Painter killed in Lagos: Ta ló pa Toheeb "kunlékunlé" nílé ọ̀rẹ́ rẹ̀ ní Ikotun?

Ta lo pa Toheeb kunlékunlé nílé ọ̀rẹ́ rẹ̀ ni Ikotun?

Oríṣun àwòrán, Ìwé Ìròyìn Punch

Àwọn ẹbi Toheeb tó n kunlé ti rọ ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Eko láti tú iṣu de ìsàlẹ̀ ìkòkò lórí ikú tó pá ọmọ wọn ní ilé ọ̀rẹ́ rẹ̀ ni agbègbè Ikotun nílùú Eko.

Ìròyìn sọ pé olóògbé náà lọ sí ilé ọ̀rẹ́ rẹ̀, Dele tí ó sì pinu láti sùn síbẹ̀ ni òpópónà Olatunji, Okerube, Ikotun.

Ni ọjọ́ kejì, ní wọ́n ni Dele jí ni owúrọ̀ kùtùkùtù láti rín ìrìnàjò lọ sí ìlú Ilorin fún ìnàwó ìgbéyáwò tó sí fi Toheeb kalẹ̀ sílé pẹ̀lú àbúrò rẹ̀ Raphael.

Gẹ́gẹ́ bí olóógbé ṣe sọ, lásìkò tí òun ń sùn lọ́wọ́ ni Raphael já lu òun tí ó sì gbá nǹkan mọ́ òun lórí, lẹ́yìn náà lo bẹ́rẹ̀ sí ní gún ni ọ̀pọ̀ ibi ni ara rẹ̀.

Akọròyìn ilé iṣẹ́ Punch ṣàlàyé pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹ ní ọjọ́ Jimọ tí ṣe ọjọ́ kẹtalélógún osù kejè, ọdún 2021.

Àwọn kan sọ pe inú ìnira náà ni Toheeb wà nígbà tí ó pé ìyá rẹ̀ Kemi lórí fóònù láti sọ nǹkan tí ó ṣẹlẹ̀ si.

Bákan náà ló fi kun pé "kíá ni mo kan sí àwọn ènìyàn ni agbègbè láti bámi ṣe àbẹ̀wò sí ni ilé náà àti pé nígbà ti ẹni náà debẹ̀, inu agbara ẹ̀jẹ̀ ni wọ́n ti ba.

Wọ́n gun ni orí, ọrùn, ikùn, àti àwọn ara rẹ mííràn, kódà gbogbo ìfún rl ló ti wà ni ìta.

"O ní Raphael ló ṣe iṣẹ́ náà, sùgbọ́n Raphael náà wà níbẹ̀ pẹ̀lú, Toheeb ti o ti wà ni ìhòhò ní àsìkò yìí gbìyànjú láti ṣàlàyé nǹkan tí ó ṣẹlẹ̀ pé lásìkò tí òun sún lọ́wọ́ ló gbá nǹkan mọ́ òun lórí sùgbọ́n Raphael ni kìí ṣe òun ni òun ṣe irú rẹ̀.

"Toheeb ni Raphael fi nǹkan tí o mú gún òun: gbogbo bẹ́ẹ̀dì ló kún fún ẹ̀jẹ̀, ó ni ìṣẹ̀ll náà ṣẹ̀ ni kété tí Dele jáde nílé fún àyẹyẹ ìgbéyàwó tó ń lọ ni Ilorin tí òun sì sùn padà.

Àkọlé fídíò, Ọmọ Ìjọ Deeper Life Pọ́ńbélé ni ìyà mi àti bàbá mi, mo sì dàgbà síbẹ̀ àmọ́ bíbọ Èṣù ọ̀dàrà lọ́nà tó tọ́ -

" Lásìkò tí mò ń pè fún ìrànwọ́ lo tún gún òun ni orí, àyà, ẹ̀kẹ́, ọ̀nà ọ̀fun, ẹsẹ̀ àti ikùn.

Nínú àgbàra ẹ̀jẹ̀ yìí ní wọ́n ti gbé lọ sí ilé iwòsàn Better Life Hospital, wọn sì ní àwọn dókítà àti nọ́ọ̀sì tètè mójú tóo sùgbọ́n lẹyin ti wan se iṣk abẹ fún ni kò gbé apá àti ẹsẹ̀ mọ́ sùgbọ́n tí wọ́n bá pé orúkọ rẹ̀ yóò dáhùn.

ìwádìí tún fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé láàrín gbogbo ìgà tí ó gba ìtọ́jú yìí, ẹ̀jẹ̀ méje ni wan fún tí wọ́n sì pe awọn onímọ̀ láti wá ṣe ìtọ́jú rẹ̀.

"Sùgbọ́n ọ̀rọ̀ bẹ̀yìn yọ lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ̀ náà, nítórí pé dókítà ní ó yẹ kí ó tí jí lẹẹ́yìn wákàtí kan tí wọ́n ti parí iṣẹ́ abẹ náà, sùgbọ́ kò lajú , bkẹ̀ ni ko yíra padà.

Lẹyìn ọ̀pọ̀ wákàtí tí wọ́n ti parí iṣẹ́ abẹ ló bẹ̀rẹ̀ sí ní pọ nǹkan funfun lẹ́nu, àwọn dókítà gbìyànjú láti dóòlà rẹ̀, sùgbọ́n ó kú ni aago mẹjọ alẹ́ ọjọ́ Eti ti wọ́n sì tí gbé òkú rẹ̀ sí mọ́ṣúàrì Yaba.

Iya Toheeb, to bá iwe iroyin Punch sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọmije lójú ṣàlàyé pé ki àwọn ọlọ́pàá ṣe àwárí nǹkan tó ṣẹlẹ gan ni pàtó sí ]akọ́bí ọmọ òun.

Ó ni Dele àti Toheeb ti n bá ọ̀rẹ́ wọn bs láti ìgbà ti wan ti wà ni kékere, tí ó sì ti lé ní ọdún mẹ́tàlélógún , kódà ní àsìkò kan, ilé ìjọsin kan náà ni a jọ n lọ.

"Sùgbọ́n mo ti bá ọmọ mi sọ̀rọ̀ kó má lọ sí lé ilé Dele mọ sùgbọ́n kìí gbọ́.

Agbẹnusọ ọlọpoàá ìpińlẹ̀ Eko, CSP Muyiwa Adejobi fi ìdí iṣẹ́lẹ̀ náà múlẹ̀ pé lóòtọ́ ni

Ó fi kun pé, " Wọ́n ti gbé ẹjọ́ náà lọ sí ẹká ìwádìí ìwà ọ̀daràn lọ́jọ́ ajé gbogbo nǹkan tó sì wà ní ìkápá ọlọ́pàá ní à ó ṣe láti mu ìdájọ́ òdodo wá .