Ẹré bọ́ọ̀lù: Arsenal bọ́ mọ́ Dangote lọ́wọ́ láti rà

Aliko Dangote àti Stan Kroenke

Oríṣun àwòrán, Facebook/Dangote and Kroenke

Àkọlé àwòrán, Aliko Dangoke jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olólùfẹ́ ikọ̀ Arsenal lorílẹ́èdè Nàìjírìa

Gbajugbaja oniṣowo ọmọ Naijiria Aliko Dangote le maa ni anfani lati ra ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal mọ lẹyin ti ọmọ ilẹ Amẹrika, Stan Kroenke, kede pe oun fẹ ra ikọ agbabọọlu naa pa.

Dangote to jẹ ọkan lara awọn ololufẹ ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal lorilẹ-ede Naijiria ti fi erongba rẹ lati ra ẹgbẹ agbabọọlu naa han lọpọ igba, ṣugbọn ko ni anfani lati ṣe bẹẹ.

Ida bi aadọrin ninu ọgọrun ni Kroenke nikan ni ninu awọn to ni Arsenal nigba ti Alisher Usmanov to jẹ ọmọ orilẹ-ede Russia si ni ida ọgbọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Usmanov ti gbiyanju lọpọ igba lati ra ikọ Arsenal ṣugbọn Kroenke to lowo to pọ ju ninu ikọ agbabọọlu naa kọ jalẹ pe oun ko ni ta ẹgbẹ agbabọọlu naa.

Sugbọn ni bayi Usmanov ti ṣetan lati ta ipin rẹ fun Kroenke lẹyin ti o kọ lati ta ikọ naa.