#FIFAWWC: Amẹ́ríkà to pàṣán má r'ágbà fín sí ìdí Thailand

Oríṣun àwòrán, fifa.com
Fun igba akọkọ ninu itan idije ife ẹyẹ bọọlu awọn obinrin lagbaye, orilẹede kan yoo maa gbo ewuro soju orilẹede miran pẹlu ami ayo mẹtala.
Orilẹede Amẹrika gb'ogo lọwọ ẹgbẹ agbabọọlu obinrin orilẹede Thailand pẹlu ami ayo mẹtala ninu ifẹsẹwọnsẹ akọkọ wọn ni idije ife ẹyẹ fawọn obinrin to n lọ lọwọ lorilẹede France.
Koda, ko si idije ife ẹyẹ bọọlu ajọ FIFA kankan ti irufẹ eyi ti ṣẹlẹ.
Agbabọọlu orilẹede Amẹrika, Alex Morgan gba goolu marun un wọle ninu ifẹsẹwọnsẹ naa, Lavelle (meji), Mewis (meji), Horan, Megan Rapinoe, Mallory Pugh ati Carli Lloyd pẹlu naa gba goolu kọọkan wọle ninu ifẹsẹwọnsẹ naa.
Ifẹsẹwọnsẹ ọhun ni akọkọ fun orilẹ€de Thailand ninu idije ife ẹyẹ agbaye.










