Eduardo: Mo ń jí mọ́tò pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ mi nítorí pé mo fẹ́ di 'Big boy'

Àkọlé fídíò, Eduardo: Mo ń jí mọ́tò pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ mi nítorí pé mo fẹ́ di 'Big boy'

Ọdun meje ni mi nigba ti awọn obi mi gbe mi dani lọ si America lọna aitọ- Eduardo

Eduardo Garcia to jẹ ọmọ Mexico to lọ ṣatipo lọna aitọ nilẹ America ba BBC sọrọ nipa irinajo aye rẹ ki awọn ọdọ le kọ ẹkọ to yẹ lara rẹ.

O sọ itan bi o ṣe dagba ninu iṣẹ ati oṣi ni kekere ko to lọ dara pọ mọ ẹgbẹkẹgbẹ.

Eduardo sọ bo ṣe tẹle awọn ọrẹ lọ ma ji mọto ki ọwọ ofin to baa nitori pe o fẹ maa ba ẹgbẹ pe lai ṣiṣẹ.

Lẹyin ọdun mẹrin ni ẹwọn ni America daa pada si Mexico to ti wa.

Eduardo de Meico tan ni oju rẹ ṣẹṣẹ ṣí si iṣẹ alase ti o fi bẹrẹ si ni se ounjẹ ta.

Bayii ile ounjẹ Eduardo ti di nla to ti gba ọpọlọpọ ọdọ si iṣẹ ni Mexico.

Eduardo gba awọn ọdọ niyanju pe ole jija tabi jibiti ṣiṣẹ kọ ni ọna abayọ kuro nninu iṣẹ ati oṣi bikoṣe iṣẹ ṣiṣẹ pẹlu ootọ inu.