẹni ti wọn n wa. Wọn kan fẹẹ yẹyẹ ara wọn ni, agbẹjọro mi yoo yanju ẹ."
Bẹẹ ni Speed Darlington wi.
Kí ló fa wàhálà láàárin Speed Darlington ati NAPTIP?
Ọsẹ diẹ sẹyin ni Speed Darlington lo sọ loju opo Instgram rẹ, pe oun ba ọmọbinrin ti ọjọ ori rẹ ko ju mẹẹẹdogun lọ, lo pọ.
O ni inu otẹẹli loun ti ba ọmọ ti ko ti i mọ ọkunrin ri naa lo pọ, ẹgbẹrun meji naira pere si ni oun fun ọmọ ọhun nigba naa.
Ọpọ eeyan lo koro oju si ọrọ ti Speed Darlington sọ yii, abọ rẹ si ni bi NAPTIP ṣe ranṣẹ si i pe ko waa ṣalaye ara rẹ fawọn.
Ọrọ yii de ọdọ ajọ to n ri si ifiyajẹ ọmọ nipinlẹ Eko, Lagos State Domestic and Sexual Violence Agency, (DSVA).
O si di pe NAPTIP kede ẹ bii ẹni ti wọn n wa lẹyin o rẹyin.
Ajọ naa ni ki olorin yii yọju si olu ileeṣẹ awọn ni ọgbọnjọ, oṣu Karun-un 2025.
NAPTIP sọ ọ di mimọ pe Darlington ko yọju, niṣe lo ni oun yoo wa lọjọ kẹrindinọgbọn, oṣu Kẹfa ọdun 2025.
Wọn ni akọrin naa sọ pe oun ni awọn nnkan mi-in lati ṣe.
Wọn fi kun un pe ọga agba to n ri si ikede ni NAPTIP, Hakeem Lawal, tun buwọ lu lẹta mi-in tawọn fi ran Darlington leti lati wa, iyẹn lọjọ kejidinlọgbọn oṣu Karun un, 2025.
Pabo naa lo pada ja si bi wọn ṣe wi, ajọ naa si lawọn fun un di ọjọ keji, oṣu Kẹfa lati waa wi ti ẹnu rẹ, laaago kan ọsan, ni ọfiisi awọn to wa ni Wuse, l'Abuja.
NAPTIP ṣalaye pe Darlington ko tun wa.
Ninu awijare rẹ, olorin taka-sufee naa sọ pe oun n fi orin ṣere ni toun ni.
O loun nilo ohun ti yoo mu aroye dani ki oun le rọwọ mu lọ sẹnu.
Ninu ọrọ mi-in to kọ soju opo rẹ, Speed Darlington sọ pe 'ẹtan' lasan ati imuniṣere ni oun fi ọrọ ibalopọ naa ṣe.
Ṣugbọn ọpọ eeyan lo koro oju si eyi, wọn ni apara buruku to le ṣi awọn ẹlomi-in lọna to si lewu pupọ ni Speed Darlington da.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ẹnu kì í sìn lára afọ́kèémù
Eyi kọ ni igba akọkọ ti ẹnu yoo kun Speed Darlington lori iwa ati ọrọ ẹnu rẹ, koda, ko pẹ to bọ lọwọ ọlọpaa lori ẹsun kan.
Ileeṣẹ ọlọpaa ti i mọle fun ẹsun ibanilorukọjẹ to waye laaarin rẹ pẹlu olorin taka-sufee mi-in, Burna Boy.
Eyi ni i ṣe pẹlu olorin ilẹ America, Diddy, ti wọn mu fun pe o lọwọ ninu ibalopọ akọsakọ.
Niṣe ni Darlington n beere lọwọ Burna Boy, ẹni to gba ami ẹyẹ Grammy ni 2021, pe bawo lo ṣe ṣe e to fi ri ami ẹyẹ nla naa gba.
O ni ṣe Diddy fi epo ra Burna Boy ni furọ lo fi ri Grammy gba ni.
"Ko pẹ ti Burna Boy gbe fọto oun ati Diddy jade lori ayelujara lo ri ami ẹyẹ Graamy gba.
" O kan n ya mi lẹnu ni. Burna Boy , mo n beere lọwọ ẹ, ma binu o. Epo meloo ni Diddy da si furọ rẹ ti o fi ri ami ẹyẹ gba?"
Bẹẹ ni Speed Darlington beere .
Fidio ibi ti awọn ọlọpaa ti waa gbe e, gba ori ayelujara nigba naa, bo tilẹ jẹ pe ko sẹni to mọ ẹni to wa lẹyin gbigbe ti wọn gbe e lọ si atimọle naa.
Burna Boy tawọn eeyan n darukọ rẹ lori ọrọ naa ko si sọ ohunkohun.
Ta a ni Speed Darlington?

Oríṣun àwòrán, Speed Darlington/Instagram
Olorin ni Baba to bi Speed Darlington naa, baba rẹ ni Pericoma Okoye, iya rẹ si ni Queen Theresa Onuorah.
Okigwe, nipinlẹ Imo, ni wọn ti bi Speed Darlington.
Orin rẹ to pe ni BangDadaDang, to jade ni 2017 lo sọ ọ di gbajumọ lawujọ orin taka-sufee.
O tilẹ sọ nigba naa pe, Diddy, olorin America naa lo fun oun ni iṣipaya toun fi gbe orin ọhun jade.
Orin naa gbajumọ daadaa nigba yẹn, to bẹẹ ti wọn n lo o ni awọn ile ijo ati ode ariya, igba naa si ni Speed Darlington bẹrẹ si i sọrọ lori ayelujara.
O fi Naijiria silẹ lẹyin to di gbajumọ tan, o lo n gbe ni America. Ṣugbọn lẹyin ọdun diẹ, o tun pada wa si orilẹede yii.
Ẹni ọdun mọkandinlogoji ni Speed Darlington, iṣẹ rẹ loju opo ayelujara rẹ si saba maa n da lorii ibalopọ ati ọrọ bi eeyan ṣe le ri owo.














