Ó gbẹnután! Alfa Musa pokùnso ní Ilorin, Ó ní Ọlọ́run kò gbọ́ àdúrà òun

Aworan okun ti wọn fi n pokunso

Ọmọ ile kewu kan, to n gbe lagbegbe Ogidi, Ilọrin, nipinlẹ Kwara ti pokunso.

Arakunrin ẹni ọdun mejilelogun yi ni a gbọ pe orukọ rẹ n jẹ Musa.

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara fidi ẹ mulẹ pe loootọ ni ọmọkunrin kan, tawọn eeyan a maa pe ni Alfa Musa, pokunso nile to n gbe lagbegbe Ogidi, Ilọrin, nipinlẹ Kwara.

Ati pe awọn ti bẹrẹ iwadii lori ohun to mu gende naa roo pe gbigbẹmi ara rẹ ni igbesẹ to kan.

Ko sẹni to fura pe Alfa Musa yoo gbe igbesẹ iku ọhun, gẹgẹ ba a ṣe gbọ.

Nigba ti ọrẹ oloogbe yii wa a dele lo ba ilẹkun ni titi pa, o kan ilẹkun titi, ṣugbọn ti ọrẹ rẹ ko dahun, bẹẹ o wa ninu ile.

Nigba to pẹ ti ọrẹ yii ti n kanlẹkun ti ko gbọ idahun kankan ni wọn ja ilẹkun wọle, nibẹ ni wọn ti ri Musa to n mi dirodiro labẹ okun to fi pokunso.

Ike ọda ati apoti ni wọn ni oloogbe naa to pọ, to si gun to fi kọrun bọ okun.

Ohun ti Alfa Musa kọ kalẹ sinu iwe ree lori idi to fi pokunso

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọkan lara awọn ti wọn jijọ n gbe pẹlu Alfa Musa lagboole Dagbẹnu ba BBC Yoruba sọrọ lori iku rẹ.

Ọbinrin naa ti o bẹbẹ pe ki a fi orukọ bo oun ni asiri, ni idi ti gende yii fi gba ẹmi ara rẹ ko ye ẹnikankan.

O tẹsiwaju pe ileekewu Sheikh Kamaldeen, ti wọn n pe orukọ ileekewu ọhun ni Asiari ni oloogbe ọhun n lọ.

O ni ''iya ko jẹ ẹ, o si ma n kirun daadaa.''

Arabinrin naa fi kun pe ọmọ ipinlẹ Ọsun, ni Musa, ṣugbọn ni kete ti iṣẹlẹ yii ṣẹlẹ lawọn pe baba rẹ to si ni kawọn sin oku rẹ si Ilọrin.

Eyi tako ọrọ ti Musa sọ silẹ ninu iwe pelebe ti wọn ba ninu yara rẹ to sọ sibẹ pe ki wọn ma ṣe sin oku oun si Ilorin.

A ko foju ri iwe pelebe yi amọ ohun ti awọn oṣojumi koro sọ nipa rẹ ree.

"Baba mi ati iya mi, mo tọrọ aforiji, mo ṣe eleyi nitori pe Ọlọrun ko gbadura mi, ki n ku san ju ki n maa dẹṣẹ lọ, mo nifẹẹ yin, ẹ lọọ sin oku mi sile"

Alukoro ọlọpaa Kwara, DSP Ejirẹ Adeyẹmi Adetoun, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fun BBC Yoruba, lọjọ Ẹti Furaide, ọjọ Kejọ, oṣu Kejila yii.

O ni iwadii ṣi n lọ lọwọ nipa ohun to mu ẹni ọdun mejilelogun yii pokunso.

Adetoun fidi ọrọ ti wọn sọ pe Musa kọ sinu iwe pelebe yi rinlẹ.

''Bẹẹ ni a ri iwe pelebe naa to si tọrọ aforijin lọwọ awọn obi rẹ pe oun pokunso.''