Nàìjíríà - orísun àwọn ọlọpọlọ pipe ninu iṣẹ litireṣọ

Oríṣun àwòrán, AFP
O le ni miliọnu mẹrinlelọgọrin oludibo to forukọ silẹ fun idibo ọdun 2019.
Wo akọsilẹ awọn nkan abuda adamọ to fi Naijiria han gẹgẹ bii orilẹ-ede ilẹ̀ Adulawọ ti eto ọrọ ajé ẹ pọju.
1) Orin Takasufe Afro kíkọ lọ́nà àrà
Ọpọlọpọ ọmọ Naijiria lo ti gbe ògo orin Takasufe ti wọn n pe ni Afro Beats ga nile ati lẹyin odi.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Eyi tun pegede si ti orin oloogbe Fela Anikulapo Kuti to n kọ Afro Beat nigba aye rẹ ninu eyi to ti ṣadapọ orin alariwo ati takasufe papọ.
Awọn èèkàn ti Ọlọrun ti gba fun ni Naijiria lẹnu orin kikọ lasiko yii kuro ni keremi.
Diẹ lara wọn ni Wizkid, Davido, Tiwa Savage ati Jidenna.
Ipa wọn ninu orin lagbaye ti gba okùn de ibi pé ile iṣẹ olorin nlanla bii Universal Music Group ati Sony ti da ẹka ileeṣẹ wọn silẹ ni Naijiria.
Orin Davido to gbe jade lọdun 2017 jẹ orin to ta julọ ni Naijiria ri.
Awọn onkorin lasiko yii gba pé orin Afro Beats ti n nipa lori ọna iṣọwọ kọrin awọn miran ni ori ayelujara ni eyi to tun n fun Naijiria lokiki sii lagbaye.
Eyi lo bi ẹya orin bii Afro-pop, azonto, hiplife atawọn mii laarin awọn eniyan Ghana ati Naijiria bi apẹrẹ orin Oliver Twist ti DBanj tun ṣi oju awọn eniyan si i.
This article contains content provided by Google YouTube. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Google YouTube cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of YouTube post
Awọn olorin Naijiria mii to tun ti di ilumọọka ni Yemi Alade, Tekno, Falz, Olamide, Simi, Mr Eazi, Mologo ati Patoranking.
2) Awọn ogbontarigi òǹkọ̀wé
Orilẹ-ede Naijiria ti bi awọn onkọwe to ju onkọwe lọ lagbaye bẹrẹ lati ara Chinua Achebe to kọ iwe Things Fall Apart nibi ti wọn ti ta iwọn to le ni miliọnu ogun lati 1958 to ti tẹẹ.

Oríṣun àwòrán, AFP
Wole Soyinka na tun jẹ eekan to ti digi araba lai yọ Ben Okri, Oloogbe D O Fagunwa, Chigozie Obioma, Helon Habila, Chibundu Onuzo, Sefi Atta, JF Odunjọ, Chimamanda Adichie atawọn mii.
3) Ojoojumọ ni awọn ọmọ Naijiria n pọ sii, ti wọn n bi sii
Opọlọpọ ọmọ ni awọn eniyan Naijiria n bi sii ni eyi ti odiwọn idagbasoek wọn ti fi di ajitannawo lagbaye.

Iwadii fihan pe to ba fi maa di ọdun 2017, Naijiria ṣeeṣe ko ti di orilẹ-ede kẹta to tobi ju lagbaye.
Eyi ni awọn ọdọ to ni agbara lati dibo tọdun 2019 yii tun fi n pariwo pe iṣẹ to wa ko to ṣe rara nitori ero ti pọ ju.
Oloye Obnasanjọ Oluṣegun to ti dari NAijiria ri kilọ ọjọ iwaju ti a ko ba ṣọra lori ọna abayọ siṣoro yii.
4) Owó epo rọ̀bì tó yapa ni Naijiria láì sí iná ọba púpọ̀
Awọn kan tilẹ maa n sọ pe kii ṣe awọn olorin takasufe nikan la fi n mọ Naijiria yatọ bi ko ṣe ti ariwo ẹrọ amunawa kaakiri adugbo.

Oríṣun àwòrán, AFP
Opọ igba ni awọn agbegbe kan ko ni ina mọnamọna fun ọpọlọpọ ọ̀sẹ̀ ni eyi ti onikaluku fi ma n wa ọna abayọ.
Bẹẹ, Naijiria ni orilẹ-ede to n pese epo rọbi julọ lagbaye ninu orilẹ-ede ilẹ Afrika. O le ni miliọnu meji àgbá epo rọbi ti wọn n pese lojumọ.Banki agbayẹ pẹsẹ iranwọ fun Naijiria
Owó ti wọn n ri n ninu epo rọbi pọ nitootọ ṣugbọn iṣoro ina ọba ṣi n gbẹbọ lọwọ wọn.
5) Naijiria- Ilé Boko Haram alakatakiti ẹsin Islam
Awọn alakatakiti ẹsin Islam lo bẹrẹ ogun Boko Haram ni apa ariwa iwọ oorun Naijiria ni eyi ti o ti gba ọpọ ẹmi ati dukia.
Orọ ogun yii lo bi ipede bring bag our girls lori ayelujara ti awọn ajajangbara kan ṣe n beere fun awọn ọmọdebinrin Chibok ti Boko Haram ji gbe lọ.

Oríṣun àwòrán, AFP
Odun 2002 ni wọn ni wọn da Boko Haram silẹ ni agbegbe Maiduguri nipinlẹ Borno.
Orukọ won tumọ si pe eewọ ni imọ ẹkọ ọlaju iwe ni eyi ti ijọba Naijiria ṣi n wa ojutu sii titi di asiko yii.

Oríṣun àwòrán, AFP
Ni asiko kan ni awọn ọmọ ogun olotẹ yii gba ijọba agbegbe kan ni ila oorun ariwa Naijiria pẹlu ofin Sheria ki ijọba Naijiria to gab wọn pada.
Bayii, omodebinrin Leah Sharibu, akẹkọọ ile iwe Dapchi kan lo ku ti ijọba ko tii ri gba ninu awọn omodebinrin mii ti wọn tun jigbe.





























